Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Ìwé Ìròyìn/1
A kí yin káàbọ̀ sí abala àkọ́kọ́ Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí àti bí wọ́n ṣe lè túnbọ̀ kọ́pa nínú ètò náà. A ó tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà. A pè yín láti fún wa ní àwọn èsì tàbí àbá lórí abala ìkejì ìwé-ìròyìn yìí ní ojú-ewé ọ̀rọ̀ ìròyìn UCoC. Adúpẹ́ fún kíkà àti ìdásí yin.
Tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí ojú-ewé ọ̀rọ̀ yin, abẹ́ igi iṣẹ́-àkànṣe yín, tàbí ojú-ewé ké'wé tó tọ̀nà, ẹ fi orúkọ yín tàbí ti ojú-ewé náà kalẹ̀ sí bí.
Ìkópa yín ṣe pàtàkì fún wa. E lè ràn wá lọ́wọ́ láti ma túnmọ̀ àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí sí èdè ìbílẹ̀ yín, kí a lè pólóngó ìròyìn nípa ìlànà yìí, kí a sì pèsè àbò fún gbogbo wa nínú àjọṣepọ̀ tí gbogbo wa fẹ́ràn yìí. Ẹ jọ̀wọ́ fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa, kí a tó tẹ̀ wọ́n jádèe.
Ìkànsí àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia
Ní oṣù kẹ́ta àti oṣù kẹrìn 2021, a fi ìpè ránṣẹ́ sí àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia ní oríṣiríṣi ìwọ̀n, irú àti ìrírí láti kọ́pa nínú àwọn ìjíròrò, kí wọ́n sì fi àwọn ìrírí, èrò, àti àbá hàn lórí àwọn ọ̀nà tí a le fi ṣe ìwádìí àti tí a le fi gbé òfin UCoC ró. A ti ṣ'ètò àwọn ìpàdé tó ju 25 lọ, a sì rí èsì 147 nípasẹ̀ ìwé ìwádìí wa tí a tẹ̀ jáde ní èdè méèjọ, tí ó jẹ́ ìlò fún àwọn ilé-iṣẹ́ 27, pẹ̀lúpẹ̀lú, àwọn ilé-iṣẹ́ míìràn tún ṣ'ètò àwọn ìjíròrò tí wọ́n sì tún fi ọ̀rọ̀ UCoC sí ètò àwọn ìpàdé ẹgbẹ́ wọn láti gba èsì kalẹ̀.
Àkójọpọ̀ èsì lórí ìkànsí àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia wà lórí ojú-ewé yìí.
Ìjíròrò àwọn ìbéèrè gbòógì 2021
Ní oṣù kẹ́rìn àti oṣù káàrún 2021, Wikimedia Foundation gbìyànjú láti gba èsì kalẹ̀ lórí ìgbófìnró Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia, kí ó ba lè wúlò fún gbogbo ará, tí yíò sì ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ kárí ayé. E lè rí àkójọpọ̀ ìkànsí àti ìjíròrò àwọn ìbéèrè ìgbófìnró 2021 ní ojú-ewé yìí.
Àwọn olùkópa tó ju 247 lọ ni ó dásí àwọn ìkànsí, ìpàdé àti àwọn ìjíròrò tó nlọ lọ́wọ́. Lára wọn ni àwọn admin, functionary, ará arbcom, òṣìṣẹ́ ẹ̀ka Wikimedia, àti àwọn oníṣẹ́ titun àti àwọn tí ó ti ní ìrírí, láti àwọn iṣẹ́-àkànṣe oríṣiríṣi 16. Lára àkójọpọ̀ ìkànsí yìí ni àwọn èsì lát'orí àwọn ìjíròrò tí àwọn olùfarajìn dásílẹ̀ lórí ìgbófìnró Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
Bí ó tilè jẹ́ wípé àwọn àbá àti èrò àwọn olùkópa yàtọ̀ gedegbe, àkíyèsi àwọn àkòrí tó jọra wà láàrín àwọn ará. Àwọn olùkópa mú ìmọ̀ràn wá lórí àwọn àìní àti eewu ìfẹ̀sùnsùn àti ìwádìí ìkọ̀kọ̀, àwọn àbàwọ́n ìlànà ìgbófìnró tì sihìn, àti pàtàkì ìmọ̀ àyíká ọ̀rọ̀, pẹ̀lú ìfẹ́ fún àtìlẹ́yìn fún àwọn olùfarajìn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn olùkópa ni ó lérò wípé àwọn ará gbọdọ̀ lè ma ṣe àtúnṣe sí ìlànà ìwádìí àti ìgbófìnró.
Àwọn ìpàdé ìjíròrò
Àwọn olùṣètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ṣ'ètò àwọn ìpàdé ìjíròrò ní ọjọ́ 15 àti 29 oṣù káàrún 2021. Àwọn ìpè kọ̀ọkan wọ̀nyìí wáyé fún ìṣẹ́jú àádọ̀rún, pẹ̀lú àwọn olùkópa bíi 20-25 tí wọ́n jíròrò lórí àwọn ìbéèrè gbóògì àti àwọn àkórí tó wúlò míìràn tí a lè gbà sílẹ̀ fún ìgbìmọ̀ kíkọ ipele ìkejì UCoC.
Lára àwọn ohun tí ó tayọ nínú àwọn ìpàdé ìjíròrò ni ọ̀rọ̀ lórí ṣíṣètò ìgbìmọ̀ ìgbófìnró aláàpapọ̀ fún gbogbo iṣẹ́-àkànṣe wikimedia, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ lórí ètò ìwádìí gbangba, àti ìjíròrò lórí ojú-ìsájú àìmọ̀, Bí ó ti yẹ kí ètò ìfọwọ́sí àwọn ará Wikimedia lóri UCoC jẹ́, àti àwọn ìjíròrò ìjìnlẹ̀ lóri àwọn ọ̀nà àti ìlànà ìgbófìnró tó bójúmu.
Ìpàdé ìjíròrò tó nbọ̀ yíò wáyé ní 12 Oṣù Kẹfà ní 5:00AM UTC.
Ìgbìmọ̀ fún kíkọ ipele ìkejì
The Universal Code of Conduct drafting committee for phase 2 has been assembled and started their work on May 13, 2021. The committee is a group of 15 members that includes Wikimedians from 9 different countries, who edit our projects in more than 11 languages. Collectively they hold sysop roles on 13 various projects and 11 higher functionary roles, including two global sysops, two sitting arbitrators on different projects, and one former steward.
Currently, the committee is moving from team and capacity-building exercises into modules and exercises that commence the drafting of the enforcement guidelines. Short summaries from the drafting meeting are available to view and translate here.
The Drafting Committee will have some draft recommendations for UCoC enforcement for community review in early August. More details will be available soon.
Búlọ́ọ̀gì Diff
Àwọn olùṣètò UCoC kọ oríṣiríṣi búlọ́ọ̀gì lórí àwọn àkíyèsí àti èsì tí wọ́n rí gbà lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ ìbílẹ̀ tí wọ́n kànsí ní ìbẹ̀rẹ̀ odún 2021.
- Self-governance of older Wikimedia projects – the curious case of Polish Wikipedia – Over the course of the last 20 years, some communities individually developed extensive systems to deal with violations of conduct policies
- Consulting the UCoC Enforcement Within an Intercultural Wikimedia Ecosystem – How can wikimedia movement's interculturality help it with enforcing the Universal Code of Conduct?
- Lessons from the recent influx of teenagers in the Korean Community: How do we deal with them as active contributors? – Changing demographics of the Wikimedia Movement. What can we learn from the new generation of users?
- Facilitating Wikimedia Communities in West Africa for the UCoC – The uniqueness of African communities and the challenges of engaging the continent in global movement conversations.
- How the UCoC came to the Himalayas – What have we learned by engaging communities in their own language? How do smaller communities' insights differ from older and more prominent projects?
- Are gamification, cream and a cookbook good ingredients for a community consultation? – Could gamification be a useful way to engage local communities? The Italian community was a test-case.
- How Silence Speaks More Than Words – Why do our most complex and intercultural projects tend to stay quiet in major movement discussions?