C. L. R. James
Cyril Lionel Robert James (4 January 1901 – 19 May 1989) to tun gba oruko ikowe J.R. Johnson je omo Afrika-Trinidad akoitan, oniroyin, elero sosialisti ati alaroko. O ko ipa pataki ni Britani ati Amerika ninu awon egbe sosialisti ati ironu Marksisti, bakanna ati lori ero to le mu opin iseamusin wa. O si tun kowe nipa kriketi.[1]
Igbesiaye
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ibi ati igba ewe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]O je bibi ni Trinidad and Tobago, nigbana to je ileamusin Oba Britani, James lo si Queen's Royal College ni Port of Spain ki o to di oniroyin kriket, ati adakowe itan aroso. Leyin re o sise bi oluko, ninu awon akeko re igbana ni Eric Williams, to di Alakoso Agba ile Trinidad and Tobago. Lapapo mo Ralph de Boissière, Albert Gomes ati Alfred Mendes, James je ikan ninu awon olodi-aseamusin Egbe Beacon, awon olukowe ti won ni asepo mo iwe iroyin The Beacon. Ni 1932, o ko lo si Nelson ni Lancashire, Ilegeesi gege olukowe igbesiaye agba kriketi West India, Learie Constantine, nibi to ti nireti pe ohun le di olukowe. Nibe lo ti sise fun Manchester Guardian to si ran Constantine lowo lati ko ìwéìgbésíayéaraẹni.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Rosengarten: Urbane Revolutionary, p. 134.