AYEDERU
AYEDERU
AYEDERU
Ayobami je omo olowo, Jibowu ni oruko baba re, oruko iya re si ni Segilola, Ayobami je omo ti ko mo
iwe pupo nitori pe kii ka iwe re, obinrin ni o n tele kaakiri. O to awon obi re lo lojo kan lati ra esi idanwo
iwe mewa fun, ki o le wo ile eko giga ti yunifasiti nitori pe esi idanwo re ko da. Baba re ko fi owo si aba
yii rara, o gbagbo ninu ki omo sise asekara lati ni esi idanwo to pegede.
Awon obi Ayobami o raye tire, won maa n jaye kiri ni, oni ode, ola ariya ni fun won, aibojuto omo won
yii lo so Ayobami di olodo nitori ko ri ibawi lati odo awon obi re. Koda, orebinrin re, Tinu ni oyun fun,
Ayobami mu lo si ile iwosan lati yo oyun naa, amo dokita so fun pe oun ko le se ati pe ko ma mu obinrin
kankan wa si odo oun mo fun oyun sise (o ti maa n mu orisirisi obinrin lo tele ri). Leyin eyi, awon obi
Tinu lo si ile awon obi Ayobami, Ayobami so pe oun ko mo Tinu ri ni ibikankan.
Leyin eyi awon obi Tinu binu si gidi gan, baba re si ni oun ti ko lomo, ni Tinu ba gbe ogun oloro
asekupani je, lo ba ku.
Awon ore Ayobami ni Dare ati Toye, awon ti wo ile eko giga yunifasiti ni tiwon nitori pe esi idanwo
tiwon dara. Awon obi Ayobami ra esi idanwo ayederu fun, oun naa si wo ile eko giga yunifasiti, oun pelu
awon ore re si n gbe po. Inu ogba Yunifasiti ni o ti pade Bayo, won bere si ni se ore, nigba ti o ya o ko eru
re kuro lodo awon ore re, o ko lo si ile Bayo nitori pe awon ore re kii jaiye , won ti maa n ka iwe ju.
Nigba ti o bere sini gbe ile Bayo, igbesi aye re yii pada si buburu, kii lo si kilaasi deede, ariya ati faaji ni
lojoojumo. Bayo a tun maa ji owo re (nitori naa lo se mu sodo), ki Ayobami to ka mo. Ni ojo kan , Toye ri
Ayobami pelu orebinrin re, Funto. O kilo fun Ayobami pe Funto kii se omo gidi o, o si so fun pe ki o jina
si. Leyin naa, Ayobami so gbogbo nnkan ti Toye so, fun Funto. Funto si seleri ninu okan re lati fi iya je
Toye.
Funto je orebinrin oluko kan ti o n je Omowe Juwon, o fi ejo Toye sun Oluko naa, o si je ki Toye kuna
ninu idanwo re, eyi si je kayeefi fun Toye ati gbogbo awon akekoo to ku, Toye lo ri Oluko naa sugbon ko
fi eti sile lati gbo alaye re.
Bayo ri bi Funto se n huwa si Ayobami ati gbogbo iya to fi n je e ati pe Ayobami ka Funto pelu orekunrin
re miiran.
Ija waye laarin egbe okunkun aake ati kanakana, nini ija yii, akekoo meji padanu emi won, Bosun ,
akekoo kan ti o je omowe wa lara awon to padanu emi re. Gbogbo awon akekoo ko ara won jo lati fi
ehonu han lori Bosun to padanu emi re, won si pinu lati dekun iwa ibaje ninu ile iwe won.
Alase ile iwe won ni ki gbogbo awon akekoo mu iwe eri ti won fi wo ile iwe wa ki won le da awon ti
won lo iwe eri ayederu, okan Ayobami poruru, ko si mo ohun ti o le se. Bayo si ba Ayobami soro wipe ki
o wa dara po mo egbe okunkun ti oun naa wa. Ayobami ko lakoko, amo nigba ti o ya, o gba si lenu, oun
naa si darapo mo egbe okunkun.
Ni gbangba ita ibugbe awon akekoo to n je Libati , oku akekoo kan w a ni ile, Funto ati Gbemisola ore re
n soro nipa awon egbe okunkun to pa akekoo naa, Ayobami ati Bayo gbo oro won, won si pin nu lati fi iya
je. Awon omo egbe aake ka Funto mo ile, won si fi ipa b ani ajosepo.
Ayobami pada omobinrin miiran ni o nifee gidi, oruko re ni Damilola, o gba lati je orebinrin re . Sugbon
ni ojo kan, Damilola mo wipe omo egbe okunkun ni Ayobami n se, o so fun, ohun to sele ni wi pe eni kan
ni o ri kaadi idanimo Ayobami ni ile Funto ti won fipa ba lopo, eni yii ni o mu kaadi yii, o si lo fun
Damilola gege bi ore re.Damilola ni oun kabamo pe oun ba ni nnkan po. Ayobami jewo fun Damilola, o
si seleri fun pe oun ma kuro ninu egbe naa. Nigba ti o kuro lodo re, o lo si ile oti, o si so ohun to sele laari
noun ati Damilola fun Bayo, Bayo so fun pe ko ba ma ti jewo fun, o si so fun pe awon nilati yanju
Damilola fun nnkan ti o mo yen.
Ayobami mu ero ibanisoro re, o si pe Damilola pe ki o ma salo nitori pe won fe pa, Bayo ka mo ibi ti o ti
n ba Damilola soro lori foonu, nibi ti o ti n gbiyanju lati gba foonu owo Ayobami, o fi obe gen imu.
Damilola ti n se omo oga olopaa salo si ile, baba re si da awon olopaa si inu ile iwe won, won fi oro wa
Ayobami lenu wo, o jewo gbogbo ohun to mo lati ran ise won lowo, won mu awon omo egbe okunkun.
Omowe Juwon ti o feeli Toye gba iwe gbele e, nigba ti awon igbimo ri aridaju wi pe orebinrin re ni
Funto ati awon omobinrin miiran ati pe awon orebinrin re kii se idanwo ki won to yege, o si maa n feeli
eni to ba wu lai je pe won feeli. Funto naa de iwaju igbimo leyin ti awon omo egbe okunkun ti fi ipa ba
lo, awon igbimo ni ki o pada si ipele kini lati ipele keji.
Won le oruko awon ti won fi esi idanwo ayederu wo ile iwe, awon ore Ayobami si ri oruko re nibe, eyi je
kayeefi fun won. Won wa Ayobami lo si ile, Bayo so fun won pe ko si ni ile, won wa lo si ile Damilola,
won ba Funmilayo ore Damilola pade, o si so gbogbo ohun to ti sele laarin Ayobami ati Damilola fun
won.
Leyin ti ohun gbogbo ti sele, Damilola pada si ile iwe, Ayobami jewo fun lori foonu pe ohun jebi esun lilo
iwe ayederu lati wo ile iwe, o si pa ara re.