100% found this document useful (1 vote)
689 views81 pages

Yor212 0

This document provides an overview of a course on Yoruba folktales taught at the National Open University of Nigeria. The course aims to expose students to Yoruba folk philosophy, worldviews, and culture as reflected in folktales. It will cover various elements of folktales like motifs, characterization, and performance techniques. The course is divided into modules that will address topics such as the origins and types of folktales, themes within folktales, and the oral tradition of Yoruba folk literature. Students will be evaluated through assignments and a final exam.

Uploaded by

Temitope Victor
Copyright
© © All Rights Reserved
We take content rights seriously. If you suspect this is your content, claim it here.
Available Formats
Download as PDF, TXT or read online on Scribd
100% found this document useful (1 vote)
689 views81 pages

Yor212 0

This document provides an overview of a course on Yoruba folktales taught at the National Open University of Nigeria. The course aims to expose students to Yoruba folk philosophy, worldviews, and culture as reflected in folktales. It will cover various elements of folktales like motifs, characterization, and performance techniques. The course is divided into modules that will address topics such as the origins and types of folktales, themes within folktales, and the oral tradition of Yoruba folk literature. Students will be evaluated through assignments and a final exam.

Uploaded by

Temitope Victor
Copyright
© © All Rights Reserved
We take content rights seriously. If you suspect this is your content, claim it here.
Available Formats
Download as PDF, TXT or read online on Scribd
You are on page 1/ 81

NATIONAL OPEN UNIVERSITY OF NIGERIA (NOUN)

YOR 212: YORUBA FOLKTALES

LÁTI ỌWO ̣́

ỌLAGOKE ALAMUPh.D
Department of Linguistics and Nigerian Languages
Ekiti State University, Ado-Ekiti, Nigeria

COURSE CODE: YOR 212


COURSE TITLE: YORUBA FOLKTALES

COURSE CONTENT SPECIFICATIONS (COURSE DESCRIPTION)


This course focuses on thefollowing: the universality of folktales; types of folktales;
motifs in folktales; the world of folktales, characterization, setting and techniques;
performance, the narrator and the audience, the songs in folktales, creativity and
originality of rendering; folktales and myths.

ÌFÁÁRÀ SÍ KOO


̣́ S
̣́ Ì YÌÍ
Nínú ko ̣́o ̣́sì yìí ni a ó ti ṣe àgbéye ̣́wò ìtànkáyé àlo ̣́, irúfe ̣́ àlo ̣́, kókó inú àlo ̣́, ibùdó àlo ̣́, àwọn
e ̣́dá-ìtàn àti aáyan ìfìwàwe ̣́dá; abbl. tí apàlo ̣́ ń lò láti gbé ìtàn kale;̣́ àwọn akópa nínú àlo ̣́,
orin ati iwulò orin inú àlo ̣́; ọgbo ̣́n ìso ̣́tàn àti ọgbo ̣́n àtinúdá.

Course writer: Professor Ọlagoke Alamu

Course Editor: Professor Adesọla Ọlatẹju

ii
Vice Chancellor’s Message
Forward

iii
ÀKÓÓNÚ KOO
̣́ S
̣́ Ì

Módù Kínní: Ìfáárà


Ìpín kínní: Oríṣi àlo ̣́, Àbùdá wọn àti Ìwúlò Àlo ̣́
Ìpín kejì: Ìṣíde Àlo ̣́
Ìpín ke ̣́ta: Àwọn Èròjà inú Àlo ̣́

Módù Kejì: Kókó Oṛ́ o ̣́, Ìhun ati Ifìwàwedá


̣́
Ìpín kinní: Kókó o ̣́ro ̣́ inú àlo ̣́
Ìpín keji : Ìhun-ìtàn alo ̣́ àti abùdá ìtàn
Ìpín ke ̣́ta: Eḍ́ á-ìtàn ati Ifìwàwe ̣́dá

Módù Kẹta: Ìlò Èdè àti Bátànì Gbólóhùn Ìṣíde àti Ìparí Àlo ̣́
Ìpín kinní: Ìlò Èdè inú àlo ̣́
Ìpín kejì: Bátànì gbólóhùn ìṣíde àti ìparí àlo ̣́

Módù Kẹrin: Àṣàyàn Àlo ̣́ Ìjàpá àti Àtúpale ̣́ wọn


Ìpín kinní: Ìjàpá, Àgbò àti Igba
Ìpín keji : Ìjàpá lóyún ìjàǹgbo ̣́n
Ìpín ke ̣́ta: Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn
Ìpín kẹrin: Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ

Módù Karùn-ún: Àṣàyàn Àlo ̣́ Olórogún tàbí Àlo ̣́ mìíràn àti Àtúpale ̣́ wọn
Ìpín kínní: Ìtàn Orogún méjì àti Ọkọ wọn
Ìpín kejì: Ìyáálé gbé ọmọ ìyàwó re ̣́ sínú ọtí
Ìpín kẹta: Ìyáálé roko tán
Ìpín kẹrin: Tanimo ̣́la àti Orogún ìyá re ̣́

iv
ÀFOJÚSÙN KOO
̣́ S
̣́ Ì
The course is designed to equip students with
1. adequate skills in the analysis of the Yoruba folktales.
2. expose the students to the world of Yoruba folktales, with reference to the Yoruba
world-view, philosophy and culture.
3. educate them on the oralness of Yoruba oral literature.

v
STUDENT’S ROLE
The student should use the study material as the major medium of instruction since the
method of instruction is the distance learning mode. Each student is expected to study
this material prior to the examination.

Evaluation
Continuous assessments are carried out in the form of assignments based on this study
material. The assignments will constitute 40% of the total score. The examination
constitutes 60% of the total score. There will be three Tutor Marked Assignment for the
course before the candidate is qualified for the examination.

ÌLÀNÀ MÁÀKÌ GBÍGBÀ


Àtẹ ìsàle ̣́ yìí ṣe àfihàn bí máàkì gbígbà yóò ṣe rí.
Ìgbéléwo ̣́n Máàkì
Iṣe ̣́-ṣíṣe/Àmúṣe módù 1 – 5 Ogójì (40%)
Ìdánwò Àṣekágbá Ọgo ̣́ta (60%)
Àpapo ̣́ Ọgo ̣́rùn-ún (100%)

vi
MÓDÙ KÍNNÍ: ÌFÁÁRÀ
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Oríṣi àlo ̣́ àti Àbùdá wọn
4.2 Ìwúlò Àlo ̣́
4.2.1 Fún Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.2.2 Fún Ìdárayá
4.2.3 Fífi ìdí òóto ̣́ múle ̣́
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Àlo ̣́ je ̣́ o ̣́kan lára lítíréṣo ̣́ àtẹnude ̣́nu Yorùbá tí ó tàn kále ̣́ ju àwọn lítíréṣo ̣́ àtẹnude ̣́nu
yòókù lọ. Àwọn ọmọdé ni a máa ń pa àlo ̣́ fún le ̣́yìn iṣe ̣́ òòjo .̣́ Ale ̣́ ni a máa ń pa àlo ̣́ pàápàá
nígbà tí òṣùpá bá yọ . Ìdí ni èyí tí ààlo ̣́ àpagbè fi je ̣́ o ̣́kan lára àwọn eré tí à ń pè ní eré
òṣùpá, èyí tí àwọn ọmọdé máa ń ṣe ní ile ̣́ káàáro ̣́ -oò-jíire. Àgbàlagbà kan ni ó máa ń pa
àlo ̣́ fún àwọn ọmọdé.
Àlo ̣́ je ̣́ àwọn ìtàn tí ó dá lé àṣà àti ìṣe Yorùbá . Oṕ̣ o ̣́lọpo ̣́ àṣà Yorùbá bí i ìgbéyàwó ,
oúnjẹ, aṣọ wíwo ̣́, òkú sínsin, àṣà ìranraẹnilo ̣́wo ,̣́ orin ati ijó ni ó wa nínú àlo .̣́ Oríṣiríṣi ìmo ̣́
èrò ìjìnle ̣́Yorùbá (tí à ń pè ní fìlo ̣́so ̣́fì ), èrò àti ìgbàgbo ̣́ àwọn Yorùbá , pàápàá nípa
Olódùmarè, àwọn òrìṣà, ọdún ìbíle ̣́ àti àwọn ohun mèremère àyíká tí Olódùmarè dá ni ó
wà nínú àlo .̣́ Káàkiri àgbáyé ni a ti ń pa àlo ̣́ . Ó fe ̣́re ̣́ má si í oríle ̣́ àgbáyé kan tí kò ní àlo ̣́
tire ̣́.
Àwọn ìtàn àtinúdá ni àlo ̣́ je ̣́. A ko mo ̣́ e ̣́ni pato ti o da wo ̣́n sile ̣́ nitori ate ̣́nudenu
̣́ ni
wo ̣́n. Ṣùgbo ̣́n báyìí, àwọn òǹko ̣́wé bí i Babalọlá (1979) àti Oṕ̣ ádo ̣́tun (1994) ti s ̣́e akojo ̣́po ̣́
wọn, wo ̣́n sì ti di kiko ̣́ sile.̣́
Ìpín kínní: Oríṣi àlo ̣́, Àbùdá wọn àti Ìwúlò Àlo ̣́
Ìpín kejì: Ìṣíde Àlo ̣́
Ìpín kẹta: Àwọn Èròjà inú Àlo ̣́

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ó gbo ̣́do ̣́ le ṣàlàyé:
(1) ìtumo ̣́ àlo ̣́, àti àwọn akópa nínú àlo ̣́.
(2) oríṣi àlo ̣́ tí ó wà àti àbùdá wọn.
(3) àwọn ohun tí à ń lo àlo ̣́ fun.
(4) oríṣiríṣi àṣà àti ìmo ̣́ ìjìnle ̣́ èrò Yorùbá (Yorùbá filo ̣́sọfì) tí ń bẹ nínú àlo ̣́.

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Ǹje ̣́ o ti gbo ̣́ nípa àlo ̣́ rí?
2. Irú àlo ̣́ wo ni o ti gbo ̣́ nípa re?̣́

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ìpín Kínní: Oríṣi Àlo ̣́ àti Abuda wo ̣́n
Oríṣi àlo ̣́ méjì ni Yorùbá ní . Èkínní ni àlo ̣́ àpagbè tí a tún ń pè ní àlo ̣́ onítàn (folktale).
Èkejì sì ni àlo ̣́ àpamo ̣́ (riddles). Àlo ̣́ àpagbè, èyí tí kóo ̣́sì yìí dá lé je ̣́ àwọn àlo ̣́ tí ó ní ìtàn
nínú, tí ó sì sáábà máa ń dá lé ẹranko kan tí a mo ̣́ sí ìjàpá (the tortoise). Àmo ̣́ kì í ṣe ìjàpá
nìkan ni àlo ̣́ àpagbè máa ń dá lé , ó tún le dá lé àwọn ènìyàn , ṣùgbo ̣́n ti ìjàpá ni ó wo ̣́po ̣́
jùlọ. Ìjàpá ni ó sáábà máa ń je ̣́ olú e ̣́dá-ìtàn nínú o ̣́po ̣́lọpo ̣́ àlo ̣́ Yorùbá.
Oríṣi àlo ̣́ kejì ni èyí tí à ń pè ní àlo ̣́ àpamo ̣́ . Nínú oríṣi àlo ̣́ yìí , apàlo ̣́ yóò béèrè
ìdáhùn tó rúnilójú tàbí ìbéèrè tí kò lọ tààrà, èyí tí àwọn ọmọdé máa ronú jinle ̣́ láti w á
ìbéèrè sí. Fún àpẹẹrẹ ìhun àlo ̣́ àpamo ̣́ ni èyí:
(i) Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!

2
Ọmọdé: Ààlo ̣́!
Apàlo ̣́: Kí ló bo ̣́ sódò tí a kò rí kó?
Ìdáhùn irú àlo ̣́ yì í gba ìronú jinle ̣́ láti fèsì sí . Èsì àlo ̣́ yìí ni „iyo ̣́‟ (salt). Ìdí èyí sì ni pé tí a
bá da iyo ̣́ sómi, níṣe ni yóò domi fún ra re.̣́
(ii) Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!
Ọmọdé: Ààlo ̣́!
Apàlo ̣́: Òkun ń hó yeye
Oṣ́ à ń hó gbùdù
Alákọrí korí bo ̣́ o ̣́
Ki ni o?
Ìdáhùn sí àlo ̣́ yìí ni „orógùn‟ . Orógùn ni à ń lò láti ro oúnjẹ nínú omi gbígbóná tí ń hó
yeye.

4.2 Ìwúlò Àlo ̣́


Iṣe ̣́ me ̣́ta pàtàkì ni à ń fi àlo ̣́ ṣe:
(1) À ń lò ó fún ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ . A fi n ko ̣́ awo ̣́n o ̣́mo ̣́de le ̣́ko ̣́o ̣́ paapaa nipa iwa o ̣́mo ̣́luabi .
Ìdí ni èyí tí ìwà rere fi máa ń borí ìwà búburú nínú àlo ̣́.
(2) À ń lò ó fún ìdárayá. À ń fi ìtàn inú àlo ̣́ dá àwọn ọmọdé lárayá.
(3) À ń lò ó láti fi ìdí òóto ̣́ múle ̣́ pàápàá nípa àṣà Yorùbá.

4.2.1 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
Yorùbá máa ń lo àlo ̣́ onítàn láti ko ̣́ àwọn ọmọdé ní e ̣́ko ̣́ ìwà rere tàbí ìwà
ọmọlúwàbí. Àwọn ìwà bí i òóto ̣́ sísọ , e ̣́mí ìre ̣́le ̣́ , ìbo ̣́wo ̣́fágbà, àìṣo ̣́lẹ, àìṣème ̣́le ̣́,
ìwo ̣́ntunwo ̣́nsì, àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ, ni awo ̣́n iwa rere ti Yoruba ka si iwa o ̣́mo ̣́luwabi , èyí tí ó ṣe
àwùjọ ní àǹfààní , tí ó sì dára fún ìbágbépo ̣́ e ̣́dá . Yorùbá gbàgbo ̣́ pé ìwà rere le ̣́ṣo ̣́ ènìyàn,
ṣùgbo ̣́n àwọn ìwà bí i olè jíjà, iro ̣́ pípa , o ̣́lẹ ṣíṣe, ìme ̣́le ̣́ ṣíṣe , ìgbéraga, àìbo ̣́wo ̣́fágbà,
ojúkòkòrò, àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ, ni awo ̣́n iwa ti Yoruba bu e ̣́nu ate ̣́ lu ti wo ̣́n si ka si iwa buburu .
Irú àwọn ì wà yìí ni Yorùbá gbàgbo ̣́ pé ó ní ìjìyà nínú , tí kò sì ṣe àǹfààní fún àwùjọ àti
ìbágbépo ̣́ e ̣́dá.

3
Àwọn ìwà búburú yìí ni àwọn ìwà tí a gbé wọ ìjàpá nínú àlo ̣́ onítàn . Àwọn ìwà yìí
ni wo ̣́n si je ̣́ ki ijapa maa jiya ninu alo ̣́ . Àwọn ìwà búburú ìjàpá ni ó ń mú wàhálà àti ìjìyà
bá a.

4.2.2 Ìdárayá
Yorùbá máa ń pa àlo ̣́ láti dá àwọn ọmọdé lárayá , pàápàá le ̣́yìn iṣe ̣́ òòjo ̣́ wọn . Ìdí ni
èyí tó fi je ̣́ pé ale ̣́ ni à ń pa àlo,̣́ pàápàá, ní àkókò òṣùpá.
Oríṣiríṣi o ̣́nà ni àwọn ọmọdé máa ń gbà kópa nínú àlo ̣́ nígbà tí a bá ń pa àlo ̣́ láti dá
ara wo ̣́n laraya. Wo ̣́n lè gbe àwọn orin inú àlo ̣́, tàbí lu ìlù sí àwọn orin yìí, kí wo ̣́n sì jó sí i.
Ìsínjẹ apàlo ̣́ máa ń pa àwọn ọmọdé le ̣́rìn -ín. Bákan náà ni àwọn ète tí apàlo ̣́ ṣe àmúlò, (èyí
tí a ó rí níwájú) máa ń je ̣́ kí ìtàn náà dùn létí wọn.

4.2.3 Fífi ìdí òóto ̣́ múle ̣́


Àwọn àlo ̣́ onítàn kán wà tí à ń lò láti fi sọ ìdí tí ohun kan fi ṣẹle ̣́ . Irú àwọn àlo ̣́ be ̣́e ̣́
ni ako ̣́le wo ̣́n maa n ni apola gbolohun yii : “Idi ti…”. Fún àpẹẹrẹ „Ìdí tí Ejò fi ń pa Eku
jẹ‟, „Idi ti Ologbo s ̣́e n le Ekute kiri‟ , Ìdí tí Abiamọ kì í fi í sin ọmọ délé ọkọ‟ (Oṕ̣ ádo ̣́tun
1994). Wo ape ̣́e ̣́re ̣́ irufe ̣́ yii sí i ní abe ̣́ Módù kẹta.

5.0 Ìsọniṣókí
Nínú ìpín yìí, kókó pàtàkì méjì ni a ye ̣́wò . Èkíní ni oríṣi àlo ̣́ tó wà àti àbùdá ìko ̣́o ̣́kan wọn .
Oríṣi àlo ̣́ kìíní ni àlo ̣́ àpagbè, èyí tí a tún ń pè ní àlo ̣́ onítàn, èyí tí ko ̣́o ̣́sì yìí dá lérí. Èkejì sì
ni alo ̣́ àpamo ̣́, èyí tí kò ní ìtà n ninu ti o ni idahun si ibeere ninu . Kókó kejì tí a ye ̣́wò
niìwúlò àlo ̣́ tàbí iṣe ̣́ tí àlo ̣́ ń ṣe. Àwọn kókó me ̣́ta yìí ni : ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́, ìdárayá àti fífi ìdí òóto ̣́
múle ̣́.

5.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Dárúkọ oríṣi àlo ̣́ tó wà.
2. Kínni awo ̣́n abuda alo ̣́ ko ̣́o ̣́kan?
3. Kín ni ìwúlò àlo ̣́?
4
6.0 Ìwé Ìto ̣́kasí
Babalọlá, A. (1979) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá (Apá kejì). Ibadan: University Press.
Ojo, O. Ìjàpá Tìrókò Ọkọ Yannibo. Ikeja: Longman Nigeria Ltd.
Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ìbàdàn: Y-Books.

5
Ìpín Kejì: Ìṣíde Àlo ̣́ Àpagbè/Onítàn
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Àwọn o ̣́nà tí à ń gbà ṣíde àlo ̣́
4.1.1 Lílo àlo ̣́ àpamo ̣́
4.1.2 Lílo ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Ní abe ̣́ ìpínyìí, ohun ti a o gbeye ̣́wo niàwọn oríṣi o ̣́nà tí a fi ń ṣíde tàbí be ̣́re ̣́ àlo.̣́

2.0 Èròǹgbà àti Afojúsùn


Ní ìparí ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, o gbo ̣́do ̣́ lè mọ:
(1) àwọnoríṣi o ̣́nà tí a fi ń ṣíde àlo ̣́
(2) àpẹẹrẹ méjì ó kéré tán tí à ń lò láti ṣíde àlo ̣́

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Ǹje ̣́ o mọ o ̣́nà tí à ń gbà be ̣́re ̣́ àlo ̣́?
2. Èwo ni o mo ̣́ nínú ìbe ̣́re ̣́ tàbí ìṣíde àlo ̣́ yìí?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Àwọn oríṣi o ̣́nà tí a fi n sị́ de alo ̣́

6
4.1.1 Lílo Àlo ̣́ Àpamo ̣́
Kí a tó pa àlo ̣́ onítàn, àlo ̣́ àpamo ̣́ ni apàlo ̣́ ko ̣́ko ̣́ máa ń fi ṣíde tàbí be ̣́re.̣́ Apàlo ̣́ máa ń lo
ọgbo ̣́n yìí láti ta àwọn ọmọdé (olùgbo ̣́) jí àti láti pèsè ọkàn wọn sile ̣́ fun alo ̣́-onítàn náà.
Fún àpẹẹrẹ apàlo ̣́ lè be ̣́re ̣́ báyìí:
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!
Àwọn ọmọ: Ààlo ̣́!
Apàlo ̣́: Kí ló ń lọ lójúde ọba tí kò kí ọba?
Ta lo mo ̣́ o ̣́n o?
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, apàlo ̣́ pe àkíyèsí àwọn ọmọ láti múrasíle ̣́ láti gbo ̣́ àlo ̣́ tí ó fe ̣́ pa.Èyí ló
mú kí àwọn ọmọ náà fèsì sí gbólóhùn àko ̣́ko ̣́ apàlo ̣́ nípa sísọ pé „ààlo ̣́‟. Le ̣́yìn èyí ni apàlo ̣́
yóò wá gbé àlo ̣́ àpamo ̣́ re ̣́ kale ̣́, èyí tí àwọn ọmọdé náà yóò ronú jinle ̣́ sí, kí o ̣́kan nínú wọn
tí ó nawo ̣́ yóò dáhùn nípa sísọ pé „Èmi mo ̣́ o ̣́ o ̣́n‟. Le ̣́yìn èyí ni ọmọ náà yóò dáhùn pé
„ojo‟. Tí ọmọ náà bá gba ìdáhùn, apàlo ̣́ yóò sọ pé „o gba a o‟.„Bi o ̣́mo ̣́ naa ba si sị́ idahun
sí àlo ̣́ àpamo ̣́ náà, apàlo ̣́yóò ní „hún un‟ o s ̣́i i o‟. Apàlo ̣́ yóò sì tún pe ẹlòmíràn títí tí a ó fi
mọ ìdáhùn sí àlo ̣́ àpamo ̣́ náà. Nígbà mìíràn, apàlo ̣́ ni yóò fi ẹnu ara re ̣́ túmo ̣́ àlo ̣́ náà bí kò
bá sí ẹni tí ó mọ ìdáhùn sí àlo ̣́ àpamo ̣́ náà láàrin àwọn o ̣́mo ̣́de naa.
Àpẹẹrẹ àlo ̣́ àpamo ̣́ mìíràn tí apàlo ̣́ le lò nìyí. Àpẹẹrẹ yìí gùn ju ti àko ̣́ko ̣́ lọ:
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!
Àwọn ọmọ: Ààlo ̣́!
Apàlo ̣́: Wòrúkú tindí tindí,
Wòrúkú tindì tindì,
Wòrúkú bí igba ọmọ, gbogbo wo ̣́n lo le ni tiroo.
Kín ni o?
Àwọn ọmọ: Erèé

3.1.2 Lílo Ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì


Le ̣́yìn tí apàlo ̣́ bá lo àlo ̣́ àpamo ̣́ láti ta àwọn ọmọ jí àti láti pèsè ọkàn wọn síle ̣́ fún àlo ̣́ -
onítàn náà, ní ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì kan yóò wáyé láàrin apàlo ̣́ àti àwọn ọmọdé , tí ó je ̣́ olùgbo ̣́ r e ̣́.
Àpẹẹrẹ ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì náà nìyí, ó sì je ̣́ o ̣́nà tí à ń gbà ṣíde àlo ̣́-onítàn:

7
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o
Àwọn ọmọdé: Ààlo ̣́
Apàlo ̣́: Ní ọjo ̣́ kan…
Àwọn ọmọdé: Ọjo ̣́ kan kìí tán láyé
Apàlo ̣́: Ní ìgbà kan…
Àwọn ọmọdé: Ìgbà kan ń lọ, ìgbà kan ń bo ̣́, ọjo ̣́ ń gorí ọjo ̣́.
Apàlo ̣́: Bàbá kan wà
Àwọn ọmọdé: Ó wà bí e ̣́wà
… … …
Le ̣́yìn ìṣíde àti ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì yìí ni apàlo ̣́ yóò be ̣́re ̣́ ìtàn tí ó fe ̣́ sọ.
Yàto ̣́ sí àpẹẹrẹ òkè yìí, o ̣́nà mìíràn wà tí apàlo ̣́ lè lò láti ṣíde àlo ̣́ re ̣́. Àpẹẹrẹ kejì ni ó
wà ní ìsàle ̣́ yìí:
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!
Àwọn ọmọdé: Ààlo ̣́!
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ mi dá fùrùgbágbòó
Àwọn ọmọdé: Kó má gbágbòó ọmọ mi lọ
Apàlo ̣́: Ó dá lérí Ìjàpá Tìrókò ọkọ Yánníbo tó ń lọ láàrin e ̣́pà
tó ní ọpe ̣́lọpe ̣́ pé òun ga.
… … …
Nínú àpẹẹrẹ kejì ni a tún ti rí àpẹẹrẹ ìso ̣́ro ̣́ ǹgbèsì mìíràn èyí tí ó yàto ̣́ díe ̣́ sí àpẹẹrẹ kínní .
Irú ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì báyìí , níbi tí àwọn ọmọdé máa ń fèsì sí o ̣́ro ̣́ apàlo ̣́ náà máa ń je ̣́ kí wo ̣́n
múrasíle ̣́ láti gbo ̣́ àlo ̣́ onítàn tí apàlo ̣́ fe ̣́ pa.Irú ìṣíde kejì yìí ní e ̣́fe ̣́ nínú , èyí tí ó máa ń mú
àwọn ọmọdé re ̣́rìn-ín. Gbogbo wa la mo ̣́ pe igi e ̣́pa ki i ga rara . Díe ̣́ náà sì ni Ìjàpá fi ga ju
e ̣́pà lọ. Le ̣́yìn ìṣíde yìí ni Apàlo ̣́ yóò be ̣́re sí
̣́ sọ ìtàn re ̣́.

5.0 Ìsọniṣókí
A ti fun wa ni ape ̣́e ̣́re ̣́ orisị́ ríṣi o ̣́nà tí apàlo ̣́ ń gbà láti ṣíde àlo ̣́ . Apàlo ̣́ ko ̣́ko ̣́ máa ń lo àlo ̣́
àpamo ̣́ láti ta àwọn ọmọ jí tàbí láti mú àwọn ọmọ lára síle ̣́ láti gbo ̣́ àlo ̣́ onítàn tàbí àpagbè .
Oṇ́ à kejì tí apàlo ̣́ ń gbà ṣíde àlo ̣́ ni lílo ìso ̣́ro ̣́ǹgbèsì èyí tí a ti fún wa ní àpẹẹrẹ re ̣́ ní 3.1.2.

8
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
1. Kọ oríṣi àpẹẹrẹ méjì tí apàlo ̣́ ń lò láti ṣíde àlo ̣́ síle.̣́
2. Kín ni àwọn ìdí tí apàlo ̣́ fi ń lo irú ìṣíde yìí.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


1. Amọo, T. A. (1988) Yorùbá Ọdún Kìn-ín-ní. Ibadan: Evans Brothers.
2. Ogundeji, P.A. (1991) Introduction to Yoruba Oral Literature. Ibadan: Dept. of
Adult Education, University of Ibadan.
3. Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn àlo ̣̀ onítàn. Ibadan: Y – Books.

9
Ìpín Kẹta: Àwọn Èròjà Inú Àlo ̣́
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Àwọn Èròjà inú Àlo ̣́
4.1.1 Orin
4.1.2 Ìsínjẹ
5.0 Ìsọniṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Oríṣiríṣi èròjà ni apalo ̣́ maa ń lò láti gbé àlo ̣́ kale .̣́ Àwọn èròjà wo ̣́nyí bí i orin àti ìsínjẹ ni
àwọn ète ti apàlo ̣́ máa ń lo láti jẹ kí àlo ̣́ náà dùn àti pa àwọn ọmọdé le ̣́rìn -ín. Àwọn èròjà
yìí ni a ó me ̣́nubà lábe ̣́ ìpín yìí.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Ní ìparí ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ake ̣́ko ̣́o ̣́ gbo ̣́do ̣́ lè mọ:
(1) ipa ti orin ko ninu alo ̣́
(2) ìwúlò orin nínú àlo ̣́
(3) àwọn o ̣́nà ìsínjẹ inú àlo ̣́

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Dárúkọ àwọn èròjà tó máa ń wà nínú àlo ̣́
2. Kín ni ìwúlò orin nínú àlo ̣́?
3. Kọ orin àlo ̣́ kan tí o mo ̣́.

10
4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Àwọn Èròjà inú Àlo ̣́
4.1.1 Orin
Oríṣi ète ni apàlo ̣́ lè lò láti mú ìtàn re ̣́ dùn àti láti je ̣́ kí àwọn ọmọdé gbádùn ìtàn náà. Oḳ́ an
nínú àwọn ète yìí ni orin. Irú orin inú àlo ̣́ yìí máa ń ní bátànì lílé àti ègbè. Apàlo ̣́ ni yóò
máa lé orin, àwọn ọmọdé yóò sì máa gbè é. Fún àpẹẹrẹ, ẹ je ̣́ kí á wo orin àlo ̣́ yìí láti inú
ìtàn „Ìjàpá àti Ìyá-Ẹle ̣́pà:
(i) Lílé: Ẹle ̣́pà yìí, ẹle ̣́pà yìí o
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Lílé: Ò bá jó lọ bí Oỵ́ o ̣́ Ilé
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Lílé: Ò bá jó lọ bí Of̣́ à Mọjo ̣́
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Lílé: Ǹ bá wò dí igbá dè o ̣́.
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Lílé: Eṕ̣ à pe ̣́ú, e ̣́pà pe ̣́ú
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Lílé: Eṕ̣ à pe ̣́ú, e ̣́pà pe ̣́ú
Ègbè: Pẹrẹpẹrẹpe ̣́ú
Àpẹẹrẹ mìíràn nìyí láti inú „Ìtàn Orogún Méjì àti Ọkọ Wọn‟
(ii) Lílé: Gbewé mi, gbewé mi jẹ
Ègbè: Àgbò gbewé mi jẹ
Lílé: Ọdún kẹta ọko ̣́ ti lọ
Ègbè: Àgbò gbewé mi jẹ
Lílé: Èmi ò rìnnà bo ̣́kùnrin pàdé
Ègbè: Àgbò gbewé mi jẹ
Lílé: Ọkùnrin ó te ̣́ní fún èmi sùn rí
Ègbè: Àgbò gbewé mi jẹ

11
Láàrin ìtàn ni apàlo ̣́ ti máa ń dá orin, tí àwọn ọmọdé yóò sì dìde láti jó, pàte ̣́wo ̣́ tàbí lu ilu
sí i. Ní ìgbà mìíràn, orin inu alo ̣́ apagbe tabi onitan ni o mu un yàto ̣́ sí àlo ̣́ àpamo ̣́, èyí tí kò
ní orin nínú.
Oríṣiríṣi ni ìwúlò orin nínú àlo ̣́:
a) Ó máa ń je ̣́ kí àwọn ọmọdé gbádùn ìtàn náà dáradára.
b) Ó máa ń je ̣́ kí àwọn ọmọdé kópa nínú ìtàn náà.
d) À ń lò ó láti má je ̣́ kí ìtàn sú àwọn ọmọdé náà, kí wọn kí ó má ba à sùn lọ.
e) Ó ń je ̣́ kí ìtàn kí ó te ̣́síwájú.

4.1.2 Ìsínjẹ
Ìsínjẹ ni ète mìíràn tí apàlo ̣́ máa ń lò láti mú kí ìtàn rẹ dùn. Ìsínjẹ ni fífi ara tàbí e ̣́yà
ara so ̣́ro ̣́ lati sẹ́ isinje ̣́ awo ̣́n e ̣́da -ìtàn inú àlo ̣́ náà . Lílo irú ète yìí máa ń je ̣́ kí àwọn ọmọdé
gbádùn àlo ̣́ onítàn naà dáradára nítorí pé ìsínjẹ lè pani le ̣́rìn-ín.
Nínú ìsínjẹ, apàlo ̣́ lè rán imú so ̣́ro ̣́ láti sí n e ̣́da-ìtànkan je ̣́. Kò sí e ̣́dá-ìtàn tí apàlo ̣́ kò
lè sínjẹ. Afo ̣́jú ni o, olóyún ni o, arọ ni o, ó sì lè je ̣́ ẹni ti o ga tabi e ̣́ni kukuru.
Ní kúkurú, apàlo ̣́ máa ń lo ìsínjẹ láti sín ìṣesí , ìhùwàsí, ìrísí àti ìso ̣́ro ̣́sí e ̣́dá-ìtàn inú
àlo ̣́ tí ó ń pa jẹ . Ète ìsínjẹ lílò yìí máa ń je ̣́ kí ìtàn náà dùn , kí àwọn ọmọdé gbádùn re ̣́, kí
wọn si tun ro pe ooto ̣́/òtíto ̣́ ni ìtàn náà.

5.0 Ìsọníṣókí
Lábe ̣́ ìpín yìí , a ti sẹ́ agbeye ̣́wo orin ge ̣́ge ̣́ bi o ̣́kan lara ete ti apalo ̣́ n lo lati mu ki
ìtàn re ̣́ dùn.A s ̣́e akiyesi pe orin inu alo ̣́ maa n ní bátànì lílé àti ègbè . Bákan náà, ni a ti s ̣́e
àgbéye ̣́wò àwọn ìwúlò orin . Orin máa ń je ̣́ kí àwọn ọmọdé gbádùn ìtàn náà dáradára ; ó ń
je ̣́ kí àwọ n o ̣́mo ̣́de kopa ninu itan kí ìtàn náà má ba à sú wọn . Ète kejì tí àwọn apàlo ̣́ ń lò
láti gbé àlo ̣́ kale ̣́ ni ìsínjẹ. Èyí ni apàló ń lò láti sín ìṣesí, ìhùwàsí àti ìrísí e ̣́dá-ìtàn jẹ.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Bátànì wo ni orin inú àlo ̣́ ní? Fi orin inu alo ̣́ kan s ̣́e ape ̣́e ̣́re ̣́.
2. Kọ ìwúlò orin inú àlo ̣́ síle.̣́

12
3. Kí ni ìsínjẹ?
4. Kí ni ìwúlò ìsínjẹ?
5. Àwọn ohun me ̣́rin wo ni apàlo ̣́ máa ń sínjẹ lára e ̣́dá-ìtàn?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


1. Babalọlá, A. (1979) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá (Apá kínní). Ibadan: University Press.
2. Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn àlo ̣̀ onítàn. Ibadan: Y – Books.

13
MÓDÙ KEJÌ: KÓKÓ OR
̣́ O,̣́ ÌHUN ÌTÀN ÀTI ÌFÌWÀWED
̣́ Á
Ìfáárà
Lábe ̣́ Módù yìí, a o sẹ́ agbeye ̣́wo awo ̣́n koko o ̣́ro ̣́ ti alo ̣́ onitan maa n da le . Le ̣́yìn
èyí ni a ó me ̣́nuba ìhun ìtàn àti ìfìwàwe ̣́dá.
Ìpín kínní: Kókó o ̣́ro ̣́ inú àlo ̣́-onítàn
Ìpín kejì: Ìhun ìtàn àti àbùdá re ̣́.
Ìpín kẹta: Ìfìwàwe ̣́dá

Ìpín kínní: Kókó o ̣́ro ̣́ inú àlo ̣́-onítàn


Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kókó o ̣́ro ̣́
4.1.1 E ̣́san
4.1.2 Ìdí Abájọ
4.1.3 Orogún ṣíṣe
4.1.4 Ìdánwò
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Kókó o ̣́ro ̣́ ni òye , e ̣́ko ̣́, tàbí ọgbo ̣́n tí aso ̣́tàn tàbí apàlo ̣́ kan fe ̣́ fi ko ̣́ wa nínú ìtàn re ̣́ . Kókó
o ̣́ro ̣́ yìí niàhunpo ̣́ ìtàn ro ̣́ mo .̣́ Bí a bá fe ̣́ mọ kókó ìtàn , a ni lati wo ahunpo ̣́ itan naa daadaa
àti ìbáṣepo ̣́ àti ìkọlura tó wáyé láàrin àwọn e ̣́dá-ìtàn, èyí tí ó mú ìtàn náà te ̣́síwájú.

14
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ake ̣́ko ̣́o ̣́ gbo ̣́do ̣́ lè sọ àwọn kókó o ̣́ro ̣́ tí àlo ̣́-onítàn ní àti ìdí tí a fi gbé
àwọn kókó yìí kale ̣́ nípa lílo bátànì ìhun ìtàn náà.

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Kí ni itumo ̣́ koko alo ̣́?
2. Fún wa ní àpẹrẹ kókó àlo ̣́ kan tí o mo ̣́.

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Kókó o ̣́ro ̣́
4.1.1 Eṣ́ an
Ìgbàgbo ̣́ Yorùbá ni pé ohun tí ènìyàn tàbí e ̣́dá kan bá gbìn ni yóò kà á . Ẹni tí ó ṣe
rere a rire, ẹni tó sì ṣìkà, á ríkà, àtoore àtìkà, o ̣́kan kìí gbé. Ìdí ni èyí tí e ̣́san fi je ̣́ o ̣́kan lára
kókó pàtàkì tó wà nínú àlọ-onítàn. Dandan ni ki e ̣́da -ìtàn kan gba e ̣́san ìwà rere tó hù tàbí
ìwà búburú.
Ge ̣́ge ̣́ bí olú e ̣́dá-ìtàn àlo ̣́, ìdí ni èyí tí a fi ń fi ìyà jẹ ìjàpá nítorí àwọn ìwà búburú tó
ń hù . Fún à pẹẹrẹ, ìwà olè tí ìjàpá hù nínú ìtàn „Ijapa àti Ìyá Alákàrà ‟níbi tí ó ti ń lọ jí
àkàrà ni o mu ki o ̣́sanyìn ẹle ̣́se ̣́ kan pa á . Bákan náà , ìwà o ̣́dàle ̣́, ìwọra, ìmọtaraẹni-nìkan,
olè àti àìṣòóto ̣́ ìjàpá ló mú kí ó kú nínú ìtàn „Ìjàpá àti Àdàbà Jọ Dá Oko Kan‟.

4.1.2 Ìdí-abájọ
Àlo ̣́-onítàn máa ń ṣe àlàyé ohun tí ó mú kí ohun kan rí bí ó ṣe rí . Ní o ̣́po ̣́lọpo ̣́ ìgbà
ni eyi maa n je ̣́yo ̣́ ni ipari a lo ̣́ tàbí nínú àkọlé ìtàn gan-an funrare .̣́ A ri ape ̣́e ̣́re ̣́ eyi ninu
àkọlé àlo ̣́-onítàn tí Babalọla (1973) ṣe àkójọpo ̣́ re ̣́. Àkọlé yìí ni „Ìdí tí orí Ìjàpá fi pá‟ àwọn
àkọlé tí ó jọ àkọlé tí a me ̣́nubà lókè yìí . Fún àpẹẹrẹ „Ìdí tí o ̣́run fi jìnnà sí ayé‟ , „Idi ti
ológbò fi ń pa èkúté jẹ‟ àti „Ìdí tí e ̣́yìn ìjàpá ṣe rí kángunkàngun‟ , „Idi ti igunnugun fi pa
lórí‟.

15
4.1.3 Orogún ṣíṣe
Nínú àwọn ìtàn àlo ̣́ mìíràn tàbí àwọn àlo ̣́ olórogúnni a ti maa n ri koko -ìtàn yìí. A
tún lè pe àwọn oríṣi ìtàn tí a ti ń rí kókó yìí ní àlo ̣́ olórogún . Owú jíjẹ láàrin ìyáálé àti
ìyàwó ni ó máa ń fa ija orogun. Nínú irú àlo ̣́ báyìí, ìyáálé ni ó máa ń kórìíra ìyàwó , tí yóò
sì ní dandan kí ó bá ohun wá nǹkan ohun kan tí ó sọnù . Ó lè je ̣́ ìgbákọ tí ìyàwó yá lo ̣́wo ̣́
ìyáálé, tí odò sì gbé e lọ . Irú ìyáálé be ̣́e ̣́ yóò ní dandan ìgbákọ òun tí odò gbé lọ ni òun fe ̣́ .
Irú ìwà búburú yìí àti ìwà e ̣́san yìí, ni yoo mu iyawo rin irin-àjò lọ inú igbó kan níbi tí e ̣́mí
àìrí kan yóò ti ràn án lo ̣́wo ̣́ lá ti ri ohun to n wa . Ìfaradà àti ìforítì ni ìyàwó be ̣́e ̣́ fi ń borí irú
ìṣòro báyìí.

4.1.4 Ìdánwò
Ìdánwò máa ń jẹyọ nínú o ̣́po ̣́lọpo ̣́ àwọn àlo ̣́ olórogún . Nínú akitiyan ìyàwó láti wá
ohun iyaale re ̣́ to sọnù tàbí tí ó bàje ̣́ lo ̣́wo ̣́ re ̣́ ni yóò ti bá ìdánwò pàdé . Ìyàwó yìí lè rin
ìrìn-àjò lọ inú igbó kan tàbí ìlú òdì kejì láti ṣàwárí ohun tí ìyáálé re ̣́ pọn o ̣́n ní dandan tó fe ̣́
gbà padà lo ̣́wo ̣́ re ̣́ l áti gbe ̣́san. Nínú ìrìn-àjò yìí ni yóò ti bá iwin tàbí bàbá arúgbó kan tí
yóò gbé iṣe ̣́ tàbí ìdánwò fún un láti ṣe , kí ó tó rí ohun tó ń wá . Ó lè ní kí ó hú igi ńlá kan
láàárín àkókò kékeré kan . Ìgbà mìíràn, arúgbó tàbí iwin yìí lè ní kí ó gbin àgbàdo tí yóò
hù lóòjo .̣́ Irú ìṣòro yìí ni ìyàwó máa ń bá pàdé . Ṣùgbo ̣́n ní o ̣́po ̣́lọpo ̣́ ìgbà ni ìrànlo ̣́wo ̣́ yóò
dé nítorí inú rere re ̣́. Ìrànlo ̣́wo ̣́ yìí lè je ̣́ iwin mìíràn tàbí ìyá re ̣́ tí ó ti kú. Àwọn yìí ni yóò ṣe
ìrànlo ̣́wo ̣́ fún ìyàwó be ̣́e ̣́ láti ṣe ìdánwò yìí ní àṣeyọrí.

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, a ti s ̣́e agbeye ̣́wo awo ̣́n olu koko ti o saaba maa n je ̣́yo ̣́ ninu
àlo ̣́-onítàn. A si ti s ̣́alaye ohun ti koko -o ̣́ro ̣́ je ̣́ ge ̣́ge ̣́ bí ohun kan pàtó tí ìtàn dá lérí . Lára
àwọn kókó o ̣́ro ̣́ tó máa ń jẹyọ nínú àlo ̣́ ni: e ̣́san, ìdí abájọ, orogún ṣíṣe àti ìdánwò.

5.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Kí ni ìtumo ̣́tí o lè fún kókó-o ̣́ro ̣́?
2. Olú kókó-ìtàn mélòó ni ó wà nínú àlo ̣́-onítàn?

16
3. Ṣe àpèjúwe olú kókó-ìtàn ko ̣́o ̣́kan.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Ogundeji, P.A. (1991) Introduction to Yoruba Oral Literature. Ibadan: Department of
Adult Education, University of Ibadan. pp. 30 – 38.

17
Ìpín Kejì: Ìhun àti Àbùdá Ìhun Ìtàn
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Àbùdá ìhun ìtàn
4.2.1 Àṣeṣtúnṣe ìṣe ̣́le ̣́
4.2.2 Àyípadà ìgbà
4.2.3 Ìṣe ̣́le ̣́ àyísódì
4.2.4 Ìrànlo ̣́wo ̣́
4.2.5 Ibùdó ìṣe ̣́le ̣́
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Níbí yìí, a o s ̣́e agbeye ̣́wo ihun itan àti àwọn àbùdá tí ìhun ìtàn máa ń ní . Èyí ṣe
pàtàkì nítorí àwọn èròjà yìí ni a lò láti gbé ìtàn kale ̣́.
Ìtàn yàto ̣́ sí sísọ ìtàn kan ní ṣókí . Ó yàto ̣́ sí sísọ ìtàn lásán . Àwọn o ̣́nà tí a gbà gbé
ìtàn kale ̣́ tàbí hun ìtàn po ̣́ ni à ń pè ní ìhun -ìtàn. Ìhun ìtàn àlo ̣́ kì í lo ̣́júpo ̣́ rárá, tààrà ló máa
ń lọ.Àlo ̣́-onítàn ní àwọn o ̣́nà tí a fi gbé e kale ̣́ èyí tí a lè pè ní àbùdá ìhun-ìtàn.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ake ̣́ko ̣́o ̣́ gbo ̣́do ̣́ le;
(1) sọ ìtumo ̣́ àhunpo ̣́-ìtàn
(2) ṣàlàyé àwọn àbùdá ìhun-ìtàn márààrún tí a ó me ̣́nubà ní o ̣́ko ̣́o ̣́kan.

18
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
1. Bátànì won i ìtàn inú àlo ̣́ máa ń ní?
2. Ǹ je ̣́ o mọ nípa àbùdá ìhun-ìtàn?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Àbùdá Ìhun-ìtàn
4.1.1 Àṣeṣetúnṣe ìṣele
̣́ ̣́
Ṣíṣe ohun kan náà ju e ̣́e ̣́kan tàbí e ̣́e ̣́mejì lọ nínú àlo ̣́ ni à ń pè ní àṣeṣetúnṣe ìṣe ̣́le ̣́ . A
rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìtàn „Ìjàpá , Àgbe ̣́ àti àwọn ọmọ re ̣́‟.Àṣeṣetúnṣe ìṣe ̣́le ̣́ ṣẹle ̣́ nígbà tí ìjàpá
lọ sí oko àgbe ̣́ láti lọ jí erèé (e ̣́wà) ní e ̣́e ̣́mẹta . Láko ̣́o ̣́ko ̣́, gbogbo awo ̣́n o ̣́mo ̣́ agbe ̣́ yii ati
ìyàwó re ̣́ ni ìjàpá kọrin fún nínú òkùnkùn tí gbogbo wọ n si salo ̣́ fi eree sile ̣́ ki ijapa to ji
erèé lọ. Ẹnú ya àgbe ̣́ gidigidi nígbà tí wo ̣́n ròyìn fún un nípa ohun tó ṣẹle ̣́ lóko , ó sì pinnu
láti te ̣́lé àwọn ọmọ àti òṣìṣe ̣́ re ̣́ ní ọjo ̣́ kejì lọ wo ohun tó ń ṣẹle ̣́ lóko. Nígbà tí ile ̣́ ṣú ni ìjàpá
tún kọ orin abàmì re ̣́ , èyí náà ba àgbe ̣́ le ̣́rù ó sì sálọ . Eẹ́ ̣́kẹta ni ọwo ̣́ tó tẹ ìjàpá , tí ó já sí
kòtò tí babaláwo àti àgbe ̣́ gbe ̣́, tí igi ṣoṣoro ṣoṣoro tí wo ̣́n rì mo ̣́ kòtò sì gún ìjàpá pa.
Láàrin àṣeṣetúnṣe ìṣe ̣́le ̣́ báyìí ni orin àlo ̣́ tí ń jẹyọ. Èyí sì fi àyè síle ̣́ fún àwọn ọmọdé
tó ń gbo ̣́ àlo ̣́ onítàn láti kópa nínú àlo ̣́ náà nípa gbígbe orin, ìlù lílù àti ijo jijo.

4.1.2 Àyípadà ìgbà


Nínú àyípadà ìgbà ni a ti ń rí kí ìgbà yí padà fún e ̣́dá -ìtàn kan. Ẹni tí ó lo ̣́lá ní ìbe ̣́re ̣́
ìtàn lè di tálákà ní ìparí .Bákan náà, ẹni tí ó ti tálákà lè di ọlo ̣́lá t àbí olówó.Ẹni tí ó sì ti ń
gbé láàrin ènìyàn lè di ẹni tí ó ń gbé inú igbó . Àpẹẹrẹ ìtàn báyìí po ̣́ nínú ìtàn olórogún .
Bákan náà, ni o wa ninu itan ijapa s ̣́ugbo ̣́n ninu itan olorogun ni o ti wo ̣́po ̣́ jùlọ.
Nínú ìtàn “Ìjàpá sọ Àparò di èrò Igbó” , àyípadà ìgbà ṣẹle ̣́ sí Àparò ẹni tí ó ti ń gbé
ààrin ìlú tó wá di èrò inú igbó nígbà tí àwọn ẹranko yòókù rí i pé olè ni.
Bákan náà , ni a ri ape ̣́ ẹrẹ àyípadà ìgbà nínú ìtàn „Ìjàpá , Abuké Ọṣìn àti Ìgbín‟ .
Le ̣́yìn tí ìjàpá pa Abuké Ọṣìn ó paro ̣́ mo ̣́ Ìgbín pé òun ló pa á . Nígbà tí wo ̣́n fe ̣́ pa Ìgbín ó
bèèrè fún ọgbo ̣́n kan láti mọ ìdí òóto ̣́ . Nígbà tí Ìjàpá rò pé ọba tí dá Ìgbín lo ̣́lá , ó je ̣́wo ̣́ pé

19
òun lòún pa Abuké Ọṣìn , ní ìrètí pé ọba yóò dá òun lo ̣́lá . Ṣùgbo ̣́n pípa ni a pa Ìjàpá fún
ìjìyà e ̣́ṣe ̣́ re.̣́

4.1.3 Ìṣele
̣́ ̣́ Àyísódì
Ge ̣́ge ̣́ bí Ògúndjì (1991: 34) ṣe wí, “is ̣́e ̣́le ̣́ ayisodi maa n waye ninu alo -̣́ onítàn nígbà
tí àyọrísí ìgbése ̣́ ti e ̣́dá-ìtàn kan gbé bá je ̣́ àyísódì tàbí òdìkejì àyọrísí ìgbése ̣́ kan náà tí e ̣́dá
ìtàn yìí tàb í e ̣́dá ìtàn mìíràn gbé . Ìtumo ̣́ èyí ni pé òdìkejì tàbí àyísód ì àyọrísí ìgbése ̣́
àko ̣́ko ̣́ni o sẹ́ ̣́le ̣́ le ̣́yin ti e ̣́da-ìtàn kan tún gbé irú ìgbése ̣́ àkọko ̣́ yìí.
A maa n ri ape ̣́e ̣́re ̣́ isẹ́ ̣́le ̣́ ayisodi báyìí nínú ìtàn olórogún tàbí ìyàwó àti ìyáálé .
Ìyàwó yóò rin ìrìn-àjò lọ sí ìlú òdìkejì tàbí inú igbó aginjù láti ṣe àwárí ohun ìyáálé rẹ kan
tí ó sọnù tàbí bàje ̣́ lo ̣́wo ̣́ re.̣́ Nínú ìrìn-àjò yìí ni yóò ti bá aláàánú kan pàdé, eni ti yoo s ̣́oore
fún un . Nípa èyí ìyàwó lè di ọlo ̣́ro ̣́ .Bí ìyáálé bá rí irú ọro ̣́ tí ìyàwó ní yìí , òun náà yóò
pinnu lati rin iru irin -àjò be ̣́e ̣́. Ṣùgbo ̣́n ní ìgbe ỵ́ ìn ìyà, ikú àti e ̣́sín ni irú ìyáálé be ̣́e ̣́ máa ń
bá pàdé.

4.1.4 Ìrànlo ̣́wo ̣́


Nígbà tí wàhálà tí kò ní o ̣́nà àbáyọ bá dé bá olú e ̣́dá -ìtàn, ìrànlo ̣́wo ̣́ àìróte ̣́le ̣́ máa ń
dé bá olú e ̣́dá -ìtàn be ̣́e ̣́.Ìrànlo ̣́wo ̣́ àìròte ̣́le ̣́ yìí máa ń dà bí i iṣe ̣́ ìyanu tàbí ìṣe ̣́le ̣́ mérìíírí . Irú
ìrànlo ̣́wo ̣́ báyìí lè wá láti ọwo ̣́ bàbá tàbí ol ú e ̣́dá-ìtàn kan tí ó ti kú tí ó sì rí irú ìyà tí ó ń jẹ
ọmọ re ̣́, nípa iṣe ̣́ ńlá tàbí ìdánwò tí ó ń bẹ níwájú re ̣́ , tí ó sì ní láti ṣe kí ó tó ní àṣeyọrí . Irú
ìrànlo ̣́wo ̣́ báyìí máa ń jẹyọ nínú àwọn ìtàn tí kókó o ̣́ro ̣́ wọn jẹ mo ̣́ ìdánwò.

4.1.5 Ibùdó-ìṣele
̣́ ̣́
Ìṣe ̣́le ̣́ inú ìtàn àlo ̣́ kì í sáábà ní ibùdó -ìṣe ̣́le ̣́ tí ó ní orúkọ gidi tàbí orúkọ ìlú . Ìdí ni
èyí tí a fi máa ń rí ìpèdè bíi „Ní ìgbà láéláé‟ , „Ni ilu Ijapa‟ . Kò sí ibi tí ìtàn àlo ̣́ kò ti lè
ṣẹle ̣́.Ó lè je ̣́ ní o ̣́run, lábe ̣́ omi òkun àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ. Nítorí ìdí èyí ni a fi mo ̣́ pé ìṣe ̣́le ̣́ mérìíìrí
ni isẹ́ ̣́le ̣́ itan alo ̣́ je,̣́ kì í ṣe ìṣe ̣́le ̣́ ojú ayé.

20
5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, a ti s ̣́e agbeye ̣́wo awo ̣́n abuda ihun itan tí ó wà nínú àlo ̣́. Àwọn
ni: àyípadà ìgbà , àṣeṣetúnṣe, ìṣe ̣́le ̣́ àyísódì , ìrànlo ̣́wo ̣́ àti ibùdó ìṣe ̣́le ̣́ . Àwọn àbùdá yìí ni
àwọn o ̣́nà tí a fi ń gbé ìtàn kale ̣́.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


(a) Kí ni ìtumo ̣́ àhunpo ̣́-ìtàn?
(b) Ṣe àlàyé lórí àwọn àbùdá ìhun ìtàn yìí:
(i) àyípadà ìṣe ̣́le ̣́
(ii) ìrànlo ̣́wo ̣́
(iii) ibùdó-ìṣe ̣́le ̣́
(iv) àṣeṣetúnṣe ìṣe ̣́le ̣́
(v) àyípadà ìgbà

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn àlo ̣̀ onítàn. Ibadan: Y – Books.
Ogundeji, P.A. (1991) Introduction to Yoruba Oral Literature. (Ìfáárà sí Lítíréṣo ̣̀ Alohùn
Yorùbá).External Studies Programme.Adult Education Department, University of
Ibadan.
Ògúnpolú, I.B. ( 1989) “Tio ̣́ri Igbetankale ̣́ Lawujo ̣́ : Ìlànà Oṭ́ un Láti Ṣe Àtúpale ̣́ Lítíréṣo ̣́
Yorùbá” Sẹmina ni Ìrántí J .S.A. Odujinrin. Lagos. Dept. of Nigerian Languages
and Literatures, Ogun State University, Agọ Iwoye, pp. 283 – 294.

21
Ìpín Kẹta: Eḍ́ á-ìtàn àti Ìfìwàwedá
̣́
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.1 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.2 Ìtumo ̣́ e ̣́dá-ìtàn
4.3 Ìfìwàwe ̣́dá
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Lábe ̣́ ìpín yìí, àwọn ohun tí a o ye ̣́woniìtumo ̣́ e ̣́dá-ìtàn, oríṣi e ̣́dá-ìtàn àti aáyan
ìfìwàwe ̣́dá.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ake ̣́ko ̣́o ̣́ gbo ̣́do ̣́ le ṣàlàyé:
(a) ìtumo ̣́ e ̣́dá-ìtàn
(b) oríṣi àwọn e ̣́dá-ìtàn inú àlo ̣́ onítàn
(d) ìtumo ̣́ ìfìwàwe ̣́dá àti aáyan ìfìwàwe ̣́dá

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Fún wa ní àpẹrẹ àwọn e ̣́dá-ìtàn inú àlo ̣́.
2. Irú e ̣́dá-ìtàn wo ni ìjàpá?

22
4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ìtumo ̣́ edá-ìtàn
̣́
Àwọn tí ó kópa nínú àlo ̣́ onítàn ni à ń pè ní e ̣́dá-ìtàn. Ìso ̣́rí e ̣́dá-ìtàn me ̣́ta ló wà nínú
àlo ̣́ onítàn. Ìso ̣́rí kínní ni àwọn ènìyàn (e ̣́dá). Ìso ̣́rí kejì ni àwọn ẹranko . Eḳ́ ẹta sì ni àwọn
e ̣́dá mériyìírí. Lábe ̣́ ìso ̣́rí ènìyàn, lábe ̣́ ẹranko àti ẹyẹ ni a ti rí àdàbà , ẹyẹlé, o ̣́nì, erin, ehoro
àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ . Lábe ̣́ à wọn ohun mérìíyìírí sì ni àwọn iwin , òrìṣà, òkú àti àje ̣́ . Àwòrán
onígi ìsàle ̣́ yìí yóò túbo ̣́ je ̣́ kí àlàyé tí à ń ṣe yé ọ.
Eḍ́ á-ìtàn àlo ̣́ onítàn

ènìyàn e ̣́dá mérìíyìírí


ẹranko àti ẹyẹ

bàbá
iwin
ìyá ìjàpá, àdàbà òrìṣà
ìyáálé ẹyẹlé, o ̣́nì òkú
ìyàwó erin, ehoro àje ̣́
ọkọ ko ̣́lo ̣́ko ̣́lo ̣́, àkùkọ ṣìgìdì
kìnnìún , ẹkùn
Àjọṣepo ̣́ àti ìbáṣepo ̣́ máa ń wà láàrin àwọn e ̣́dá -ìtàn yìí pàápàá láàrin ènìyàn àti
ẹranko.Èyí wo ̣́po ̣́ nínú àlo ̣́ ìjàpá. Fún àpẹẹrẹ ní nú ìtàn „Ìjàpá àti Ìyá Alákàrà‟ (Babalọla
1979: 20 – 25), a ri ape ̣́e ̣́re ̣́ ibagbepo ̣́ ati ibasepo
̣́ ̣́ laarin e ̣́ranko ati eniyan . Lára àwọn e ̣́dá -
ìtàn inú ìtàn yìí ni : Ìjàpá, Ìyá Alákàrà , Omidan kan (ọmọ-alákàrà), ọba, àwọn ọdẹ,
babaláwo, o ̣́sanyìn-ẹle ̣́se ̣́ kan àti àwọn ìjòyè.
Kì í ṣe ní gbogbo ìgbà ni àwọn e ̣́dá -ìtàn inú ìtàn àlo ̣́ máa ń je ̣́ orúkọ gidi . Yàto ̣́ fún
àwọn ẹranko , ẹyẹ àti igi àti àwọn ohun mìíràn t í kò ní e ̣́mí ṣùgbo ̣́n tí wo ̣́n ní orúkọ bí i
àpáta, òjò, omi, abbl.Àwọn ènìyàn inú àlo ̣́ kì í ní orúkọ pàtó . Irú iṣe ̣́ tí wọn ń ṣe tàbí ipò tí
wo ̣́n wà ní a fi ń pè wo ̣́n . Fún àpẹẹrẹ: Ọba, Ìjòyè, Ìyá-alákàrà, Ọdẹ, Àgbe ̣́, Bàbá-Ẹle ̣́mu,
o ̣́re ̣́Alábahun, ọmọ-ọba, ìyàwó, ìyáálé àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ. Yánníbo, ìyàwó Ìjàpá ni o fe ̣́re ̣́ je ̣́ e ̣́ni
tí a fún lórúkọ.

23
4.2 Ìfìwàwedá
̣́
Ó yẹ kí á ṣàlàyé péìfìw àwe ̣́dá yàto ̣́ sí e ̣́dá-ìtàn.Ìfìwàwe ̣́dá ni awo ̣́n o ̣́gbo ̣́n ti onko ̣́we
lò láti mú kí àwọn e ̣́dá -ìtàn inú iṣe ̣́ ọn à re ̣́ ní àwòmo ̣́ ènìyàn tàbí ìwà tí òǹko ̣́wé gbé wọ
àwọn e ̣́dá -ìtàn rẹ . Lóòóto ̣́ a kò l è sọ ní pàtó pé òǹko ̣́wé báyìí báyìí ni ó kọ ìtàn , àlo ̣́,
ṣùgbo ̣́n ìtumo ̣́ ìfìwàwe ̣́dá yìí náà bá ti e ̣́dá-ìtàn inú àlo ̣́ mu.
Ge ̣́ge ̣́ bí ó ṣe jé káári -ayé, ohun marun-ún ni a lè fi ṣe ìtúpale ̣́ ìwà e ̣́dá-ìtàn inú ìtàn
kan:
(i) ohun ti aso ̣́tan so ̣́ nipa e ̣́da-ìtàn
(ii) ohun ti awo ̣́n e ̣́da-ìtàn yòókù sọ nípa re ̣́
(iii) ohun ti e ̣́da-ìtàn náà bá sọ nípa ara re ̣́
(iv) ìṣesí àti ìhùwàsí e ̣́dá-ìtàn náà.
(v) ìrísí àti orúkọ e ̣́dá-ìtàn náà.
Ohun ti aso ̣́tan ba so ̣́ nipa e ̣́da -ìtàn ṣe pàtàkì púpo ̣́ láti júwe irú ènìyàn tí e ̣́dá -ìtàn náà je .̣́
Bákan náà ni ohun tí àwọn e ̣́dá -ìtàn yòókù bá sọ nípa e ̣́dá -ìtàn kan náà ṣe pàtàkì láti ṣe
àpèjúwe irú ẹni tí e ̣́dá-ìtàn náà je ̣́. Nígbà mìíràn, e ̣́dá-ìtàn kan lè ṣe àpèjúwe ara re ̣́. Èyí náà
tún máa ń je ̣́ kí á mọ irú ènìyàn tí e ̣́dá -ìtàn náà je ̣́. Ìṣesí àti ìhùwàsí e ̣́dá-ìtàn kan náà máa ń
ràn wá lo ̣́wo ̣́ láti mọ irú ẹni tí ó je.̣́ Fún àpẹẹrẹ ìwà Ìjàpá nínú o ̣́po ̣́lọpo ̣́ ìtàn àlo ̣́ ìjàpá je ̣́ kí a
lè sọ irú e ̣́dá-ìtàn tí Ìjàpá je ̣́.Àwọn ìwà bí olè jíjà, ojúkòkòrò, àìníte ̣́lo ̣́rùn, iro ̣́ pípa àti àwọn
ìwà búburú mìíràn tí Ìjàpá ń hù ní à ń lò láti ṣe àpèjúwe re ̣́ . Gbogbo akitiyan yii ni a n pe
ní ìfìwàwe ̣́dá.
Ní ìgbe ̣́yìn, a le lo irisi tabi oruko ̣́ e ̣́da -ìtàn láti s ̣́e apejuwe re .̣́ Fún àpẹẹrẹ orúkọ àti
ìnagijẹ tí a fún Ìjàpá je ̣́ kí á mọ irú e ̣́dá -ìtàn tí ó je ̣́ – „Ijapa o ̣́lo ̣́gbo ̣́n -e ̣́we ̣́‟, „Ijapa Tiroko
Ọkọ Yánníbo‟. Oríkì ìjàpá nínú àwọn àlo ̣́ onítàn náà júwe ìrísí re:̣́
Ìjàpá Tìrókò Ọkọ Yánníbo
Ẹse ̣́ danindanin bí àran o ̣́pẹ
Tó ko ̣́léko ̣́lé, tó fi ìrán bà á je ̣́
Tí ń lọ láàrin e ̣́pà, típàko ̣́ re ̣́ ń hàn fírífírí
Ó ní ọpe ̣́lọpe ̣́ pé òun ga!

24
Nínú oríkì yìí, a le juwe irisi Ijapa bayii : Ó je ̣́ ẹranko tàbí èdá -ìtàn tí ẹse ̣́ re ̣́ yí bí i
àran o ̣́pẹ, e ̣́dá-ìtàn tó ní igbá le ̣́yìn àti ìrán ní ìdí re ̣́ . Ìlà méjì tí ó gbe ̣́yìn je ̣́ kí á mo ̣́ pé
ẹranko tàbí e ̣́dá-ìtàn kúkurú, tí kò ga ni Ìjàpá.

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, a ti s ̣́e agbeye ̣́wo itumo ̣́ ati orisị́ e ̣́da -ìtàn tó wà. Ìso ̣́rí me ̣́ta ni a
pín àwọn e ̣́dá -ìtàn sí : ènìyàn, ẹranko àti ẹyẹ àti e ̣́dá mérìíyìírí . Bákan náà , ni a sẹ́
àgbéye ̣́wò ohun tí ìfìwàwe ̣́dá je ̣́ àti àwọn o ̣́nà tí a lè lò láti ṣe àpèjúwe e ̣́dá -ìtàn kan tàbí irú
ẹni tí ó je.̣́

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Ṣàlàyé lórí irú àwọn e ̣́da-ìtàn tó wà nínú àlo ̣́ onítàn.
2. Kí ni ìtumo ̣́ ìfìwàwe ̣́dá?
3. Àwọn ohun márùn-ún wo ni a lè lò láti fi ṣàpèjúwe e ̣́dá-ìtàn kan?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Ogundeji, P.A. (1991) Introduction to Yoruba Oral Literature. (Ìfáárà sí Lítíréṣo ̣̀ Alohùn
Yorùbá).External Studies Programme.Adult Education Department, University of
Ibadan.
Dasylva, A. O. (2017) “Folklore, Oral Traditions and Oral Literature” in Toyin Falo ̣́la and
Akintunde Akinye ̣́mi (ed.) Culture and Customs of the Yoruba.USA Pan-African
University press, pp. 139 – 158.

25
MÓDÙ KẸTA: ÌLÒ ÈDÈ ÀTI BÁTÀNÌ GBÓLÓHÙN ÌṢÍDE ÀTI ÌPARÍ ÀLO ̣́

Àkóónú Ìpín kínní : Ìlò Èdè


1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Àfiwé tààrà
4.2 Àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́
4.3 Ìfohunpènìyàn/Ìsọhundènìyàn
4.4 Àsọdùn/Asọrégèé
4.5 Ìfìrómo ̣́rísí/Ìfìrógbóyeyọ
4.6 Àwítúnwí
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Ní abe ̣́ Módù yìí ni a ó ti ṣe àgbéye ̣́wò o ̣́nà ìṣọwo ̣́loèdè inú àlo ̣́ àti àwọn bátànì ìṣíde àti
ìparí àlo ̣́. Bátànì ìlò èdè nínú àlo ̣́ ni ìṣíde àti ìparí àlo ̣́ je. ̣́
Ìpín kínní: Ìlò Èdè
Ìpín kejì: Bátànì Gbólóhùn Ìṣíde Àlo ̣́
Ìpín kẹta: Bátànì Gbólóhùn Ìparí Àlo ̣́
Ìlò èdè je ̣́ ohun pàtàkì tí kò ṣe é fojú fò rárá nínú ìtúpale ̣́ iṣe ̣́ ọnà lítíréṣo ̣́ kan bí i àlo ̣́
onítàn. Lílo èdè tó dára máa ń je ̣́ kí ìtàn múnilo ̣́kàn gidi . Èdè ni ó ń mú ìtàn dùn nínú àlo ̣́
yòówù tí apàlo ̣́ fe ̣́ pa.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, o gbo ̣́do ̣́ mo ̣́:
1. ohun ti ilo ede je ̣́
26
2. díe ̣́ lára àwọn ọnà èdè tó jẹyọ nínú àlo ̣́

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Kí ni ìlò-èdè?
2. Fún wa ni ape ̣́re ̣́ o ̣́na-èdè me ̣́ta.

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Àfiwé Tààrà
Ọnà èdè yìí máa ń jẹyọ púpo ̣́ nínú àlo .̣́ Ohun meji to jo ̣́ra ni a fi n we ara wo ̣́n ninu
àfiwé tààrà. Ìjọra yìí lè je ̣́ nípa ìrísí, ìrírí àti ìhùwàsí. Àfiwé tààrà ní àwọn o ̣́ro ̣́ kan tí ó ń ṣe
ato ̣́ka re ̣́. Àwọn o ̣́ro ̣́ náà ni: bíi, bí, tó. Àwọn o ̣́ro ̣́ yìí je ̣́ o ̣́ro ̣́-ìṣe tí ó ń fi ìrísí hàn.
Nínú ìtàn Ìjàpá àti Àwọn Èrò Ọjà (Oṕ̣ ádo ̣́tun 1994: 80 – 83) a ri ape ̣́e ̣́re ̣́ afiwe taara
níbe ̣́:
(i) Àwọn ọmọ lòun tú n be ̣́re ̣́ si pa sile ̣́ bí ìdin yìí (o.i. 80). Èyí túmo ̣́ sí pé àwon ọmọ
Ìjàpá po ̣́ bí ìdin ṣe ń po ̣́.
(ii) „Onikaluku ba gba orin naa bí ẹni gba igbá ọtí (o.i. 82).
Ní ayé àtijo ̣́ níṣe ni à ń gbé igbá ọtí kiri . Bí ẹni kan bá ti mu ọtí tàbí ẹmu nínú igbá
yóò gbé e fún ẹni tí ó te ̣́lé e.
Nínú ìtàn „Ìjàpá àti Àdàbà jọ dá oko kan‟ a rí àfiwé tààrà níbi tí aso ̣́tàn ti ń
ṣe àpèjúwe bí oko tí Ìjàpá àti Àdàbà jọ dá ṣe tóbi tó.
(iii) Oko ye ̣́n kan lo ̣́ gbansasa bi omi okun ni
Nínú ìtàn „Ìjàpá àti Àgàràmo ̣́kù (Babalọla, 1979: 8).
(iv) Ó ń faho ̣́n po ̣́n nu béré bíi ejò (o.i. 7).

4.2 Àfiwé Ẹlelo


̣́ ̣́o ̣́
Àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́ náà ni à ń pè ní „me ̣́táfo ̣́‟. Àfiwé inú ọnà èdè yìí kò lọ tààrà bíi ti
àfiwé tààrà. Ìjọra tí ó dálé orí ìhùwàsì àti ìrísí náà gbo ̣́do ̣́ wà nínú ohun méjì tí a fi ń wé
ara wo ̣́n. Fún àpẹẹrẹ tí a bá ní:
(i) Ajá ni ọmọ náà

27
Ohun ti a n sẹ́ ni pe, à ń fi ìwà ọmọ náà wé ti ajá. Èyí ni pé ọmọ náà ń ṣe ìṣekúṣe.
Nígbà mìíràn , o ̣́gangan ìṣe ̣́le ̣́ ni ó máa ń je ̣́ kí á mọ ìtumo ̣́ àfiwé ẹ le ̣́lo ̣́o ̣́ nítorí pé
àfiwé kan lè ní ju ìtumo ̣́ kan lọ. Fún àpẹẹrẹ:
(ii) Ẹle ̣́de ̣́ ni obìnrin náà
Ìtumo ̣́ èyí pín sí o ̣́nà me ̣́ta. Oṇ́ à kínní ni pé, o ̣́bùn ni obìnrin náà. Èkejì sì ni pé obìnrin náà
bímọ púpo ̣́ bí ẹle ̣́de ̣́. Ìkẹta ni pé ó ní inú fùfù (ìbínú àbíjù).
Àwọn onímo ̣́ kan tile ̣́ sọ pé àfidípò (metonymy) ní àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́ je ̣́ nítorí à ń fi ohun
kan di ohun miiran. Fún àpẹẹrẹ nínú oríkì Yorùbá, a le fi ìnagijẹ dípò orúkọ ẹnìkan.
(iii) Adéyẹmí Alówólódù
Nínú àpẹẹrẹ yìí, Alówólódù le è ro ̣́pò Adéyẹmí . Bí a bá ti pè é, a á mo ̣́ pé òun (Adéyẹmí)
ni a n pe.
Àpẹẹrẹ àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́ tàbí àfidípò náà po ̣́ nínú àlo ̣́ àpamo ̣́ àti òwe Yorùbá
Àpẹẹrẹàfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́ wà nínú ìtàn „Ìjàpá ká ehín Erin‟.
(iv) kàkà kí ewé àgbọn ro ,̣́ líle ni ń le sí i. (o.i. 36)
Àpẹẹrẹ yìí náà je ̣́ òkan nínú òwe Yorùbá . Ṣùgbo ̣́n àìsàn baba Yánníbo, ìyàwó Ìjàpá ni a fi
ń wé ewé àgbọn nínú òwe yìí.
(v) egungun-náín-ẹran-to ̣́ro ̣́ ni (o.i. 36)
Àfiwé yìí ń ṣe ìrísí baba Yánní bo nígbà tí ó ń ṣàìsàn . Ìtumo ̣́ èyí ni pé ó rù gidi ; kò le ̣́ran
lára.
(vi) „Abokorẹrẹ ni awo ̣́n ara adugbo maa n pe gbogbo wo ̣́n‟
Àpẹẹrẹ yìí jẹ mo ̣́ àpẹẹrẹ (iii) lókè. Nítorí pé àwọn o ̣́re ̣́ me ̣́fà (Ejò, Ẹmo ̣́, Àfè, Ẹdá, Eḷ́ írí àti
Ẹgbárá) inú àlo ̣́ yìí je ̣́ àgbe ̣́ tí oko wọn sì tóbi , àwọn ènìyàn fún wọn ní ìnagijẹ yìí , èyí tí ó
di oruko ̣́ wo ̣́n . Nínú ìtàn „Ìdí tí Ejò fi ń pa Eku jẹ‟ ni a ti mú àpẹẹrẹ yìí (Oṕ̣ ádo ̣́tun 1994:
12).

4.3 Ìfohunpènìyàn /Ìsọhundènìyàn


Kí á gbé ìwà , ìhùwàsí tàbí ìrísí ènìyàn wọ ohun tí kì í ṣe ènìyàn ni à ńpè ní
ìfohunpènìyàn. Nínú ọnà-èdè yìí ni ohun tí kì í ṣe ènìyàn tàbí ohun tí kò le ̣́mìí ti ń hùwà
ènìyàn kan tàbí ní àbùdá ènìyàn . Ọnà èdè yìí ni àwọn mìíràn náà ń pè ní Ìsọhundènìyàn .

28
Ọlábo ̣́dé (1992: 42) tile ̣́ ṣe àkójọpo ̣́ lilo “e ̣́yà ara ènìyàn láti to ̣́ka sí ohun tí kì í ṣe ènìyàn .
Àwọn òkú ìsọhundènìyàn ni Ọlá bo ̣́dé pe awo ̣́n ape ̣́e ̣́re ̣́ yii nitori pe wo ̣́n ti di baraku ninu
èdè Yorùbá:
Orí igi
Ẹnuo ̣́nà
Etí odò
Ojú ile ̣́
Gbogbo awo ̣́n ohun alaile ̣́mii ti ki i sẹ́ eniyan ti a fa ila si loke yii ni wo ̣́n ni abuda eniyan
tí a fi ń ṣe àpèjúwe wọn . Àpẹẹrẹ ìfohunpènìyàn tàbí ìsọhundènìyàn náà po ̣́ nínú àlo ̣́
onítàn:
(i) „Apata yii te ̣́ju‟
(ii) „Oǵ̣ be ̣́ni Apata‟
(Babalọla, 1979: 6)
(iii) Ó bá wọlé, ó sán ṣòkòtò re ̣́, ó gbé igbá re ̣́, ó mú àdá re.̣́
(Babalọlá 1979: 29)
Ìjàpá ni ó ṣe bí ènìyàn nínú àlo ̣́ „Ijapa ati Abo ̣́n-ẹyìn‟.
Nínú àlo ̣́ ìjàpá, gbogbo awo ̣́n e ̣́ranko mu awo ̣́n alo ̣́ yii ni o n huwa bi eniyan . Wo ̣́n
ń so ̣́ro ,̣́ wo ̣́n ń ní ìtàkuro ̣́sọ , wo ̣́n ń ní ọba , wo ̣́n ń ní ìdílé àti be ̣́e ̣́ lọ , àwọn ẹbọra n so ̣́ro ̣́,
o ̣́sanyìn ẹle ̣́se ̣́ kan, méjì, me ̣́fà wà. Fún ìdí èyí, a le so ̣́ pe iso ̣́hundeniyan ni o je ̣́ koko o ̣́na -
èdè inú àlo ̣́ onítàn.

4.4 Àsọdùn/Àsọrégèé
Ge ̣́ge ̣́ bí o ̣́ro ̣́ tí à ń pe ọnà -èdè yìí, sísọ àsọdùn ni ó ro ̣́mo ̣́ . A le so ̣́ pe o ̣́na -èdè yìí
ro ̣́mo ̣́ ohun tí Yorùbá ń pè ní à-sọ-ré-kọjá-ewé. Jíjúwe ìṣe ̣́le ̣́ kan tàbí ohun kan tí kò le ṣẹle ̣́,
ṣùgbo ̣́n tí ó lè mú ìtàn kan dùn.
Àpẹẹrẹ ọnà -èdè yìí po ̣́ nínú àlo ̣́ onítàn . Ẹ je ̣́ kí á wo àyọlò yìí nínú „Ìtàn Ìjàpá àti
Àgàràmo ̣́kì‟ :
(i) Ìjàpá gbé Àgàràmo ̣́kù délé Ọba ; ó so ̣́ o ̣́ kale ̣́ . Àgàràmo ̣́kù ní kí wo ̣́n be ̣́re ̣́ sí í se
oúnjẹ fún òun ; wo ̣́n be ̣́re ̣́, wo ̣́n ń sè , wo ̣́n ń so ̣́ , gbogbo e ̣́ran to wa niluu : ewúre ̣́,

29
àgùntàn, adìẹ, pe ̣́pe ̣́yẹ, àgbò, òbúkọ, ẹranńlá, gbogbo re ̣́ ni wo ̣́n se fun Agaramo ̣́ku ,
ó sì ń jẹ wo ̣́n. Agàràmo ̣́kù rè é, kì í yó; bó ti ń jẹ be ̣́e ̣́ ló ń ṣu, ló ń to ̣́.
(Babalọlá, 1979: 11)
A ri i ninu ayo ̣́lo yii pe aso ̣́dun wa nibe ̣́ . Ìbéèrè tó lè wá sí ọkàn wa ni pé:
Ǹje ̣́ èyí lè ṣẹle ̣́ kí ẹnìkan jẹ gbogbo ẹran yìí tán ? Àsọdùn ni èyí je ̣́ , ṣùgbo ̣́n ó mú
ìtàn náà dùn.
(ii) Bákan náà nínú ìtàn Ìjàpá àti Ìyá Ẹle ̣́pà a rí àsọdun:
Le ̣́yìn èyí, Ọba ránṣe ̣́ pe gbogbo àwọn irúnmọle ̣́ ìlú . Nígbà tí
àwọn imọle ̣́ náà dé iwájú Ọba , Ọba be ̣́ wo ̣́n pé ó kàn wo ̣́ n, ó
kan agbaagba , pé lo ̣́jo ̣́-ọjà ijo ̣́ me ̣́rin òní, wọn ó bá òun mú olè
afiniṣe ̣́sín náà. Oṣ́ anyìn ẹle ̣́se ̣́me ̣́wàá wà ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́ me ̣́sàn-án
wà ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́me ̣́jọ wà ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́méje wà ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́me ̣́fà wà
ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́ márùn-ún wà ń be ̣́; ẹle ̣́se ̣́ me ̣́rin wà ń be;̣́ ẹle ̣́se ̣́ me ̣́ta
wà ń be;̣́
(Babalọla 1973: 5)
4.5 Fìrómo ̣́rísí
Àpẹẹrẹ fìrómo ̣́rísí tàbí fìrógbóye yo ̣́ po ̣́ nínú àlo ̣́ onítàn .A o s ̣́e aye ̣́wo die .̣́ Nínú ìtàn „Ìjàpá
àti Àdàbà jọ dá oko kan‟ ni a ti rí àpẹẹrẹ yìí:
(ix) Àwọn o ̣́re ̣́ méjì yìí wá jọ dá oko kan , oko yii tó ibùso ̣́ méjì ní ìbú , ó tó ibùso ̣́ me ̣́ta
ní ìró. Oko ye ̣́n kan lo ̣́ gbansasa bi omi okun ni . Wo ̣́n wá gbin oríṣiríṣi ohun tí ẹnu
ń jẹ sínú re :̣́ iṣu lọ salalu, gbogbo re ̣́ ta bo ̣́kùàbo ̣́kùà, wo ̣́n san ebè ke ̣́rẹke ̣́rẹ bí e ̣́gbe ̣́
ògiri ògbólógbòó ilé; e ̣́ge ̣́ ta fálafàla; àgbàdo gbo ̣́mọpo ̣́n do ̣́ǹkùdọnku , ewébe ̣́ lọ súà
bí i koríko inú pápá , wo ̣́n dúdú minrinminrin bí ewéko etípadò , gbogbo ohun
o ̣́gbìn wọn ṣe dáradára.
(Babalọlá 1973: 8)
(x) Akèǹgbè rún wómúwómú – p. 19
(xi) Ile ̣́ ń ro ̣́ gìrìgìrì, gbogbo igi igbo n mi rìyàrìyà –p. 22
(xii) wo ̣́n ṣèèṣì tẹ ìgbákọ mo ̣́le ̣́, ó fo ̣́ pe ̣́kẹpe ̣́kẹ –p. 34

30
4.6 Àwítúnwí
Oríṣi àwítúnwí méj ì ló wà . Àwọn ni : àwítúnwí ẹle ̣́yọ o ̣́ro ̣́ àti àwítúnwí oníhun
gbólóhùn. Ṣùgbo ̣́n a lè ṣe atunpin onihun gbolohun si o ̣́na meji : àwítúnwí àpólà gbólóhùn
àti àwítúnwí odidi gbólóhùn. A le lo aworan onígi láti je ̣́ kí òye yìí túbo ̣́ yéwa yekeyeke :
Àwítúnwí

Ẹle ̣́yọ o ̣́ro ̣́ Oníhun gbólóhùn

Àpólà gbólóhùn Odindi gbolohun


A o wo ape ̣́e ̣́re ̣́ o ̣́ko ̣́o ̣́kan awo ̣́n orisị́ awitunwi yii bi wo ̣́n s ̣́e jẹyọ nínú àlo ̣́.
(i) Àwítúnwí Ẹle ̣́yọ Oṛ́ o ̣́
(a) onígbà mú igbá, onífe mú ife
(b) Oṕ̣ á, Afúnmọ-lára-bí-ọye ̣́, Oṕ̣ á, Oǵ̣ bo ̣́n-rírì-hara-ọmọ-nù
(d) Ó fìyà jẹ ọkùnrin , ó fìyà jẹ obìnrin ; tọmọge-tadélébo ̣́ ló jìyà ló jewé ìyà
pe ̣́lú. (Babalọlá 1973: 35 – 36)
(ii) Àwítúnwí Àpólà Gbólóhùn
(a) Ọmọ-ọwo ̣́ kì í kú lójú ọwo ̣́, be ̣́e ̣́ ni ọmọ-ẹse ̣́ kì í kú lójú ẹse ̣́, àwọn ọmọ re ̣́ kò
ní kú lójú rẹ.
(b) Dájúdájú wo ̣́n ń rí bìkan bá wo ̣́ o ̣́, wo ̣́n ń ríkan s ̣́e kan.
(d) Nígbà tí wo ̣́n dé oko, Ìjàpá be ̣́re ̣́ sí í wa is ̣́u, ó wà kínní, ó wà kejì, ó wà kẹta,
ó wà á títí me ̣́fà pé. (Babalọlá 1973: 39 – 41)
(iii) Àwítúnwí Gbólóhùn
Àpẹẹrẹ àwítúnwí gbólóhùn kún inú orin àlo ̣́ fo ̣́fo ̣́. Ó fe ̣́re ̣́ má sí ì orin àlo ̣́ kan tí kò
ní i nínú. Nínú orin ìtàn Ìjàpá àti Ajá lọ jí iṣu wà, a ri ape ̣́e ̣́re ̣́ o ̣́na-èdè yìí:
Lílé: Ajá ó, ràn mí lẹrù,
Ègbè: Ṣémbélékeṣé
Lílé: Ajá ó, ràn mí lẹrù,
Ègbè: Ṣémbélékeṣé
Lílé: Bó ò bá ràn mi le ̣́rù, má ké s‟Ólóko,

31
Ègbè: Ṣémbélékeṣé
Lílé: Bólóko gbo ̣́ o, a mu o ̣́ de.
Ègbè: Ṣémbélékeṣé
Lílé: A mu ọ dè, á gbà ọ níṣu,
Ègbè: Ṣémbélékeṣé
Lílé: Ajá ó, ràn mí lẹrù,
Ègbè: Ṣémbélékeṣé

Nínú orin àlo ̣́ òkè yìí, èyí tí ó ní àbùdá lílé àti ègbè, a ri ape ̣́e ̣́re ̣́ awitunwi gbolohun ninu
lílé àti awitunwi e ̣́le ̣́yo ̣́ o ̣́ro ̣́ ninu egbe. Gbogbo orin inu alo ̣́ ni o ni batani yii. Ẹ je ̣́ kí á wo
àpẹẹrẹ mìíràn. A mu ape ̣́re ̣́ yii lati inu itan „Ijapa ati Buje‟ (Babalọlá 1973: 161 – 166):
Bùjé, Bùje pa mi o, 1
Terebùjé
Bùjé, Bùje pa mi o,
Terebùjé
Oko mi mo n ro 5
Terebùjé
Oṇ́ à mi mò ń ye ̣́,
Terebùjé
Bùjé ni n wá yà p‟ejò
Terebùjé 10
Ò pejò pojúgun
Terebùjé
Ò be ̣́re ̣́ gb‟Áhun po ̣́n
Terebùjé
Ò gbáhun po ̣́n, gb‟Ahun jo 15
Terebùjé
Gbé mi síbàdí ká re lé
Terebùjé
Ìbàdí layé wà
Terebùjé
Ìbàdí layé wà 20
Terebùjé

32
Gbogbo oris ̣́i awitunwi me ̣́te ̣́e ̣́ta ti a ti me ̣́nuba loke yii ni o je ̣́yo ̣́ ninu orin yìí. bí a ti rí
àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́ pàápàá nínú ègbè orin yìí, ni a ri awitunwi apola gbolohun ni ila 5, 7,
13, 15. Àwítúnwí gbólóhùn ni a rí ní ìlà 1, 3, 19 àti 21.

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìpín yìí, a ti s ̣́e agbeye ̣́wo ilo -èdè nínú àlo ̣́ onítàn àti oríṣiríṣi ọnà -èdè tó jẹyọ
àti àpẹẹrẹ wọn. Lára àwọn ọnà-èdè tí a rí fàyọ nínú àlo ̣́ onítàn ni àfiwé tààrà, àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ̣́,
ìfohunpènìyàn tàbí ìsọhun dènìyàn, àsọdùn tàbí àsọrégèé , fìrómo ̣́rísí tàbí fìrógbóyeyọ , àti
àwítúnwí.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Ipa wo ni ede n ko ninu itan?
2. Ṣe e ̣́kúnre ̣́re ̣́ àlàyé àpẹrẹ lórí àfiwé tààrà nínú àlo ̣́ kan ti o ka.
3. Kí ni àwọn àbùdá inú ìfo ̣́ro ̣́dárà?
4. Ṣàlàyé lórí ìfohunpènìyàn tàbí ìsọhundènìyàn pe ̣́lú àpẹẹrẹ láti inú àwọn àlo ̣́ tí o ti
kà.
5. Wá àlo ̣́ kan tí ó ní àsọdùn tàbí àsọrégèé kí o sì ṣe àtúpale ̣́ ọnà-èdè náà.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Babalọlá, A. (1973) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kínní. Ibadan: University Press Ltd.
Babalọlá, A. (1979) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kejì. Ibadan: University Press Ltd.
Ọlábo ̣́dé, A. (1992) LIY 371: Ìmo ̣̀ Ìṣọwoḷ̀ oèdè Yorùbá. University of Ibadan.
External Studies Programme.
Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

33
Ìpín Kejì: Bátànì Gbólóhùn Ìṣíde àti Ìparí Àlo ̣́
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Ní abe ̣́ ìpín yìí,a o s ̣́e agbeye ̣́wo a wọn ọnà èdè tó j ẹyọ nínú bátànì gbólóhùn ìṣíde àti ìparí
àlo ̣́.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, o gbo ̣́do ̣́ le mo ̣́:
1. àwọn oríṣiríṣi bátànì ìṣíde àti ìparí àlo ̣́.
2. àwọn ọnà-èdè tó jẹyọ nínú àwọn bátànì yìí.

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Oṇ́ à wo ni à ń gbà ṣíde àlo ̣́?
2. Bátànì wo ni à ń lò parí àlo ̣́?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Bátànì Gbólóhùn Ìṣ íde Àlo ̣́
Oríṣi ìtàkuro ̣́sọ ni ó máa ń wáyé láàrin apàlo ̣́ àti àwọn olùgbo ̣́ re ̣́ tí ó je ̣́ àwọn
ọmọdé. Lílo ète ìtàkuro ̣́sọ yìí wà fún ìtanijí àwọn ọmọdé yìí àti láti mú wọn je ̣́ akópa nínú
ìtàn náà. Àpẹẹrẹ àwọn ìṣíde yìí ni a ó rí ní ìsàle ̣́ yìí:
On
̣́ à ìṣídé – 1

34
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!...... 1
Àwọn ọmọdé: Ààlo ̣́
Apàlo ̣́: Ní ọjo ̣́ kan…
Àwọn ọmọdé: Ọjo ̣́ kan kì í tán láyé ……. 5
Apàlo ̣́: Ní ìgbà kan
Àwọn ọmọdé: Ìgbà kan ń lọ, ìgbà kan ń bo ̣́, ọjo ̣́ ń gorí ọjo ̣́.
Apàlo ̣́: Ní ìlú Ìjàpá ………..
Nínú ìṣíde yìí , a ri ape ̣́e ̣́re ̣́ iso ̣́ronfesi laarin apalo ̣́ ati awo ̣́n olugbo ̣́ re ̣́ (àwọn
ọmọdé). Ọnà èdè kan tí ó wo ̣́po ̣́ jùlọ ní nú ìṣíde àlo ̣́ yìí ni àwítúnwí . Bí a ṣe rí àpẹẹrẹ
àwítúnwí o ̣́ro ̣́ be ̣́e ̣́ ni a rí àpẹẹrẹ àwítúnwí àpólà gbólóhùn.
Ní ìlà kínní àti èkejì ni a ti rí àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́ . Ìlà 4 – 5 (àpólà gbólohùn), 6 – 7
(àpólà gbólóhùn). Ní ìlà 1 – 2, a ri iyato ̣́ ninu ohun ori silebu ila 2 èyí tí ó sì mú kí ọnà
èdè ìfo ̣́ro ̣́dárà jẹyọ.
Ọ́nà ìṣíde àlo ̣́ – 2
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!...... 1
Àwọn ọmọdé: Ààlo ̣́
Apàlo ̣́: Bàbá kanwà
Àwọn ọmọdé: Ó wà bí e ̣́wà
Apàlo ̣́: Óbí ọmọ kan 5
Àwọn ọmọdé: Óbí i, bí i, bí i
Apàlo ̣́: Kò rí bí
Nínú ìṣíde yìí náà ni a ti rí àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́ àti àpólà . Ìlà 1 àti 2 (àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́) Ìlà 3
àti 4 (àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́) ìlà 5 àti 6 (àwítúnwí àpólà gbólóhùn).
Nínú àlo ̣́ oríṣiríṣi ọnà èdè ni a lè rí àwọn ọnà èdè bí i àfiwé tààrà , àfiwé ẹle ̣́lo ̣́o ,̣́
àwítúnwí, ìfo ̣́ro ̣́dárà àti be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lọ . A o fa awo ̣́n ape ̣́e ̣́re ̣́ o ̣́na ede yo ̣́ ninu awo ̣́n alo ̣́ ti a o ri
ní Módù karùn-ún àti e ̣́kẹfà.
Ọ́nà ìṣíde àlo ̣́ – 3
Apàlo ̣́: Ààlo ̣́ o!......
Àwọn ọmọdé: Ààlo ̣́

35
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ mi dá fìrìgbágbòó, ó dálérí
Ìjàpá Tìrókò Ọkọ Yánníbo, Àtíòro,
Yemọja, Oṇ́ ì àti Ẹkùn.
Ìṣíde yìí kò gùn tó méjì àko ̣́ko ̣́ nítorí ìgbése ̣́ me ̣́ta péré ló ní . Ní ìlà 1 àti 2 ni a ti rí
àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́.
Nítorí pé àlo ̣́ onítàn kò ní ìgbà àti àkókò kan pàtó tí a dá a síle ̣́ , àwọn ìpèdè bí i „Ní
ìgbà kan‟, Ní ọjo ̣́ kan‟, „Ni igba laelae‟, „Ni aye atijo ̣́ ati be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ lo ̣́ ni a ń lò láti be ̣́re ̣́ ìtàn
àlo ̣́.

4.2 Bátànì Gbólóhùn Ìparí Àlo ̣́


Bí ó ṣe wà nínú ìṣídé àlo ̣́, be ̣́e ̣́ náà ni àwọn bátànì ìlò èdè wà fún ìparí àlo ̣́ . Le ̣́yìn tí
apàlo ̣́ bá fi sọ ọgbo ̣́n tí ó fe ̣́ kí àwọn ọmọdé ko ̣́ nínú àlo ̣́ ni yóò sọ báyìí pé:
Apàlo ̣́: Ìdí àlo ̣́ mi rè é gbáńgbáláká
Ìdí àlo ̣́ mi rè é gbàǹgbàlàkà
Bí n bá puro ̣́ kí agogo ẹnu mi má rò ó
Ṣùgbo ̣́n bí n ò bá puro ̣́, kí agogo ẹnu mi ró le ̣́e ̣́mẹta
Ó di pó… pò…pó!
Àwọn ọmọdé: Ẹ ò puro ̣́ baba
Apàlo ̣́ máa ń lo bátànì ìlò èdè yìí láti je ̣́ kí àwọn ọmọdé rò pé òóto ̣́ ni ìtàn àlo ̣́ yìí ṣẹle ̣́.
Nítorí pé àlo ̣́ je ̣́ ìtàn àtinúdá tí à ń pa fún àwo ọmọdé láti dá wọn le ̣́ko ̣́o ̣́ , apàlo ̣́ máa ń
gbìyànjú láti mú kí àwọn ọmọdé máa rò pé ìtàn ìṣe ̣́le ̣́ gidi ni. Ìdí ni èyí tí apàlo ̣́ yóò ki ọwo ̣́
bọ inú e ̣́re ̣́ke ̣́ re ̣́ le ̣́e ̣́mẹta láti je ̣́ kí ó ró. Èyí ni apàlo ̣́ ń pè ní agogo ẹnu. Èyí ni ó sì fi òte lé e
pé òóto ̣́ ni ìṣe ̣́le ̣́ inú ìtàn náà . Ìdí sì ni èyí tí àwọn ọmọdé náà yóò fi pariwo pé „Ẹ ò puro ̣́
baba‟.
Nínú bátànì ìparí àlo ̣́ yìí ni a ti rí àwọn ọnà èdè wo ̣́nyí: àwítúnwí gbólóhùn (ìlà 1 &
2) ìfo ̣́ro ̣́dárà – ìlà 1 àti 2 (gbáńgbáláká/gbàǹgbàlàkà), àwítúnwí àpólà gbólóhùn (ìlà 3 àti
4).

36
5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, a ti ṣe àye ̣́wò ìlò èdè nínú àlo ̣́ pàápàá àwọn tó wà nínú bátànì
gbólóhùn tí a fi ń ṣíde àlo ̣́ àti èyí tí a fi ń parí àlo ̣́ . A ti wo oris ̣́iris ̣́i itakuro ̣́so ̣́ ti o maa n
wáyé láàrin apàlo ̣́ àti àwọn olùgbo ̣́ re ̣́. A ri ape ̣́e ̣́re ̣́ awo ̣́n o ̣́na ede wo ̣́nyi ninu batani
gbólóhùn ìṣíde àti ìparí àlo ̣́: àwítúnwí ẹyọ o ̣́ro ̣́, àwítúnwí àpólà gbólóhùn, ìfo ̣́ro ̣́dárà àti be ̣́e ̣́
be ̣́e ̣́ lọ.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Fún wa ní ó kéré tán àpẹẹrẹ ìṣíde àlo ̣́ méjì.
2. Àwọn ọnà èdè wo ni o rí fàyọ nínú àwọn ìṣíde àlo ̣́ náà?
3. Bátànì gbólóhùn wo ni a fi ń parí àlo ̣́?
4. Ṣe àpèjúwe àwọn ọnà èdè inú bátànì yìí.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

37
MÓDÙ KẸRIN: ÀTÚPALE ̣́ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÀLO ̣́ ÌJÀPÁ
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Ìjàpá, Àgbò àti Igbá
5.0 Ìsọniṣókí
6.0 Ìbéèrè
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáàrà
Ní abe ̣́ módù yìí, a sẹ́ atupale ̣́ awo ̣́n asạ́ yan alo ̣́ ijapa me ̣́rin . A s ̣́e akojo ̣́po ̣́ awo ̣́n alo ̣́
wo ̣́nyí fún ake ̣́ko ̣́o ̣́ láti kà fún ìgbà àko ̣́ko ̣́ láti le ṣe àmúlò àwọn ohun tí a ti ń ṣe àgbéye ̣́wò
wọn lábe ̣́ módù kínní dé ìkẹta fún àtúpale ̣́ àwọn àlo ̣́ wo ̣́nyí. Iṣe ̣́ àdáṣe ni èyí je ̣́ fún ake ̣́ko ̣́o ̣́.
Ìpín kínní: Ìtàn Ìjàpá, Àgbò àti Igbá
Ìpín kejì: Ìjàpá lóyún Ìjàngbo ̣́n
Ìpín kẹta: Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn
Ìpín kẹrin: Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ
Títí di ìsinyìí , ìwọ kò tí ì ní àǹfààní àti ka ìtàn kan ní kíkún. Nítorí ohun tí a ti ń
ye ̣́wò láti módù kínní dé ìkẹta ni àwọn èròjà inú àlo ̣́ àti àwọn òṣùwo ̣́n tí a le lò láti ṣe
àtúpale ̣́ àlo ̣́. Àwọn èròjà yìí níìwọ yóò lò láti ṣe àtúpale ̣́ ìtàn yìí.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ìwọ yóò le:
(i) ka itan naa funra re ̣́ ki o si mo ̣́ o ̣́n
(ii) dáhùn àwọn ìbéèrè tó ro ̣́mo ̣́ ìtàn náà fúnra rẹ
(iii) mọ bí a ṣe ń ṣe ìtúpale ̣́ àlo ̣́ nípa lílo àwọn èròjà ìtúpale ̣́ tí a ti gbéye ̣́wò ní módù
kínní sí ìkẹta (modules 1 – 3).

38
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
1. Irú ẹranko wo ni à ń pè ní àgbà?
2. Ohun meji wo ni a n lo igba fun?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan inu ipin yii – Ìtàn Ìjàpá, Àgbò àti Igbá
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ o!
Àwọn Jànmọ: Àlo ̣́!
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ mi dá fììrìgbágbòó, ó dálérí
Ìjàpá, Tìrókò, ọkọ Yánníbo
Ẹse ̣́ dan-ìn-dan-ìn bí àrán o ̣́pẹ
Tí ńlọ láàrin e ̣́pà,
Ó ní ọpe ̣́lọpe ̣́ pé òun ga!
Ní ìgbà kan , ní ìlú Ìjàpá , àgbe ̣́ tó bá gbin igbá , ó ti bo ̣́ sí àmù owó ni ; igbá tà púpo ̣́, ó sì
níyelórí. Ge ̣́ge ̣́ bí àwọn àgbe ̣́ ile ̣́ Yorùbá ti kú lé kòkó lónìí , ni awo ̣́n agbe ̣́ ilu Ijapa naa ka
ìgbá sí ohun ọro ̣́ pàtàkì . Torí náà, àgbe ̣́ tí kò bá gbin igbá kò lè fọwo ̣́ so ̣́yà pé àgbe ̣́ gidi
lòun.
Ìjàpá wo ara re ̣́ títí ní ọjo ̣́ kan , ó ní „Gbogbo àgbe ̣́ , igbá ni wo ̣́n fi ń ṣe ohun ọro ̣́ .
Ọmọdé gbin igbá , àgbà gbìn , wo ̣́n ń rówó ṣe . Èmi náà á lọ gbin igbá .Mo tile ̣́ ti kiyesi bi
wo ̣́n ti ń ṣe é. Ṣé kénìyàn kàn gbin igbá ni , kò mú wàhálà dání; kò sí pé à ń ro oko fun un,
fúnra re ̣́ ni yóò tàn bo oko tí yóò pa á . Èmi náà fe ̣́ di àgbe ̣́ tó lórúkọ – àgbe ̣́ onígbá .‟
Alábahun bá he àdá àti ọko ̣́ re ,̣́ ó lọ síbi oko kan báyìí lo ̣́nà jíjìn sí abúlé re ̣́, ó pa oko, ó tó
yàrá kan ni titobi, ó gbin ìdí igbá kan síbe ,̣́ ó ní èyiùn náà tó bá tàn kále ,̣́ ó tó. Ṣé kí àwọn
ará abúlé sá mo ̣́ pé òun ní igbá lóko ni.
Bó ti gbin igba yii tan , ó gbéra, ó bo ̣́ wálé.Kò padà débe ̣́ títí ọdún fi yipo. Ó ń sùn,
ó ń jí ; ó ń fi àwọn tí ńlọ só ko da apara pe olooraye ni wo ̣́n , títàn ni igbá ń tàn kále ̣́ , èmi
loko-ríro wá ti je ̣́, fúnra re ̣́ kí yóò poko ni! Ó ń wò ní tire ̣́, ó ń sùn, ó ń jí.
Nígbà tí ọdún jọ, onígbá ń ka ‟gba, wo ̣́n ń tà á , wọn ń fowó re ̣́ dá aṣọ sára , wo ̣́n ń
jẹun, wo ̣́n ń gbádùn . Ìjàpá dìde níjo ̣́ kan , ó múra ó di oko . Ó fa agbo ̣́n lo ̣́wo ̣́ ó ń lọ kérè
igbá tire ̣́.Bó ti débe ̣́ ló ní , „Haa, igbá burúkú yìí ! Eyọ kan ṣoṣo ló so . Àwọn ẹgbe ̣́ rẹ ń so

39
ogún, wo ̣́n ń so ọgbo ̣́n , ẹyọ kan ṣoṣo ni ìwọ lè so . Ó mà kúkú yo ̣́lẹ o ! kò burú; o ̣́kan naa
tile ̣́ tóbi dáadáa. N o gbe e be ̣́e,̣́ a mu owo die ̣́ wa ti mo ba ta a.‟
Ǹ je ̣́ kó be ̣́re ̣́ kó gbé igbá, ni igba ba so ̣́ro ̣́ lo wi pe , „Ijapa, o s ̣́e o. mo mo ̣́ pe o ̣́le ̣́ ni
mí, ṣùgbo ̣́n je ̣́je ̣́ mi ni mo jókò ó tó wá gbìn mí sínú igbó yìí o . Lọ wo àwọn àgbe ̣́ ẹgbe ̣́ rẹ ,
ìgbà gbogbo ni wo ̣́n ń roko fún igbá w ọn kí oúnjẹ bá lè tó wọn , ate ̣́gùn àlàáfíà a sì fe ̣́ sí
wọn. Oúnjẹ rere àti ate ̣́gùn tó tutù ló ń mú igbá so dáadáa. Èmi nìyí, àtèṣín tó ti fi mí síbí,
e ̣́e ̣́melòó ló wá be ̣́ mí wò ? Ǹje ̣́ o tile ̣́ bìkítà àti roko fún mi ?o ko naani boya mo je ̣́un boya
n ko je ̣́un. Lónìí, o wa fe ̣́ kore ohun ti o ko sẹ́ wahala fun . Jo ̣́wo ̣́ máa bá tire ̣́ lọ o, fi mi sile ̣́
je ̣́je ̣́ o, tí o kò bá fe ̣́ kàn din nínú iyo ̣́ o.‟
E ̣́rù ba Ìjàpá nígbà tó gbo ̣́ o ̣́ro ̣́ tí igbá yìí sọ , ó sì yà á le ̣́nu pé igbá lè so ̣́ro ̣́ . Ṣùgbo ̣́n
síbe ̣́síbe ̣́ ó pinnu pé níwo ̣́n igba to je ̣́ pe oun loun gbin igba yii, dandan ni koun gbe e lo ̣́ ta.
Bó ti be ̣́re ̣́ pé kóun gbé igbá à fi gbaa , ni igba fo to kan Ijapa nikoo lori ; Ìjàpá fìdí jále ,̣́ ó
ṣubú. Bó ti wo iwájú ló t ún rí igbá ló ń yí gbirigid i bo ̣́ lo ̣́do ̣́ re .̣́ Ìjàpá fi eré sí i , igbásáré
te ̣́lé e, ó di gbirigidi gbirigidi gbirigidi, ó di kìtà kìtà kìtà , ni Ijapa n ke pe awo ̣́n e ̣́ranko to
pàdé lo ̣́nà pé kí wọn gba òun lo ̣́wo ̣́ igbá tó ń lé òun, ló ń kọrin báyìí pé:
Igbá ńl’Áhun,
Teregúngún màjàgúngún tere
Igbá ò loẉ̀ o ̣̀
Teregúngún màjàgúngún tere
Igbá ò le ̣̀se ̣̀
Teregúngún màjàgúngún tere
Igbá ńl’Áhun,
Teregúngún màjàgúngún tere
Igbá ò low ̣̀ o ̣̀
Teregúngún màjàgúngún tere
Igbá ò le ̣̀se ̣̀
Teregúngún màjàgúngún tere

Gbogbo awo ̣́n e ̣́ranko to pade lo ̣́na ni wo ̣́n n fi i sẹ́ e ̣́le ̣́ya ti wo ̣́n ni ki igba mu u n
dáadáa. Nígbà tó yá, tó kù díe ̣́ kí igbá bá a, ni Ijapa ba pade Agbo lo ̣́na . Ó bẹ Àgbò kó ran
òun lo ̣́wo ̣́, kó bá òun kan igbá pa . àgbò ṣàánú fún un , ó be ̣́re ̣́ sí í kan igbá , ó kàn án títí tí
igbá fi fo ̣́ we ̣́we ̣́.

40
Ìjàpá bá be ̣́re ̣́, ó ṣa èfífo ̣́ igbá, ó ní òun á lọ tà á be ̣́e.̣́ Ó mú èfífo ̣́ igbá kékeré kan fún
Àgbò. Àgbò ni òun ò fe ̣́ igbá, iṣe ̣́ gidi lòun ṣe fún Ìjàpá, láìje ̣́ pé òun bá a kan igbá pa, pípa
ni igba ye ̣́n iba pa Ahun . Torí náà, iṣe ̣́ lòun fe ̣́ kó lọ bá òun ṣe lóko òun .Ìjàpá gbà be ̣́e ,̣́ ó
te ̣́lé Àgbò lọ sí oko re ̣́.
Àgbò me ̣́se ̣́ oko kan , Ìjàpá náà mú tire ̣́. Ṣùgbo ̣́n nítorí pé o ̣́lẹ ni, wéré ni Àgbò kọ já
lára re ̣́, tó ń roko lọ níwájú . Ìjàpá ń rò nínú ara re ̣́ pé , tòun bá lè pa Àgbò yìí , àtoko re ̣́, àti
igbá yìí, yóò di tòun , òun yóò sì tún fi ẹran re ̣́ se e ̣́bẹ jẹ. Ó dára, ó ń roko lọ , ó ń wá o ̣́nà
àtipa Àgbò.
Nígbà tí Àgbò ro oko tán , àáre ̣́ ti mú u , ó bá lọ síbi odò tó wà le ̣́bàá oko re ̣́ , ó mu
omi, ó fi e ̣́yìn ti igi kan , láìpe ̣́ ó sùn lọ . Nígbà tí Ìjàpá retí re ̣́ tí kò tètè rí i , ló bá dìde, ó ń
lọ sí ibi odò náà .Nígbà tó débe ,̣́ ó rí i pe Agbo ti n hanrun . Ló bá wò yíká, ó rí igi ẹle ̣́nu
ṣóńṣó kan ló bá mú u, ó rọra yo ̣́ lọ síbi tí Àgbò sùn sí , àfi ṣo ̣́-o ̣́! Ó tẹ igi bọ Àgbò lójú, ó fi
e ̣́rú-ọko ̣́ gbá a wọle ̣́ dáadáa.Àgbò jà jà jà; ibe ̣́ ló kú sí.
Ìjàpá gbé òkú Àgb ò lọ sí abà re ,̣́ ó kun ún, ó sè é, ó ń tasánsán. Bó ti so ̣́ o ̣́ kale ̣́ lórí
iná, ọbe ̣́ náà sì gbóná jù; ló bá forí lé àgbe ̣́de ̣́Ajá tó wà nítòsí abà re ̣́. Bó ti débe ̣́ ló rí Ajá tí
ń rọ àdá, tó ń fi apákan ń fínná tó ń fi apákan lu irin-ọmọ-iṣe ̣́Ajá kò sí nílé. Ni Ijapa ba so ̣́
fún Ajá pé òun fe ̣́ bá a fínná.Ajá gbà, ó sì gbé ẹwìrì lé Ìjàpá lo ̣́wo ̣́. Gbígbà tí Ìjàpá gba
ẹwìrì, ọkàn re ̣́ kò kúrò níbi ìkòkò àgbò re ̣́, orin lo fe ̣́wiri n ko ̣́, ló ń pé:
Ìkòkò àgbò ḿbẹ lájà
Ìkòkò àgbò ḿbẹ lájà
Tó kún bámúbámú
Tó kún bámúbámú
Ìkòkò àgbò tó dùn ḿbẹ lájà
Tí mo bá délé má mú jẹ
Tí mo bá délé má mú jẹ
Ìkòkò àgbò
Ìkòkò àgbò ḿbẹ lájà

Inú re ̣́ ń dùn, ito ̣́ ń súyọ le ̣́nu re,̣́ ó dàbí ẹni pé ó ń gbóòórùn títasánsán e ̣́bẹ tó fàgbò sè; ó ń
fínná me ̣́sàn-án me ̣́wàá, ó n fẹwìrì kọrin.
Àṣe gbogbo bó ti ń ṣe ni Ajá ń kíyèsí . Alágbe ̣́dẹ kúkú ni , gbogbo ohun ti eniyan le
fi e ̣́wiri so ̣́ lo ti ye e. nígbà tí ó gbo ̣́ orin ti Ijapa n fe ̣́wiri ko ,̣́ ó yára mú irin tó fi ń rọ àdá, ó

41
mú u padà sínú iná , ó kó èédú síná , ó ní kí Ìjàpá máa fínná , òun ḿbo ̣́ , òun fe ̣́ yára
ṣègbo ̣́nse ̣́ lóko kan le ̣́bàá àgbe ̣́dẹ náà . Ko ̣́ro ̣́ t‟Aja yi wo ̣́nu igbe ̣́, ahéré Ìjàpá ló sáré lọ.Bó ti
débe ̣́, kòì tí ì wọlé tó ti ń gbo ̣́ òórùn títasánsán ọbe ̣́ Ìjàpá .Ní ìṣe ̣́jú-akàn, Ajá ti gun òkè àjà,
ó gbé ìkòkò àgbò so ̣́kale ̣́ , ó fi gbogbo re ̣́ jẹ pátápátá; kìkì eegun díe ̣́díe ̣́ ló fi síle ̣́
níbe ̣́.Káláǹgbá tó paradà le ̣́gbe ̣́e ̣́ ògiri , Ajá ti padà sí à gbe ̣́dẹ.Ó kí Ìjàpá kú iṣe ̣́ , ooru mbo
Ìjàpá wo ̣́o ̣́; ajá ní, „Ku is ̣́e ̣́ o ̣́re ̣́ mi. Ǹje ̣́ kò ti re ̣́ o ̣́ díe ̣́ be ̣́e ̣́?Je ̣́ kí n ràn o ̣́ lo ̣́wo ,̣́ kó o sinmi, kó
o gbate ̣́gun sara die ̣́.‟
Ajá gba ẹwìrì, ló ń pé:
Ìkòkò àgbò ḿbẹ lájà
Ìkòkò àgbò ḿbẹ lájà
Mo ti je ̣̀ e ̣̀ tan.
Mo ti fi i lanu
Pátápátá po, pátá po, pátápátá po.

Ìjàpá fura pé ǹje ̣́ ìkòkò àgbò n ko ̣́ l‟Ajá sọ pé òun jẹ tán yìí ?Ó yára kí o ̣́re ̣́ re ̣́ pé ó
dìgbóóṣe, òun fe ̣́ yára lọ bẹlé wò.
Nígbà tí Ìjàpá délé , ìkòkò àgbò re ̣́ ló bá níle ̣́ ; egungun àgbò nìkan ló kù , gbogbo
e ̣́gbe ̣́ ìkòkò ni Ajá ti faho ̣́n lá , tí ń dán kooro . Ìjàpá gbójú sókè , omi lo bo ̣́ loju re ̣́.Kí ló lè
ṣe?Kò lè pe Ajá le ̣́jo ̣́ sílé-ẹjo ̣́ àwọn ẹranko nítorí kò ní lè fìdí ẹjo ̣́ re ̣́ múl e ̣́; kò kúkú mú Ajá
níbi tó ń gbé ń jí ìkòkò àgbò jẹ .Nibo loun o ti ni oun ri agbo se . Ẹjo ̣́ apànìyàn ni wọn yóò
tún ṣe fún òun, nítorí òfin wà pé ẹranko kan kò gbọdo ̣́ pa ẹranko ẹle ̣́gbe ̣́ re ̣́ jẹ àfi Kìnnìún,
Ẹkùn àti Ìkookò ni wo ̣́n fún láṣẹ . Tóun bá pẹjo ̣́, òun yóò tún jẹ ìyà kún ìyà ni , nítorí bí
ọwo ̣́ ènìyàn kò bá tí ì tẹ èèkù idà, kì í bèèrè ikú tó pa ìyá òun. Sùúrù lòun ó mú.
Báyìí ni Ìjàpá pa Agbo to gba a sile ̣́ lo ̣́wo ̣́ Igba ti iba pa a .Ṣùgbo ̣́n, Ọlo ̣́run rán Ajá
láti gbe ̣́san ibi tó ṣe sí Àgbò . Ìtàn yìí ko ̣́ wa pé a kò gbọdo ̣́ fi ibi san oore o . Dípò be ̣́e ̣́, ire
ló yẹ ká fi san ibi o.
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Bí n bá puro,̣̀ kágogo ẹnu mi má ròó,
Bí n ò bá purọ, kágogo ẹnu mi ró le ̣̀e ̣̀mẹta –
Ó di …pó….pó….pó!
Orísun ìtàn: Babalọla (1973)

42
5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìtàn yìí , a ri i bi Ijapa ti fi ibi san oore fun Agbo ti o gba a sile ̣́ lo ̣́wo ̣́ Igba .
Igbá fe ̣́ pa Ìjàpá le ̣́yìn ìgbà tí ó fi ṣe ẹle ̣́yà ṣùgbo ̣́n Àgbò ràn án lo ̣́wo ̣́ láti kan Igbá pa . Ìjàpá
pa Agbo ; ó fi ibi san ire. Le ̣́yìn ìgbà tí ó pa Àgbò tí ó sì fi ẹran re ̣́ se e ̣́bẹ aládùn , Ajá ni ó
kérè gbogbo oúnjẹ tí Ìjàpá sè.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ro ̣́mo ̣́ ìtàn yìí :
1. Kí ni ìdí tí Ìjàpá fi dá oko igba?
2. Kí ni ìdí tí Igbá fi bá Ìjàpá jà?
3a. Ta ni o gba Ijapa sile ̣́ lo ̣́wo ̣́ Igba ?
b. Oṇ́ à wo ni ó fi gba Ìjàpá síle ̣́?
4. Dárúkọ àwọn e ̣́dá-ìtàn inú ìtàn yìí
5. Irú e ̣́dá-ìtàn wo ni a lè pe Ìjàpá? Fi apẹẹrẹ gbe ìdáhùn rẹ le ̣́se ̣́.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Babalọlá, A. (1973) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kínní. Ibadan: University Press Ltd.

43
Ìpín kejì: Ìtàn Ìjàpá Lóyún Ìjàǹgbo ̣́n
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Ìjàpá Lóyún Ìjàǹgbo ̣́n
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Wo ifaara abe ̣́ ipin kinni

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Èyí kò yàto ̣́ sí ti abe ̣́ ìpín kínní

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Kí ni orúkọ ìyàwó ìjàpá nínú àlo ̣́?
2. Irú e ̣́dá-ìtàn wo ni ìjàpá?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan inu ipin yii – Ìtàn Ìjàpá Lóyún Ìjàngbo ̣́n
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ o!
Àwọn Jànmọ: Àlo ̣́!
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ mi dá gbà -á, ó dá gbò -ó, ó dá fììrìgbágbòó , ó dálérí Alábahun
Ìjàpá

Nígbà tí Ìjàpá di o ̣́mo ̣́ o ̣́dun me ̣́e ̣́e ̣́dogun , ó fe ̣́ ìyàwó kan; Yánníbo loruko ̣́ iyawo re ̣́.
Yánníbo je ̣́ arẹwà obìnrin ; ó pupa ròbòtò , eyín ẹnu re ̣́ funfun nigín -nigín. Bí àṣe ̣́ṣe ̣́yọ

44
o ̣́go ̣́mo ̣́, ó gùn, ó síngbọnle ̣́, ó rí so ̣́so ̣́ro ̣́ díe ̣́. Bó wọ aṣọ, á yẹ e ̣́, bó bọ bàtà, à bá a mu, bó ń
rìn lọ , ó mú irin wu ni . Bí ọmọbìnrin yìí ti le ̣́wà tó , be ̣́e ̣́ ló níwà : ó lè gé ara re ̣́ fi tọrẹ ,
o ̣́po ̣́lọpo ̣́ àánú ní ḿbẹ níhò ojú re ̣́ , ó lo ̣́yàyà, ó sì nífe ̣́e ̣́ sí tọmọdétàgbà . Ṣùgbo ̣́n inú re ̣́ kò
dùn tó be ̣́e ̣́ nítorí pé kò bímọ. Bí kò sí ti bímọ yìí náà , kò bínú ẹrú kò bínú ọmọ ; bí ẹnìkan
bá bímọ ní ilé wọn tàbí ní àdúgbò , Yánníbo ló ḿbá wọn to ̣́jú re ̣́ ; á we ̣́ fún ọmọ ọlo ̣́mọ , a
kun ati kè fún un , á po ̣́n o ̣́n ; bó ṣu òun ni yóò kó o , bó to ̣́ òun ni yoo nu u , ó sá ń to ̣́ jú
gbogbo o ̣́mo ̣́ we ̣́e ̣́re ̣́ to ba ri , á máa yan sàká , á máa se oúnjẹ fún wọn , bóyá nípa be ̣́e ̣́ òun
náà á dọlo ̣́mọ. Òtúbáńte ̣́.
Nígbà tó di ogún ọdún tí Yánníbo ti délé ọkọ tí kò lóyún ọjọ kan súle ̣́ , ó pe ọkọ re ̣́,
ó ní „Baálé mi , ọkọ àyà mi , olówó orí mi , o ̣́ro ̣́ e ̣́dùn ọkàn mi gan -an ni mo fe ̣́ ba yin so ̣́ .
Láti ogún ọdún tí a ti ḿbá á bo ̣́ yìí, ẹ kò ṣe ̣́ mí, ẹ kò hùwà kan tí kò te ̣́ mi lo ṛ́ ùn sí mi. Èmi
náà sì ń ṣagbára mi láti máa mú inú yín dùn . Ṣùgbo ̣́n nǹkan tí ń kọ mi lóminú , tó sì ń bà
mí nínú je ̣́ ni àìro ̣́mọbí . Ère kí ni obìnr in le je ̣́ nile o ̣́ko ̣́ laibimo ̣́ ? Ẹwà obìnrin ni ọmọ je ̣́ ,
òun sì ló ń koná ìfe ̣́ láàrin ọkọ àti aya . Nítorí náà , ẹ bá mi wá aájò ṣe ; kìí ṣe pé ẹ ti
káwo ̣́bọtan láti ọjo ̣́ yìí wá, rárá, n ko so ̣́ iye ̣́n; ṣùgbo ̣́n awo ̣́n agba lo n pa a lowe pe , “Bi ina
kò bá tán lórí, e ̣́je ̣́ kì í tán ní èékánná‟ kí òwe náà je ̣́ tiyín ; bí a kòì rí ọmọ bí a kò gbọdo ̣́ je ̣́
kí agara dá wa o.
„Mo dupe ̣́ pupo ̣́ lo ̣́wo ̣́ re ,̣́ ìyàwó mi o ̣́ke ̣́mú; o o ni pasan nile mi . Oǵ̣ e ̣́de ̣́ kì í yàgàn ,
Olódùmarè kò ní í ṣe o ̣́ lágàn , ọmọ alálùbáríkà ni Ọlo ̣́run yóò fi dá wa lo ̣́lá. Èmi náà kò je ̣́
re ̣́we ̣́sì, lo ̣́sàn-án lórú ni mò ń ro o ̣́nà tí a ó gbà tí a ó fi do ̣́lo ̣́mo ̣́. Ṣé ìwọ náà rí i pé n kò fe ̣́
obìnrin mìíràn, n ko si bimo ̣́ si ipamo ̣́ . Bí ó ti rí lára rẹ , be ̣́e ̣́ lókàn mí gbo ̣́ngbo ̣́n . Mo mo ̣́
pé a ó bímọ , ọmọ tí yóò gbe ̣́yìn te ̣́yìnṣe ni Ọlo ̣́run yóò sì pèsè fún wa, ape-kó-tó-jẹun
̣́ kò
ní í jẹ ìbàje ̣́. Tújúká, ìyàwó mi, Ọlo ̣́run ni n s ̣́o ̣́mo .̣́ N o lo ̣́ ba o ̣́re ̣́ mi kan to je ̣́ babalawo to
gbójú, ale ̣́ yìí gan-an ni n o lo ̣́ ibe.‟̣́
Àkàlà ni babal áwo náà tí Ìjàpá fe ̣́ lọ bá; o ̣́re ̣́ ni òun àti Ìjàpá ṣùgbo ̣́n , láti ìgbà tí
Ìjàpá ti ń wá ọmọ , kò fi lọ o ̣́re ̣́ re ̣́ yìí , àwọn babaláwo ìlú òkèèrè ló lọ ń bá tó ń náwó tó ń
nára. Be ̣́e ̣́ ni ògbólògbó adáhunṣe àti olóògùn ni Àkàl à ń ṣe , ẹbọ ló rú títí tí orí re ̣́ fi pá .
Ohun ti a ni ki i jo ̣́ ni loju, ni ko je ̣́ ki Ijapa ti fi e ̣́dun o ̣́kan re ̣́ lo ̣́ Akala . Nísinsìnyìí, ó dìde,
ó lọ so ̣́do ̣́ Àkàlà, ó sọ fún un wí pé, „Oṛ́ e ̣́ mi Akala , inú mi dùn bí mo ti bá ọ yìí, tó o jókòó

45
láàrin àwọn ọmọ àti ìyàwó rẹ , tó ń jẹ tó ń mu ; tó ro ̣́mọ pè rán níṣe ̣́ , to ro ̣́mo ̣́ ba so ̣́ro ̣́ , tí
àwọn aládùúgbò ń fi orúkọ ọmọ pè o ̣́ . Ìbá je ̣́ rí be ̣́e ̣́ fémi náà, ayo ̣́ mi ìbá túbo ̣́ kún. A sa jo ̣́
gbéyàwó ní sáà kan náà ni . Ọlo ̣́run kò sì fún wa lo ̣́mọ , jo ̣́wo ̣́ mo be ̣́ o ̣́ , a ki i mo ̣́ eniyan
me ̣́fà kójú ẹgbàafà po ̣́n ni , babaláwo ni o ̣́ , bá mi késí Oṣ́ anyìn rẹ kó ṣòògùn oyún fún
ìyàwó mi.‟
„O seun,
̣́ o ̣́re ̣́ mi Ìjàpá. N ko s ̣́ai n ro o ̣́ro ̣́ tire ̣́ yii . Níjo ̣́ wo ná ni èmi àti ìyàwó mi ń
so ̣́ro ̣́ rẹ níbi yìí, tí à ń gbàdúrà kOḷ́ o ̣́run ṣí ìyàwó rẹ nínú . Èrò-ọkàn tèmi ni pé ìgbà tí ẹ kò
sọ fún wa, mo ti gba pe e ̣́ ti ri awo ̣́n to n saa
̣́ jo fun yin ni . Ìpè tí a sì gbo ̣́ là á je ̣́. Nísisìyìí tí
ó wá sọ fún mi yìí, n o sa ipa mi, ìyàwó rẹ yóò sì lóyún. Ṣùgbo ̣́n kin ní kan ni o, nítorí o ̣́ro ̣́
rẹ ṣòro, òògùn tèmi ní èèwo ̣́ o : o o gbo ̣́do ̣́ to ̣́ o ̣́ wo , tí o bá to ̣́ ọ wò , o o loyun o, kí lo máa
ṣe bí ọmọ náà? Kò sí, àfi ikú o. Torí náà, mo kilo ̣́ fun o ̣́ gidigidi o, kò sí e ̣́ro ̣́ re ̣́ o.‟
„Haa!kí ló máa sun mi si ye ̣́n? Ohun ti mo ti n wahala fun lati ogun o ̣́dun se ̣́yin ki n
tún wá fọwo ̣́ ara mi ṣe ara mi ! Ńdào, n kii s ̣́o ̣́mo ̣́de , àgbà ni mo dà yìí , torí náà ohun tó bá
ní ṣiṣe ni kó o sọ fún mi; pé n máa fọwo ̣́ kàn an ye ̣́n, ká mú u kúrò, n ko je ̣́ je ̣́ os ̣́e ̣́.‟
„Inu midun lati gbo ̣́ ileri ti o sẹ́ . Ohun irubo ̣́ to maa wa , ta o fi s ̣́etutu ni malau
méje, ewúre ̣́ méje, àgbò méje, òbúkọ méje, ẹyẹlé méje, adìẹ me ̣́rìnlá: àkùkọ méje, àgbébo ̣́
méje. Ìgò epo méje , egbìnrín iyo ̣́ méje , ata meje, àpò àlùbo ̣́sà méje. Le ̣́yìn ìyẹn, o o wa a
lọ ra odindi ẹja àro ̣́ tí wo ̣́n ká , tí wo ̣́n ti yangbẹ , tó je ̣́ o ̣́wo ̣́jú, èyí la ó fi se àṣèjẹ fún aya re ̣́
le ̣́yìn tí a bá ti rúbọ tí a sì ti tu Es ̣́u loju . Tí o bá lè ṣe gbogbo ohun tí mo kà síle ̣́ yìí , ìyàwó
rẹ kò ní mú oṣù náà jẹ, oyún ni yóò fi ní o.‟
Ìjàpá dúpe ̣́ lo ̣́wo ̣́ Àkàlà , ó gbéra, ó relé re ̣́.ó kó, ó rò fún ìyàwó re ̣́; nígbà tó sì dọjo ̣́
kejì, wo ̣́n wá gbogbo ohun tí Àkàlà kà síle ̣́ , ó pé pérépéré . Ìjàpá kó o lọ fún Àkàlà ,
babaláwo náà sì sọ fún un pé tó bá di òwúro ̣́ ọjo ̣́ kejì, kó wá gba àsèjẹ ìyàwó re ̣́ o.
Àkàlà rúbọ, ó tú èrù atùkèṣù , ó se àsèjẹ fún Yánníbo , ọbe ̣́ náà ń ta sánsán , ẹja àro ̣́
yẹn tóbi, ó fo ̣́ ke ̣́re ̣́ke ̣́rẹ sínú ọbe ̣́ náà , ó ń po ̣́n to ̣́o ,̣́ epo n sạ́ n geere loju o ̣́be ̣́ naa , irú, ògìrì
àti àlùbo ̣́sà kò je ̣́ kénìyàn lè mójúkúrò lára àsèjẹ náà, ó wọ ni lójú gidigidi.
Ìjàpá dé, ge ̣́ge ̣́ bí Àkàlà ti sọ fún un . Babaláwo gbé ọbe ̣́ lé e lo ̣́wo ̣́, ó sì tún kì í nílo ̣́
pé kò gbọdo ̣́ to ̣́ ọ wò o, Yánníbo ló ni í o. Ó gba aàsèjẹ, ó dúpe ̣́ lo ̣́wo ̣́ Àkàlà, ó lọ.

46
Bí ó ti ńlọ lo ̣́nà , ọbe ̣́ yìí ń ta sánsán sí i nímú , ó ń fi imú fa òórùn re ̣́ , ó ń dá o ̣́fun
mì, ito ̣́ ń yo ̣́ sí i le ̣́nu, ó ń rò ó nínú ara re ̣́ pé Yánníbo nìkan ni yóò jẹ ọbe ̣́ tí ń ta sánsán yìí.
ṣebí obìnrin kò lè dánìkan bímọ , tóun bá to ̣́ díe ̣́ wò níbe ̣́ , nǹkan náà á fi tètè bo ̣́sí i ni . Ó
dúró, ó sị́́ ọbe ̣́ náà wò , ó rí ẹja àro ̣́ yẹn tó ti tú púyẹpúyẹ sínú ọbe ,̣́ ó wo ̣́ o ̣́ lójú; ó gbé ọbe ̣́
síle,̣́ ó na ọwo ̣́ kóun mú iṣu ẹja kan jẹ , ó tún sáwo ̣́ kì, ọkàn re ̣́ kàn sọ fún un pé wo ̣́n mà ti
kìlo ̣́ fún òun te ̣́le ̣́ kóun má to ̣́ o ̣́ wò; ó dé e padà, ó gbé e, ó ńlo .̣́ Bó ti tun rin die ̣́ , ó tún
dúró, ó ṣí ọbe ̣́; tóun bá mú iṣu ẹja kan lásán , ìyẹn ò ba òògùn je ̣́ ke ,̣́ òun ò sì tí ì lè fi ìyẹn
lóyún; báwo lọkùnrin tile ̣́ máa ṣe lóyún , òun ò gbo ̣́ ọ rí . Ìjàpá mú irú ẹja pùke ̣́pùke ̣́ kan , ó
sọ o ̣́ se ̣́nu ṣo ̣́dú, ó gbé ìṣaàsùn re ̣́ ó ń lọ , ó ń jẹ ẹja yẹn ní àjẹrìn . Nígbà tí ó jẹ e ̣́ tán, ó dùn
mo ̣́ ọn le ̣́nu, ó ní àṣé ohun tó dùn báyìí ni Àkàlà ní kí Yánníb o nikan je ̣́, bóyá ó tile ̣́ fe ̣́ gba
ìyàwó òun náà ló ṣe ṣebe ̣́ tó dùn báyìí lọ fún un . Òun á jẹ eléyìí , ẹni tó ní kóun má jẹ e ̣́ ,
kólúwa re ̣́ kú, kó rùn, kó dojúbole ̣́ gbìrìgidi bí ìgbín . Òun lòun ni owó tóun fi ra nnkan ti
wo ̣́n fi sè é, o ̣́re ̣́ òun ló sì sè é, tòun bá jẹ èyí, òun á tún lọ bá a kó se òmíràn pé ewé kòì je.̣́
Ìjàpá gbé ọbe ̣́ kale ̣́ nídìí igi kan , ó fọwo ̣́ sí i , ó jẹ gbogbo re ̣́ pátápátá , ó fo ̣́ ìsáàsùn
mo ̣́le ̣́ níbe ̣́. Ó dìde, ó ń lọlé pé òun á lọ sọ fún Yánníbo pé Àkàlà kòì se àsèjẹ re ̣́ o . Bó ti ń
lọ lonà,
̣́ ni inu be ̣́re ̣́ si i mu u , inú re ̣́ be ̣́re ̣́ sí í ga , ó ń fe ̣́, ó ń tóbi, ó ń ga á le ̣́mìí , kò lè mí
dáadáa mo ̣́, ó ń kérora. Nígbà tí inú yìí fe ̣́ be ̣́, ló bá ṣe ̣́rí padà, ó ní òun á lọ bẹ Àkàlà kó bá
òun rọ kinní yìí, kó ṣe ètùtù fún òun, òun á puro ̣́ pé gbòǹgbò ló yọ òun ṣubú tí ọbe ̣́ dànù, tí
díe ̣́ sì kán sí òun le ̣́nu ; ló bá padà , ló ń sáré lọ sílé Àkàlà , ikùn ti di gbandu , kò je ̣́ kó lè
sáré mo ̣́, ó túbo ̣́ ń tóbi sí i ní ìṣììṣe ̣́jú ni . Nigbà tó rílé Àkàlà lo ̣́o ̣́o ̣́kán ló forin se ̣́nu , tó ń kọ
o ̣́ tàánú tàánú pé:
Bàbaláwo, mò wá be ̣̀be ̣̀,
Alugbinrin.
Bàbaláwo, mò wá be ̣̀be ̣̀,
Alugbinrin.
Òògùn tó ṣe fún mi le ̣̀re ̣̀kàn.
Alugbinrin.
Tó ní n má mà mow ̣̀ o ̣̀ kan’nu,
Alugbinrin.
Tó ní n má mà me ̣̀se ̣̀ kan ’nu,
Alugbinrin.
Gbòǹgbò ló yo ̣̀ mí te ̣̀re ̣̀,

47
Alugbinrin.
Mo fọ̀wo ̣̀ ba ’be ̣̀, mo mu ba’nu,
Alugbinrin.
Mo bo’ju wo’kun, ó yó kẹndu,
Alugbinrin.
Bàbaláwo, mò wá be ̣̀be ̣̀,
Alugbinrin.
Bàbaláwo, mò wá be ̣̀be ̣̀,
Alugbinrin.

Nígbà tí Àkàlà rí i, ó yanu kò le pa á dé, ó ní, „Ijapa, o s ̣́e yii tan!Mo so ̣́ fun o ̣́ tabi n
kò sọ fún ọ? Kò sí e ̣́ro ̣́ re!̣́ Ikú ni. Èrè àìgbọràn àti ojúkòkòrò ló jẹ yìí o.‟
Ìjàpá be ̣́re ̣́ sí í be ̣́be ̣́ , ó ń wí àwáwí , ó ń sunkún , ó ń kégbe , Àkàlà ní kí ó lọ sójú
Oṣ́ anyìn, kí ó lọ be ̣́ e ̣́ nítorí Oṣ́ anyìn ni òrìṣà ìṣègùn, bóyá ó lè rí ìwòsàn ṣùgbo ̣́n òun ò mọ
e ̣́ro ̣́ re ̣́. Bó je ̣́ obìnrin ló jẹ àsèjẹ yẹn , ọmọ ni yóò fi bí , ṣùgbo ̣́n òun ò rí ọkùnrin tó bímọ rí
o.
Ìjàpá fi ìdí wo ̣́ dé ojú Oṣ́ an yìn, ó do ̣́bále ̣́, ó ḿbe ̣́be ̣́. Oṣ́ anyìn ni ó ti jẹ èèwo ̣́, e ̣́mí re ̣́
ni yoo fi s ̣́e etutu . Ìgbàtí inú Ìjàpá tóbi títítí , ló bá be ̣́ pò ó ! Bí Ìjàpá ti kú ikú oró nítorí
ojúkòkòrò àti àwíìgbo ̣́ àko ̣́ -ìgbà nìyí o. Ojú òrìṣà Oṣ́ anyìn ló kú sí o . Òun ni wo ̣́n ṣe ń fi
Ìjàpá bọ Oṣ́ anyìn o. Oṣ́ anyìn bá gbé Ìjàpá, ó jẹ e ̣́ o.
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Bí n bá puro,̣̀ kágogo e ̣̀nu mi ma roo,
Bí n ò bá purọ, kágogo ẹnu mi ró le ̣̀e ̣̀mẹta –
Ó di …pó….pó….pó!Orísun ìtàn: Babalọla (1973)

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìtàn yìí, a ri i bi ojukokoro s ̣́e pa Ijapa . Ìjàpá kú ikú oró sí ojú òrìṣà Oṣ́ anyìn
le ̣́yìn ìgbà tí ó jẹ àsè èyí tí babaláwo ti kìlo ̣́ fún un pé kò gbọdo ̣́ jẹ níbe ̣́ nítorí Yánníbo ni a
se ase naa fun. Inú Ìjàpá wú títí tó fi be ̣́ tí ó sì kú.

48
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
1. Kí ni ìdí tí Ìjàpá fi tọ babaláwo lọ?
2. Kí ni àwọn ohun ti babaláwo ní kó mú wá fún ìrúbọ?
3. Àwọn èròjà wo ló wà nínú àlo ̣́ yìí. Wo modu kinni, ìpín kẹta fún ìto ̣́niso ̣́nà.
4. Ṣe àpèjúwe ìwà Ìjàpá
5. Àwọn kókó -o ̣́ro ̣́ wo ni o rí fàyọ nínú ìtàn yìí ? (Wo modu keji , ìpín kínní fún
ìto ̣́so ̣́nà)

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Babalọlá, A. (1973) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kínní. Ibadan: University Press Ltd.

49
Ìpín kẹta: Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka Ìtàn Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Ìbéèrè
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Wo ìfáárà abe ̣́ ìpín kínní

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Èyí kò yàto ̣́ sí ti ìpín kínní

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Orúkọ mìíràn wo ni Yorùbá ń pe ikàn?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan inu ipin yii – Ìtàn Ìjàpá àti Bàbá Oníkàn
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ o!
Àwọn Jànmọ: Àlo ̣́!
Apàlo ̣́: Àlo ̣́ mi dá fììrìgbágbòó , ó dálérí Ìjàpá Ọkọ Yánníbo àti Bàbá Oníkàn
kan.

Ní ìgbà kan , bàbá kan wà ní ìlú kan, ó gbin ikàn sí oko re ̣́ . Oko tí à ń wí yìí tóbi púpo ̣́ ,
jìnwìnnì ni ikàn re ̣́ máa ń so ; kò se ̣́ni tó máa rí oko ọkùnrin àgbe ̣́ yìí kí ikàn má wu
olúware ̣́ jẹ. Bí Ìjàpá bá ń lọ sí ọjà ní ìlú kejì, e ̣́bá oko ikàn yìí ló ń gbà kọjá; ito ̣́ á máa sú sí

50
i le ̣́nu bi o ba ti ri igba to so do ̣́nkudo ̣́nku yii , o ̣́fun a sì máa dá a ; ṣùgbo ̣́n kò ní owó tí yóò
fi ra a je ̣́.
Nígbà tó dijo ̣́ kan , ebi n pa a , kòì tí ì jẹun látààáro ̣́; ṣé àhejẹ ni Alábahun n s ̣́e te ̣́le ,̣́
ilé àwọn o ̣́re ̣́ re ̣́ ló ti ń jẹun le ̣́e ̣́mẹta lójúmo ̣́ , ṣùgbo ̣́n ní ọjo ̣́ tí à ń wí yìí , púpo ̣́ nínú àwọn
o ̣́re ̣́ re ̣́ kò sí nílé, àwọn tó sì wà nílé kò ní oúnjẹ ; ọjo ̣́ ọjà ni, gbogbo awo ̣́n i yàwó wọn ṣe ̣́ṣe ̣́
lọ ra nǹkan ọbe ̣́ ní ọjà ni.
Ebi wa n pa Ijapa , kò fojú dá ibi tó ti lè jẹun ; nígbà tí ódé oko bàbá oníkàn yìí , ó
wo ̣́ o ̣́ lójú, ó wò yíká, kò re ̣́nìkankan, ó yà bàrá sí oko, ó be ̣́re ̣́ sí í ká ikàn jẹ; ó jẹ ó yó, ó lọ
sílé re ̣́, ó délé, ó momi, ojú re ̣́ wále ̣́, ọkàn re ̣́ bale ̣́, ayo de. Láti ìgbàyí ni Ìjàpá ti lọ ń jí ìgbá
bàbá yìí ká, kò tile ̣́ délé o ̣́re ̣́ kankan mo ̣́ , ó kúkú sọ ìgbá di tire ̣́, ó ń mù, ó ń yo ̣́ nínú oúnjẹ
o ̣́fe.̣́
Bàbá oníkàn kíyèsí pé ọwo ̣́ òun ń yípadà nínú oko ; igi ikan to ba so jinwinni ti
bàbá yìí bá fojú sọ pé òun yóò ká ní ọjo ̣́ kejì , kó tó dé lo ̣́jo ̣́ kejì náà , ile ̣́ á ti gbẹ; Ìjàpá á ti
fi i je ̣́. Nígbà tó yá, bàbá yìí bá be ̣́re ̣́ sí í ṣépè fún ẹni tó wá ń jí òun ní ikàn ká:
“Ẹ́ni to wa ji ikan yii ka , ògún ni yóò pa olúware ̣́ , ile ̣́ ni yóò mú u ; ọwo ̣́ re ̣́ kò ní
te ̣́nu, kò ní te ̣́gbe ̣́ kò ní bá ogbà
̣́ mu…‟
Ní ọjo ̣́ kan , Ìjàpá ṣì wà nínú oko nígbà tí bàbá oníkàn dé , tí ó be ̣́re ̣́ sí í ṣe ̣́ èpè fún
olè tí ń jí i níkàn . Ìjàpá ò lè ro ̣́nà jáde kólóko má rí i ; ọgbo ̣́n wo l òun ó ta tóun yóò fi
de ̣́rùba àgbe ̣́ yìí o? Èrò kan sọ sí i nínú, ló bá déédéé forin se ̣́nu, ó pé:
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Ìwọ ká, èmi ká,
Kínìnrínjingbin
Tèmi ṣe lè dèpè?
Kínìnrínjingbin
Èpè kan ò p’Ahun,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin

51
Nígbà tí ọkùnrin yìí gbo ̣́ ohùn Ìjàpá lójijì be ̣́e ̣́ , àyà re ̣́ pami, ó ṣíyán kò dúró gbọbe ̣́,
ó ń du bo ̣́ nílé lẹlẹlẹlẹ .Nígbà tó délé, ó kó, ó rò fún àwọn o ̣́re ̣́ re ;̣́ gbogbo wo ̣́n mura , wo ̣́n
tún bá a padà sí oko.
Ìjàpá rèé, aláṣejù ni; nígbà tó rí i pé ọgbo ̣́n tóun ta ṣiṣe ̣́, ó kúkú pẹbu sóko olóko bíi
ọká, kò gbèrò àtitètè kú rò níbe ̣́. Nígbà tí oníkàn yì í àti àwọn o ̣́re ̣́ re ̣́ débe ̣́ , wo ̣́n ní kí àgbe ̣́
náà ṣe ̣́ èpè bó ti ṣe láko ̣́o ̣́ko ̣́ ; bí ó ti be ̣́re ̣́ èpè ṣíṣe ̣́, ni Ijapa tun for in se ̣́nu, tó yí ohùn padà
gbá-a, tí gbohùn-gbohùn gba ohùn re ̣́, tí gbogbo igbó gbojikan, ó ń pé:
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Ìwọ ká, èmi ká,
Kínìnrínjingbin
Tèmi ṣe lè dèpè?
Kínìnrínjingbin
Èpè kan ò p’Ahun,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Àtàgbe ̣́ àtàwọn o ̣́re ̣́ re ̣́, o ̣́nà o ̣́to ̣́o ̣́to ̣́ ni wo ̣́n gbà délé. Òmíràn ṣubú nígbà tó ń sáré lọ,
aṣọ òmíràn ko ̣́gi , ó fàya , òmíràn forí sẹgi , òmíràn fẹse ̣́ dá .Wàràwéré, o ̣́ro ̣́ yìí ti tàn do ̣́do ̣́
ọba. Ọba ránṣe ̣́ pe àgbe ̣́ yìí àti àwọn o ̣́re ̣́ re,̣́ ó wá dìí òkodoro le ̣́nu wọn:
„Kabiyesi, mo ni ko ̣́k àn mi túbo ̣́ léle ̣́ kí n máa bo ̣́ lo ̣́do ̣́ yín ni mo rí oníṣe ̣́ yín . Ó ti
pe ̣́ tí mo ti ń kíyèsí pé olè kan máa ń wá jí mi ní ikàn ká, mo s ̣́o ̣́ o ̣́ titi n o ri i mu. Ní òwúro ̣́
yìí bí mo ti ji de oko, ni mo tun ri o ̣́wo ̣́ tuntun lára ìgbá mi, mo ba mu epe s ̣́e ̣́. Àfi bí nǹkan
náà ti déédéé dá mi lóhùn nínú oko; n ko mo ̣́ nnkan naa , n ko si gbo ̣́ iru ohun be ̣́e ̣́ ri.
„Mo sare wale, mo so ̣́ fun awo ̣́n o ̣́re ̣́ mi; gbogbo wa tun ko ra wa rẹirẹi, ó doko. Mo
tún ṣe ̣́pè bíi tàko ̣́ko ,̣́ ohun naa tun da mi lohun ; ó gba gbogbo igbó kan , àfi bíi ohùn àwọn
ogun-o ̣́run, nítorí kò jọ ohùn aráyé kankan. Kábíyèsí, ẹnìkan nínú wa kò mo ̣́ o ̣́nà tí ẹnìkejì
gba padà sílé, o ̣́rán di bí-o-ò-lọ-yà-fún-mi, eré àsádijú lolúkúlùkù sá délé . Èyí tá a rí rè é
o, ko ̣́ba ó pe ̣́…‟

52
Ọba ronú títí, o ̣́ro ̣́ náà dòòyà, ó yà á le ̣́nu; òun níláti tètè ròkan ṣe , nítorí èèmo ̣́ ló ń
bo ̣́ nílùú yìí .„Ẹ́ ba mi kesi awo ̣́n babalawo ati awo ̣́n adahunsẹ́ to wa niluu , kí wo ̣́n wá lọ
be ̣́dí o ̣́ràn yìí wò.‟ Alagogo o ̣́ba kede, ó lu agogo káàkiri ìlú . Ní òwúro ̣́ ọjo ̣́ kejì, àwọn awo
ìlú péjọ; bàbá oníkàn mú wọn lọ síbi oko re ,̣́ ó ṣépè bó ti máa ń ṣe , alábahun tún kọrin bó
ti n ko ̣́ o ̣́ , ògbùrùgburu, àwọn awo sá bo ̣́ sílé wọn ; òmíràn fara gbọgbe ,̣́ àpò ifá ẹlòmíràn
fàya, ẹlòmíràn e ̣́we ̣́ fi ẹse ̣́ ro ̣́ nígbà tó ṣubú sínú kòtò , ó ń rìn ye ̣́ńkúye ̣́nkú bíi amúkùn -ún
kiri.
Nígbà tí ọba rí i pé ọwo ̣́ àwọn babaláwo kò ká o ̣́ràn tó wà níle ̣́ yìí , ó késí Oṣ́ anyìn
ẹle ̣́se ̣́kan. Oṣ́ anyìn ẹle ̣́se ̣́kan rèé , òun ni Babaìṣìgùn, òun ni òrìṣà tí ń tú àṣírí gbogbo ohun
tó pamo ̣́ sí ìko ̣́ko ̣́ . Ọba àti àwọn ìgbìmo ̣́ re ̣́ rí i pé Oṣ́ anyìn nìkan ló lè kojú èèmo ̣́ tó wà
lóko oníkàn yìí; wo ̣́n ránṣe ̣́ sí i pé kó wá bá wọn mú ìgárá náà tí ń jí ìgbá onígbàá jẹ tó tún
ń de ̣́rùbà olóko. Oṣ́ anyìn dé, ó yanbọ, àwọn ìlú san án . Ó múra, ó gbé ẹwìrì re ̣́ àti òòlù re ̣́
dání, ó te ̣́lé bàbá oníkàn ; àwọn oníṣègùn , àwọn ọdẹ àti àwọn ará ìlú mìíràn tó fe ̣́ ṣe
o ̣́fíntótó, àwọn má-mójú-mi-débe ̣́ gbogbo ló te ̣́lé wọn.
Nígbà tí wo ̣́n dé oko , Oṣ́ anyìn dáná àgbe ̣́dẹ , ó fi òòlù sí i , ó fínná mo ̣́ ọ , òòlù
gbóná, ó re ̣́ dòdò; Oṣ́ anyìn sọ fún bàbá oníkàn kó sọ bó ti ń sọ , òun náà be ̣́re ̣́ èpè, ó ń ṣe ̣́ ẹ
léjìléjìdà. Alábahun tún dáhùn nínú oko pé:
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Ìwọ ká, èmi ká,
Kínìnrínjingbin
Tèmi ṣe lè dèpè?
Kínìnrínjingbin
Èpè kan ò p’Ahun,
Kínìnrínjingbin
Oníkàn yìí jingbin,
Kínìnrínjingbin
Gbogbo awo ̣́n to te ̣́le Oṣ́ anyin wa ti salo ̣́, àṣubúlébú-n-te ̣́be agbádá àwọn babaláwo
ń fe ̣́ riyẹriyẹ te ̣́lé wọn le ̣́yìn, gèlè àwọn obìnrin tú, ọrùn nìkan ló dá a dúró, etí re ̣́ méjéèjì ń
fe ̣́ le ̣́le ̣́ te ̣́lé wọn le ̣́ yìn bí àsìá ìdí ọko ̣́ ti ń rèlùú òyìnbó ; sálúbàtà ẹlòmíràn ti fò sọn ù, ẹse ̣́

53
kan s ̣́os ̣́o lo ba a dele . Ṣùgbo ̣́n Oṣ́ anyìn kò yíse ̣́, ó faraṣoko, ó ń so ̣́ ìgbà tí olè náà yóò be ̣́re ̣́
sí í ká ìgbá yìí.
Nígbà tí Ìjàpá rí pé ohun gbogbo ti pa lo ̣́lo ,̣́ ó ṣebí gbogbo wọn ti sálọ , ó jáde, ó
be ̣́re ̣́ mú ìgbá ká .Oṣ́ anyìn rọra n yo ̣́ gulo ̣́gulo ̣́ te ̣́le e le ̣́yin toun ti oolu to ti be ̣́ yoyo lo ̣́wo ̣́ ;
bó ti dé e ̣́yìn Ìjàpá , àfi ṣìn -ìn-ìn, ló te ̣́ e ̣́ bo ̣́ o ̣́ lo ̣́rùn .Ìjàpá kò lè dún po ̣́bo ̣́ , ó kú
pátápátá.Oṣ́ anyìn bá gbé òkú re ̣́ lọ so ̣́do ̣́ ọba. Ọba ní kíOṣ́ anyìn máa gbé e lọ, àtòkú àtààyè
re ̣́, Oṣ́ anyìn lóun tí pinnu àti fi olè náà fún un te ̣́le ̣́ . Torí náà kí Oṣ́ anyìn lọ ṣe òkú Abahun
bó ti wù ú.
Inú Oṣ́ anyìn dùn , díndín ló lọ dín Ìjàpá jẹ o . Látọjo ̣́ yìí ni wo ̣́n ti ń fi‟Ìjàpá bọ
Oṣ́ anyìn o, tí wo ̣́n sì ń pe Ìjàpá ní „ẹran o ̣́sanyìn o‟.
Olè àti àṣejù ló pa Ìjàpá o; ìwà tí ò sunwo ̣́n, e ̣́ jù ú le o.
̣́
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Bí n bá puro,̣̀ kágogo ẹnu mi má ròó,
Bí n ò bá purọ, kágogo ẹnu mi ró le ̣̀e ̣̀mẹta –
Ó di …pó….pó….pó!
Orísun ìtàn: Babalọla (1973)

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìtàn yìí, Ìjàpá náà tún ni e ̣́dá -ìtàn ge ̣́ge ̣́ bí a ti rí i nínú ìtàn méjì àko ̣́ko ̣́ ní abe ̣́
ìpín kínní àti ìkejì . Alábahun fi ọgbo ̣́n e ̣́we ̣́ jí ikàn ní oko Baba oníkàn . Oṕ̣ o ̣́ ìgbà ni ó yí
ohùn padà láti kọ orin abàmì tí ó de ̣́rù ba bàbá oníkàn àti gbogbo ará ìlú . Ṣùgbo ̣́n àṣejù àti
ojúkókòrò ni ó pa Ìjàpá nígbe ̣́yìn.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Oṇ́ à wo ni Ìjàpá gbà tó fi ń jí ikàn baba oníkàn?
2. Ṣe àgbéye ̣́wò orin inú àlo ̣́ yìí. Eẹ́ ̣́melòó ni orin yìí wáyé nínú àlo ̣́ yìí? Iṣe ̣́ wo ni orin
ń ṣe nínú àlo ̣́? Wo modu keji, ìpín kínní fún ìto ̣́so ̣́nà.
3. Nínú àwọn koko -o ̣́ro ̣́ tí a ye ̣́wò ní Módù kẹta , ìpín kínní, èwo nínú àwọn kókó -o ̣́ro ̣́
yìí ló ro ̣́mo ̣́ ìtàn tí o kà yìí.

54
4. Ṣé òóto ̣́ ni pé àbùdá ìhun ìtàn „àṣeṣetúnṣe ìṣe ̣́le ̣́‟ jẹyọ nínú ìtàn yìí ? Tó bá je ̣́ lóòóto ̣́,
lo ̣́nà wo ni èyí gba jẹyọ?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Babalọlá, A. (1979) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kejì. Ibadan: University Press Ltd.

55
Ìpín kẹrin: Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka Ìtàn Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Wo ifaara abe ̣́ ipin kinni

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Èyí kò yàto ̣́ sí ti ìpín kínní

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Ẹranko mélòó ló wà nínú ìtàn yìí?
2. E ̣́dá-ìtàn mélòó ló wà nínú àkọlé ìtàn náà?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
3.1 Ka itan inu ipín yìí – Ìtàn Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ o!
Àwọn Jànmọ: Àlo!̣̀
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ mi dá fììrìgbágbòó, ó dálérí Ìjàpá, Ajá, Ẹkùn àti Ọdẹ

Ní ìgbà láéláé , Ẹkùn, Ìjàpá àti Ajá, inú igbó kan náà ni wo ̣́n ń gbé . Ẹkùn je ̣́ àgbe ,̣́ ó gbin
o ̣́ge ̣́de,̣́ ilá, e ̣́fo ̣́, iṣu, e ̣́ge ̣́, àgbàdo àti oríṣiríṣi nǹkan tí ẹnu ń jẹ. Gbogbo ohun o ̣́gbin re ̣́ lo s ̣́e

56
dáadáa: iṣu re ̣́ ta àta-sán-ebè, àgbàdo re ̣́ yọmọ bo ̣́kùàbo ̣́kùà , erèé re ̣́ so jìnwìnnì , ìgbá-ikàn
re ̣́ so do ̣́kìàdo ̣́kìà, ó so àsokanle ̣́, gbogbo re ̣́ dara.
Ìjàpá rèé , o ̣́lẹ ni , ẹni tí kò bá sì ṣiṣe ̣́ ti ń fe ̣́ jẹun da ndan ni koluware ̣́ jale ; olè ni
Ìjàpá, oko-olóko ló ti ń kórè ohun tí yóò jẹ.
Ní ọjo ̣́ kan , Ìjàpá fe ̣́ lọ jí irè -oko Ẹ́kun , ó mo ̣́ pé bí Ẹkùn bá mú òun , pe ̣́rẹpe ̣́rẹ ni
yóò fa òun ya , ó lọ bá Ajá , ó be ̣́e ̣́ kí ó bá òun lọ sí oko òun . Ajá rèé, o ̣́tá ni òun àti Ẹkùn
nítorí Ẹkùn fe ̣́ràn àt ipa Aja je ̣́. Ìjàpá ń ta ọgbo ̣́n àtifi orí Ajá fún Ẹkùn fọn fèrè ; ó rò nínú
ara re ̣́ pe bi oun ba le tan Aja de ibudo Ẹ́kun , òun á tì í mo ̣́lé, bí ẹkùn bá tile ̣́ dé , òun á sọ
pé Ajá lòun múwá fún un ge ̣́ge ̣́ bí nǹkan àlejò , yóò dáríjì òun. Ajá kò mo ̣́ pé oko Ẹkùn ni
Ìjàpá ń tan òun lọ, ó te ̣́lé e ní ìrètí pé oko Ìjàpá lòun ń lọ . Nígbà tí wo ̣́n dé oko Ẹkùn , wo ̣́n
kò bá Ẹkùn lóko. Ìjàpá be ̣́re ̣́ sí í be ̣́ o ̣́ge ̣́de ̣́, ó ń wa iṣu, ó ń fe ̣́ e ̣́fo ̣́, ó ń já erèé, ó ń re ata, kò
sí irè-oko kan to wa ni oko Ẹ́kun ti Ijapa ko ji .
Nígbà tó pe ̣́, ó di gbogbo ohun to ji yii jo ̣́ , ó ní kí Ajá wá bá òun gbé díe ̣́ , Ajá bá a
gbé e . Nígbà tí wo ̣́n gbérù tán tí wo ̣́n wo iwájú báyìí , Ẹkùn ni wo ̣́n rí tó ń sáré bo ̣́
takọtakọ. Bí Ajá ti rí Ẹkùn báyìí, jẹbẹtẹ gbo ̣́mọ lé e lo ̣́wo ̣́, ó be ̣́re ̣́ sí í gbo ̣́n.
„Ijapa, ṣebí ó sọ fún mi pé oko rẹ là ḿbo ,̣́ àṣéè oko Ẹkùn ni. O wa tan mi fun Ẹ́kun
pajẹ ni.‟
„Yara sapamo ̣́ se ̣́yin o ̣́ge ̣́de ̣́ yii, kò ní rí ọ. Ẹkùn kàn ń kọjá lọ nítire ̣́ ni.‟
Ajá ju ẹrù síle ̣́ pe ̣́e ,̣́ ó sápamo ̣́ sí e ̣́yìn igi o ̣́ge ̣́de ̣́, ó ń fọkàn re ̣́ gbàdúrà pé kí Ọlo ̣́run
yọ òun lo ̣́wo ̣́ Ẹkùn o . Je ̣́je ̣́ lòun jókòó sílé òun tí Ìjàpá ní kóun wá kálọ sí oko o , òun kò
mo ̣́ pé Ẹkùn ni yóò tan òun fún pajẹ o . „Iwo ̣́ Ọ́lo ̣́run Ẹ́le ̣́daa , ìwọ ló dá mi tí o sì dá Ẹkùn
yìí, má ṣàì yọ mí nínú ewu yìí o, má je ̣́ kí ń dìjẹ fún Ẹkùn lónìí o.
Nígbà tí Ajá ṣì ń gbàdúrà báyìí , Ẹkùn ti do ̣́do ̣́ Ìjàpá, ó bí i ohun tó wá mú nínú oko
òun. Ìjàpá dáhùn pé, „Kabiyesi, olówó mi, ọkọ mi, má bá mi wí , èmi ko ̣́ ni mo rán ara mi
wá, rírán ni wo ̣́n rán mi, n ko si mo ̣́ pe oko yin ni. Ẹ jo ̣́wo ̣́ ẹ foríjì mí, n o ni de sakani oko
yín mo ̣́.‟
„Wo ̣́n ran o ̣́ ni! Ta ni ran o ̣́ wa kore gbogbo isẹ́ ̣́ ti mo fi oogun oju mi s ̣́e?‟
„Aja ni!‟
„Aja!Ajá tàbí kínla!‟

57
„Aja ni; a jijo ̣́ wa naa ni, mo ro pe oko re ̣́ ni, n ko mo ̣́ pe tiyín ni, olúwa mi.‟
„Nibo l‟Aja o ̣́hun wa?‟
„Oun lo le ̣́ se ̣́yin o ̣́ge ̣́de ̣́ agbagba lo ̣́hun -ún nì. Ìgbà tí ó rí yín náà ni ó sápamo ̣́ síbe ̣́ .
N ko le sare lo je ̣́ ki e ̣́ ri mi mu ni iro ̣́wo ̣́ro ̣́se bayii.‟
Nígbà tí Ajá gbo ̣́ pé Ìjàpá ti fi òun hàn, tí ó sì puro ̣́ ràbàtà báyìí mo ̣́ òun, ó bú eré dà
síle,̣́ ìjáfara léwu, bí òun kò bá sá, òun di ìjẹ fún Ẹkùn nìyẹn . Bí Ẹkùn ti rí Ajá lo ̣́o ̣́kánkán
báyìí, ó fi Ìjàpá sí le ̣́, ó be ̣́ te ̣́lé e , ó di púrà , ó di kìtà kìtà kìtà , wo ̣́n ń sáré lọ lẹlẹ , gìgìríse ̣́
wọn ń kan wo ̣́n nípàko ̣́ bí wo ̣́n ti ń sáré lọ . Ajá ń sá àsálà fún e ̣́mí re ̣́ , Ẹkùn ń sáré oúnjẹ ,
wo ̣́n ń forí rún oko l ọ girigiri.Ìjàpá nítire ̣́ ti kó èyí tí yóò jẹ ní nú irè-oko to kore , ó bá ẹse ̣́
re ̣́ so ̣́ro ̣́, ó gba àbùjá lọ sí ihò àpáta tí ó ń gbé.
Ajá ń sáré lọ , ó la ẹ nu sile ̣́, ó ń mí hẹlẹhẹlẹ , àáre ̣́ ti ń mú u , síbe ̣́ ó forítìí , tí ó bá
dúró, Ẹkùn á fi í jẹ , òun á kúkú sáré àsákú tàbí àsálà . Nígbà tó yá , ó rí ọlo ̣́dẹ ka n
lo ̣́o ̣́kankan, eléyìíni ge ̣́gùn , ó ń dèsun ẹranko , Ajá fi òpópó o ̣́do ̣́ re ̣́ ṣo ̣́nà , ó ń sáré lọ
gbururu, ó ń ké pé , „Gba mi , ọdẹ, ọlo ̣́dẹ gbà mí, n o de ̣́ru re ̣́, Ẹkùn ni ń lé mi bo ̣́! Gbà mí,
mo sa di o ̣́.Gbà mi o máa mú mi relé, gbà mi o rà mí!‟
Ojú ti ọlo ̣́dẹ gbé sókè báyìí, Ẹkùn ló rí tí ń sáré kíkankíkan te ̣́lé Ajá . Kíá ló bá táwo ̣́
sí ìbọn re ̣́, ó di gàà! Ìbọn mú Ẹkùn le ̣́se ̣́, ẹse ̣́ re ̣́ kan dá, ó ṣe ̣́rí padà, ó ń sá wo ̣́nkúwo ̣́nkú lọ.
Ajá ní òun kò lè gbé nínú igbó náà mo ̣́ nítorí Ẹkùn yóò máa ṣo ̣́ òun kiri ni , yóò sì
wá pa òun jẹ lóru níbi yòówù kóun sá sí . Ìjàpá lè fi òun wá ojúrere lo ̣́do ̣́ Ẹkùn kí ó fi
ibùdó òun hàn án. Torí náà ó sàn kí òun kúkú bá olóore òun lọ.
Láti ìgbà yìí ni Ajá ti ń bá ọlo ̣́dẹ rìn o, tí Ajá kò gbé inú oko mo ̣́ tó fi di o ̣́kan nínú
àwọn ẹran o ̣́sìn nílé o.
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Bí n bá puro,̣̀ kágogo ẹnu mi má ròó,
Bí n ò bá purọ, kágogo ẹnu mi ró le ̣̀e ̣̀mẹta –
Ó di …pó….pó….pó!
Orísun ìtàn: Babalọla (1979)

58
5.0 Ìsọníṣókí
Ìjàpá tan Ajá lọ jí ohun o ̣́gbìn ní oko Ẹkùn . Ojúkòkòrò Ìjàpáni o mu Ẹ́kun ka wo ̣́n
mo ̣́ inú oko re .̣́ Ìjàpá puro ̣́ mo ̣́ Ajá lo ̣́do ̣́ Ẹkùn pé Ajá ni ó rán òun wá jalè lóko Ẹkùn . Ó sì
fi ibi ti Ajá sá pamo ̣́ sí han Ẹkùn . Ẹkùn lé Ajá láti pajẹ . Ó pàdé Ọlo ̣́dẹ .Ọlo ̣́dẹ sì gba Aja
síle ̣́ lo ̣́wo ̣́ Ẹkùn.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Ge ̣́ge ̣́ bí o sẹ́ ka ninu itan yii, irú e ̣́dá wo ni Ìjàpá?
2. Dárúkọ ohun o ̣́gbìn márùn-ún tí ó wà nínú oko Ẹkùn.
3. Ta ni o gba Aja sile ̣́ lo ̣́wo ̣́ Ẹ́kun?
4. Kí ni ìdí tí Ajá fi jẹ ẹran o ̣́sìn nílé?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Babalọlá, A. (1979) Àkójọpo ̣̀ Àlo ̣̀ Ìjàpá, Apá Kejì. Ibadan: University Press Ltd.

59
MÓDÙ KARÙN-ÚN: ÀTÚPALE ̣́ ÀṢÀYÀN ÀWỌN ÀLO ̣́ OLÓROGÚN
TÀBÍ ÀLO ̣́ MÌÍRÀN
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Orogún Méjì àti Ọkọ wọn
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Nínú Módù yìí, a o sẹ́ atupale ̣́ awo ̣́n as ̣́ayan alo ̣́ olorogun tabi awo ̣́n alo ̣́ miiran ti o yato ̣́ si
àlo ̣́ Ìjàpá. A sẹ́ akojo ̣́po ̣́ awo ̣́n alo ̣́ wo ̣́nyi fún ake ̣́ko ̣́o ̣́ láti kà ní àkàgbádùn àti láti ṣe àmúlò
àwọn iṣe ̣́ tí a ti s ̣́e ni abe ̣́ modu kinni titi de ike ̣́ta fun itupale ̣́ awo ̣́n alo ̣́ yii.
Ìpín kínní: Ìtàn Orogún Méjì àti Ọkọ wọn
Ìpín kejì: Ìyáálé Gbé Ọmọ Ìyàwó Re ̣́ Sínú Ọtí
Ìpín kẹta: Ìyáálé Roko Tán
Ìpín kẹrin: Tanímo ̣́la àti Orogún Ìyá Re ̣́
Títí di ìsinyìí , o kò ní àǹfààní àti ka àwọn ìtàn mìíràn tàbí àlo ̣́ olórogún ní kíkún .
Le ̣́yìn kíka ìtàn yìí ní àkàgbádùn , ìwọ yóò dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ro ̣́ mo ̣́ ìtàn yìí èyí tí yóò
fi iyenisi ati itupale ̣́ itan naa han.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Le ̣́yìn ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́ yìí, ìwọ yóò lè:
(i) ka itan naa funra re ̣́ ni akagbadun
(ii) dáhùn àwọn ìbéèrè tó ro ̣́ mo ̣́ àwọn ìtàn náà.
(iii) mọ bí a ṣe ń ṣe àtúpale ̣́ àlo ̣́ nípa ṣíṣe àmúlò àwọn ohun tí a ti gbéye ̣́wò ní

60
Módù 1 – 3.

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Irú àlo ̣́ wo ni à ń pè ní àlo ̣́ olórogún?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan Orogun meji ati Ọ́ko ̣́ wo ̣́n
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ o!
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àlo!̣̀
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ mi lérí fùùrùgbágbòó
Agbáloọ̀ :̣̀ Kó máà gbágbo ọmọ mi lọ
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ mi lérí kò lérí,
Àlo ̣̀ mi lérí àwọn ìyàwó méjì àti ọkọ wọn

Ọkọ wọn je ̣́ e ̣́ni ti maa n sọ́ ̣́de ̣́ lo ̣́ si idale ̣́.Bí ó bá sọdẹ lọ nígbà mìíràn, ó le lo oṣù me ̣́ta.Èyí
sì ti mo ̣́ awo ̣́n iyawo re ̣́ lara . Ṣùgbo ̣́n bí ó bá ń ti ìdále ̣́ bo ̣́ o ̣́po ̣́lọpo ̣́ aláàárù ló máa ń gbà tí
yóò ru ẹran tó ti pa te ̣́lé e . Ó ti pa erin ri . Ó sì ti pa ẹfo ̣́n . Beẹ́ ̣́ sì ni ọwo ̣́ re ̣́ ti tẹ kìnnìún
le ̣́e ̣́kan. Ojú ogúnjọ tí ọdẹ aperin bá ti ìgbe ̣́ ọdẹ dé àwọn obinrin re ̣́ pe ̣́lu awo ̣́n e ̣́bun Ọ́lo ̣́run
woṇ́ sì máa ń ṣọdún ẹran ni. Àwọn ìyàwó kì í wo ̣́n ní ìdí ààrò. Bí wo ̣́n ṣe ń sè ni wo ̣́n máa
ń so ̣́.
Oríṣiríṣi ènìyàn ló máa ń wá kí ọdẹ yìí bí ó bá ti dé . Ọdẹ náà sì je ̣́ ẹni tí ó lawo ̣́
dáadáa, gbogbo awo ̣́n alejo wo ̣́nyi lo maa wa n fun un ni nnkan . Oríṣiríṣi ìròyìn ohun tí ó
ti s ̣́e ̣́le ̣́ le ̣́yin ti o ti kuro nile ni wo ̣́n maa n so ̣́ fun un . Ìròyìn tí wo ̣́n sì fún un nipa iyaale re ̣́
kì í ṣe èyí tó rẹwà . Wo ̣́n máa ń fi yé e pé bí ó bá ti kúrò nílé tán ni ìyáálé re ̣́ máa ń ṣe
àgbèrè káàkiri ìlú . Ṣùgbo ̣́n ohun tí ó jọ ni lójú ni pé ìyáálé yìí ló máa ń sọ fún ọkọ wọn pé
ìwà àgbèrè ti w ọ ìyàwó òun le ̣́wù àti pé bí ọkọ bá ti kúrò nílé tán kò lówò méjì le ̣́yìn
ìṣekúṣe.
Ọkọ yìí ní àléébù kan , ìwà náà sì ni pé ó fe ̣́ràn ìyáálé re ̣́ ju ìyàwó lọ . Ó sì je ̣́ kí èyí
hàn sí àwọn méjéèjì . Ìdí nìyí tí ó fi je ̣́ pé bí ìyáálé bá ti ro ẹjo ̣́ pé ìyàwó ń ṣe àgbèrè kì í
bojú we ̣́yìn mo ̣́ ti fi máa ń kó ẹgba yá a. Ṣùgbo ̣́n nígbà tí ó lọ sí oko ọdẹ ní àsìkò kan , ó pe ̣́

61
ju bi o s ̣́e maa n pe ̣́ lo ̣́, odidi o ̣́dun me ̣́ta lo lo ni irin ajo. Ní ààrin ọdún me ̣́ta yìí, ó bá àwọn
ẹranko tí ń ṣeré ìfe ̣́ tó e ̣́e ̣́mejì . Ge ̣́ge ̣́ bí àṣà Yorùbá , bí èyí bá sì ṣẹle ̣́ sí ọdẹ kan àpẹẹ rẹ pé
ìyàwó re ̣́ ń ṣàgbèrè ni ó je.̣́
Nígbà tí ó rí àmì yìí ní ìgbà me ̣́rin o ̣́to ̣́o ̣́to ̣́ ni ó bá fi o ̣́ro ̣́ lọ ọdẹ ẹle ̣́gbe ̣́ re ̣́ kan . Eléyìí
ló wá bèèrè bóyá ó le ̣́ran o ̣́sìn nílé. Ọdẹ sì dáhùn pé òun ní àgbò kan. Ọdẹ wá fi ìdí òògùn
kan han an. Ó ní bí ó bá ti fi í sí ara Àgbò náà kí ó sọ pé kí àwọn ìyàwó re ̣́ máa fún Àgbò
náà ní ewé ọdán ní o ̣́ko ̣́o ̣́kan kí wo ̣́n sì máa kọrin báyìí pé:
Apàlo:̣̀ Gbewé mi, gbewé mi jẹ
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àgbò, gbewé mi jẹ
Apàlo:̣̀ Ọdún me ̣̀ta ọkọ ti lọ
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àgbò, gbewé mi jẹ
Apàlo:̣̀ Èmi ò rìnà boḳ̀ ùnrin pàdé
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àgbò, gbewé mi jẹ
Apàlo:̣̀ Ọkùnrin ò te ̣̀ni fún èmi sùn rí
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àgbò, gbewé mi jẹ

Bí ọkọ ṣe délé, ó ní sùúrù, ó ní kí o ̣́ko ̣́o ̣́kan àwọn ìyàwó òun méjéèjì ṣe pe ̣́pe ̣́fúúrú fún òun
fún bí ọjo ̣́ me ̣́ta ni ó bá dán òògùn ná à wò. Ìyàwó ni ó ko ̣́ko ̣́ já ewé ọdán tí ó sì kọrin òkè
yìí, kíá ni Àgbò gba ewé re ̣́ jẹ . Ṣùgbo ̣́n nígbà tí ó di orí ìyáálé ni Àgbò kò bá gba ewé re ̣́
jẹ. Ṣé ìwà àgbèrè sì je ̣́ e ̣́ṣe ̣́ ńlá ní ayé ìgbà náà, kò jọ òde òní tí àwọn kan fi ń sánjú oge ,
òfin ìlú wọn ni pé pípa ni wo ̣́n máa ń pa obìnrin tí wo ̣́n bá ti mú fún ìwà àgbèrè . Báyìí ni
wo ̣́n pa ìyáálé alágbèrè náà.
E ̣́ko ̣́ ìtàn yìí ko ̣́ wá pé kí á yẹra fún ìwà àgbèrè àti iro ̣́ pípa.
Apàlo:̣̀ Ibi ti mo de niyi ti mo de ̣̀yin
Kí àlo ̣̀ mi gba orógbó jẹ
Kí ó má ṣe gba obì jẹ
Orógbó á gbó wọn sáyé
Obì á bì woṇ̀ soṛ̀ un
Bí mo bá puro ̣̀

62
Kí agogo ẹnu mi maa ro ni e ̣̀e ̣̀me ̣̀ta
Ṣùgboṇ̀ bí n kò bá paro ̣̀
Kí ó ró
Ó di pó! pó!! pó!!!
Ó ró tàbí kò ró?

Àgbáloọ̀ :̣̀ Ó ró.


Orísun ìtàn: Oṕ̣ ádo ̣́tun (1994)

5.0 Ìsọníṣókí
Nínú ìtàn yìí, a ri o ̣́na ìṣíde ìtàn náà èyí tí a ti fún wa ní àpẹẹrẹ irúfe ̣́ re ̣́ ní abe ̣́ Módù
kẹta. Le ̣́yìn èyí , a ri isọ́ ro to wa ni ile olorogun ati iwa agbere ti iyaale hu . A le so ̣́ pe
àwọn kókó o ̣́ro ̣́ tí ìtàn náà dá l érí ni ìwà àìṣòdodo àti ìwà àgbèrè èyí tí ìyáálé hù èyí tí ó fa
ikú re ̣́.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


Dáhùn àwọn ìbéèrè wo ̣́nyí:
1. Iṣe ̣́ wo ni ọkọ àwọn orogún méjì yìí ń ṣe?
2. Ṣe àpèjúwe ìwà ìyáálé inú ìtàn yìí.
3. Àwọn kókó wo ni ó jẹyọ nínú ìtàn náà?
4. Oṇ́ à wo ni ọkọ yìí gbà láti mọ òóto ̣́ láàárín ìyáálé àti ìyàwó?
5. Àwọn e ̣́dá-ìtàn mélòó ló wà nínú ìtàn yìí?
6. Kí ni ìyàto ̣́ láàrin bátànì ìparí àlo ̣́ yìí àti èyí tí a gbéye ̣́wò ní Módù kẹta, Ìpín kejì?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

63
Ìpín kejì: Àtúpale ̣́ Ìtàn Ìyáálé Gbé Ọmọ Ìyàwó Re ̣́ Sínú Ọtí
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Ìyáálé Gbé Ọmọ Ìyàwó Re ̣́ Sínú Ọtí
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Wo ifaara abe ̣́ ipin kinni ni Modu yii.

2.0 Èròǹgbà
Wo erongba abe ̣́ ipin kinni ni Modu yii bakan naa

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Kí ni ìtumo ̣́ ìyàálé?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan Iyaale gbe ọmọ ìyàwó re ̣́ sínú ọtí
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ o!
Àgbáloọ̀ :̣̀ Àlo!̣̀
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ mi lérí fùùrùgbágbòó
Agbáloọ̀ :̣̀ Kó máà gbágbo ọmọ mi lọ
Apàlo:̣̀ Àlo ̣̀ mi lérí kò lérí,
Ó lérí ọkùnrin àgbe ̣̀ kan tó fe ̣̀ràn iṣe ̣̀ oko.

64
Ó fe ̣́ ìyàwó àko ̣́fe ̣́ ní rògbàrògbà . Ó ṣe gbogbo ohun tí wọn ń ṣe lé aya lórí kí wo ̣́n tó sin
Èjìdé fún un tìlù tìfọn. Ẹnu kọ ìròyìn ní ọjo ̣́ ìgbéyàwó wọn. Ọkùnrin àgbe ̣́ yìí náwó gidi ní
ọtíkà te ̣́ lo ̣́jo ̣́ náà , kò níyì kankan . Ọtí ṣe ̣́ke ̣́te ̣́ po ̣́ bí omi òkun . Be ̣́e ̣́ sì ni kì í ṣe àsìkò ọtí
òyìnbó ni àgbe ̣́ yìí kì bá rà. Ṣùgbo ̣́n ọtí àgàdàngidi náà wá sí ibi ayẹyẹ.
Ọdún kan le ̣́yin igbeyawo agbe ̣́ ati Ejide , ìròyìn ìyàwó yìí kò tán níle ̣́ . Nígbà tí ó
tile ̣́ yá ni wo ̣́n bá sọ o ̣́ di àṣà , wọn á sì sọ pé ináwó kan kọyọyọ bí ìnáwó ìgbéyàwó Èjì dé
àti bàbá àgbe ̣́.
Ṣé ènìyàn kò le gbo ̣́n títí kí tire ̣́ máà bá a . Be ̣́e ̣́ sì ni kò sí e ̣́dá tí kò ní ìṣòro tire ̣́ , àní
kálukú ló ní tire ̣́ lára. Agbo ̣́n dára títí, oró ńko ̣́, ìkamùdù sunwo ̣́n lóòóto ̣́ ó kù sí ibi òó rùn.
Àní bí ẹmo ̣́ òyìnbó ṣe yááyì tó àìnírù ni àléébù ẹranko . Èjìdé àti bàbá àgbe ̣́ fe ̣́ràn ara wọn
bí e ̣́mí . Wo ̣́n lóúnjẹ nílé , wo ̣́n láṣọ lára wọn sì ní owó lápò lápò .Ṣùgbo ̣́n ewúre ̣́ tí bà bá
àgbe ̣́ tún fe ̣́ràn le ̣́yì n Ejidelo sẹ́ e ̣́ke ̣́ta wo ̣́n ninu ile . Nígbà tí ó sì di ojú ọdún kẹsàn -án tí
Èjìdé kò rí oyún,ni baba agbe ̣́ ba fe ̣́ iyawo tuntun le e.
Èjìdé àti ìyàwó kékeré tí orúkọ re ̣́ ń je ̣́ Mopé fe ̣́ràn ara wọn . Irú aṣọ kan náà ni wo ̣́n
máa ń wo ̣́, be ̣́e ̣́ sì ni gèlè wọn kì í yàto ̣́ . Kò se ̣́ni tó le rí wọn kí ó pè wo ̣́n ní obìnrin ọkọ
kan naa . Ńṣe ni wọn ń hùwà bíi ọmọ ìyá kan náà . Nígbà tí yóò sì fi tó ọdún kan tí Mop é
délé ó ti lóyún . Ó sì fi oyún náà bí ọmọkùnrin kan làǹtìlanti . Ńṣe ni Èjìdé ń ra ọmọ yìí
me ̣́yìn kiri. Ṣàṣà ènìyàn ló sì mo ̣́ pé kì í ṣe òun ló bí i. Àṣé ìfe ̣́ tí a fe ̣́ adìẹ kò dénú ni ìfe ̣́ tí
Èjìdé ní sí ọmọ ìyàwó re ̣́. Ojú ayé lásán ló ń ṣe, kò gbàdúrà kí ọmọ náà ó yè.
Ọtíkà ni Èjìdé máa ń tà . Ìkòkò aládi ńlá ló fi máa ń dáná re ̣́ . Bàbá tó àsìkò tó yẹ kí
ó ti oko dé ni wọn kò róye bà bá. Nígbà tí wo ̣́n retí rétí tí etí di rere ni ìyàwó kékeré tí í je ̣́
Mopé bá ní òun tọ ẹse ̣́ ọkọ lọ sí oko. Kín ni Mopé kúrò ní ilé sí ni Èjìdé bá gbé ọmọ , ó di
so ̣́dù nínú iná ọtí.
Nígbà tí Mopé yóò fi rin ibuso ̣́ meji lo ba pade o ̣́ko ̣́ re ̣́ lo ̣́na . Ọkọ ni òun pa
àgbo ̣́nrín ni òun ń ṣaáyan re ̣́ ló je ̣́ kí òun pe ̣́ . Báyìí ni Mopé àti ọkọ fi ìdùnnú ru ẹran
àgbo ̣́nrín padà sí abúlé wọn. Eṛ́ ín àti o ̣́yàyà sì ni Èjìdé fi kí àwọn méjéèjì kú àbo ̣́.
Bí wo ̣́n ṣe simi díe ̣́ tán ni ìyàwó bá wọ ìye ̣́wù lọ láti yẹ ọmọ re ̣́ wò níbi tí ó te ̣́ ẹ sí
ni o ̣́mo ̣́ ba di awati . Èjìdé sì sọ pé òun kò mọ ibi tí ọmọ wà . Báyìí ni wo ṇ́ s ̣́aa wa o ̣́mo ̣́ titi

65
tí wọn kò sì rí aáràfi ọmọ . Ṣé amòòkùn jalè , bí ọba ayé kò rí i , ọba ti o ̣́run ń wò ó . Àṣé
gbogbo igba ti Ejide fi n gbe o ̣́mo ̣́ ju sinu ikoko o ̣́ti ni ewure ̣́ o ̣́ko ̣́ wo ̣́n n s ̣́o ̣́ o .̣́
Le ̣́yìn tí wo ̣́n ti wá ọmọ títí tí agara sì ti dá wọn ni ewúre ̣́ bá be ̣́re ̣́ sí kọrin báyìí pé:
Apàlo:̣̀ Orogún burúkú
Àgbáloọ̀ :̣̀ Kónkolà kónkòlá kó-n-kó
Apàlo:̣̀ Ó gbom
̣̀ ọ sọ soṭ̀ í
Àgbáloọ̀ :̣̀ Kónkolà kónkòlá kó-n-kó
Apàlo:̣̀ Bó bá jọ bí iro ̣̀ ẹ wo inú ọtí wò
Àgbáloọ̀ :̣̀ Kónkolà kónkòlá kó-n-kó

Bí ewúre ̣́ yìí ṣe ń kọrin ni Èjìdé ní “Ẹ ò wa , wo ewure ̣́ adasinilo ̣́run , ọjo ̣́ wo lòun wá
gbo ̣́mọ sọ sínú ọtí ?” Ṣ́ùgbo ̣́n ewúre ̣́ kò yéé kọrin . Báyìí ni ọkọ wọn ṣe kó àwọn ìyàwó
méjéèjì àti ewúre ̣́ dé ààfin ọba . Bí ewúre ̣́ sì ṣe kọrin yìí ni ọbá ní kí àwọn ìránṣe ̣́ re ̣́ lọ gbé
ìkòkò ọtí náà wá. Nígbà tí wo ̣́n sì wo inú ìkòkò ọtí, òkú ọmọ ni wo ̣́n bá níbe ̣́. Báyìí ni ọba
pàṣẹ pé kí wo ̣́n be ̣́ Èjìdé lórí ní ìdí ògún.
E ̣́ko ̣́ tí ìtàn yìí ko ̣́ wa ni pé kò yẹ kí á máa ṣe ìkà àti ìlara . Kò sí ohun tí Ọlo ̣́run ṣe
fún e ̣́nikan ti ko le sẹ́ fun awa naa , ṣùgbo ̣́n kí á máa dúró de àsìkò tiwa.
Apàlo:̣̀ Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Kí of̣̀ oṇ̀ -oṇ̀ gun àjà
Kí ó gbé ẹgbàá kò mí
Kí n fi agogo e ̣̀nu popo
Ogbó orógbó ni kí n gbó
Kí n má ṣe gbó ogbó obì
Ṣebórógbó ní kí n gbó ni sáyé
Obì níí bì woṇ̀ soṛ̀ un
Bí mo bá dé ìdí og̣̀ e ̣̀de ̣̀ àgbagbà
Kí n bímọ gbàǹgbà
Bí mo bá puro ̣̀

66
Kí agogo ẹnu mi máà ró ní e ̣̀e ̣̀mẹta
Ṣùgboṇ̀ bí n kò bá paro ̣̀ kí ó ró
Ó di pó! pó! pó!
Ó ró tàbí kò ró?
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ó ró. Orísun ìtàn: Oṕ̣ ádo ̣́tun (1994)

5.0 Ìsọníṣókí
Ìtàn yìí je ̣́ ìtàn olórogún . A si ri o ̣́kan lára ìṣòro tó wà ní ilé olórogún . Èyí ni ìlara
ìyáálé sí ìyàwó. Ìyáálé kò bímọ ṣùgbo ̣́n ìyàwó bí . Ìfe ̣́ ojú ni ìyáálé ní sí ìyàwó . Nígbà tí ó
yá ó fi ìwà re ̣́ tòóto ̣́ hàn nípa pípa ọmọ ìy àwó re ̣́ ní o ̣́nà búburú.Ó gbé ọmọ náà jù sínú orù
tí a fi ń se ọtí. Ọba sì dájo ̣́ ikú fún un fún ìwà o ̣́dájú yìí. Wo ̣́n be ̣́ orí ìyáálé ní ìdí ògún.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


Dáhùn àwọn ìbéèrè wo ̣́nyí:
1. Kí ni oruko ̣́ iyaale ati iyawo ninu itan yii?
2. Ọdún mélòó ni ìyáálé lò nílé ọkọ láìbímọ?
3. Iṣe ̣́ wo ni ìyàwó ń ṣe?
4a. Ǹ je ̣́ orin inú àlo ̣́ yìí ro ̣́ mo ̣́ kókó ìtàn náà?
b. Ní o ̣́nà wo?
5. Ṣe àpèjúwe ìwà ìyáálé yìí.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

67
Ìpín kẹta: Ìtàn Ìyáálé Roko Tán
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Ìyáálé Roko Tán ní àkàyé
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Wo ifaara abe ̣́ ipin kinni ni Modu yii.

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Wo erongba abe ̣́ ipin kinni ni Módù yìí bákan náà

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


Dárúkọ ìwà me ̣́ta tí Yorùbá bu ẹnu àte ̣́ lù.

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan ìsàle ̣́ yìí - Ìyáálé roko tán
Apàlo:̣̀ Ààlo ̣̀ o!
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ààlo!̣̀
Apàlo:̣̀ Ní ọjo ̣̀ kan
Agbáloọ̀ :̣̀ Ọjo ̣̀ kan ni òní je ̣̀
Koḅ̀ a je ̣̀ kó je ̣̀ ọjo ̣̀ rere fun wa
Apàlo:̣̀ Ní ìgbà kan
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ìgbà kan ń lọ,

68
Ìgbà kan ń bo,̣̀
Ìgbà kan kì í tán láyé
Apàlo:̣̀ Ọkùnrin kan wà tí ó ní ìyàwó kan.

Ó fe ̣́ ìyàwó re ̣́ ge ̣́ge ̣́ bí wo ̣́n ṣe ń fe ̣́ ìyàwó ní ayé ìgbà náà.Ìyàwó náà kò sì mọ ọkùnrin títí ó
fi dele o ̣́ko .̣́ Ṣùgbo ̣́n níbi tí iṣe ̣́ Olódùmarè je ̣́ àwámárìdìí sí , ìyàwó náà kò fi inú soyún be ̣́e ̣́
ni ko si fi e ̣́yin gbe o ̣́mo ̣́ po ̣́n fodidi o ̣́dun me ̣́waa le ̣́yin ti o ti dele o ̣́ko ̣́.
Le ̣́yìn tí gbogbo aláwo ilé ayé ti ṣe é tì ,ni wo ̣́n ba ko ̣́ri si o ̣́do ̣́ Ọ́lo ̣́run . Oṛ́ un kò sì
jìnnà sílé ayé báyìí nígbà náà , bí ènìyàn bá tètè lọ láàáro ̣́ títí ale ̣́ olúware ̣́ yóò dé .Nígbà tí
wo ̣́n dé o ̣́do ̣́ Aṣe ̣́dá .Ó ní kí wo ̣́n ní sùúrù nítorí pé ọmọ tí ń bẹ níle ̣́ kò dára . Ó ní
ìṣènìyànṣẹranko ọmọ ni . Ó ní adìẹ pile ̣́ ni, àmo ̣́ a tún máa mú àwo ̣́ ènìyàn nígbà mìíràn .
Tọkọ taya yìí ní kí Ọlo ̣́run ṣáà fún àwọn . Wo ̣́n ní ká rí ẹni báwí ṣàn ju àìrí báwí rárá .
Olódùmarè ni ó dára kí wo ̣́n máa lọ, Òun yóò mú ìbéèrè wọn s ̣́e ̣́.
Báyìí ni àwọn méjéèjì ṣe padà sílé ayé . Ìyàwó kò mú oṣù náà jẹ le ̣́yìn èyí tí wo ̣́n dé
tí ó fi lóyún . Le ̣́yìn oṣù kẹsàn -án ni ìyàwó náà bí obìnrin . Ọmọ náà dára ju ojo ilé tí mo
lọ.Ó rí wiliki wiliki.Ó dúdú bí kóró iṣin .Nígbà tí yóó fi tó ogún ọdún tí a bí ọmọ náà , ó ti
di o ̣́mo ̣́ge gidi sụ́ gbo ̣́n awo ̣́n obi re ̣́ ko tun gbo ̣́ mo -kó-ó ọmọ mìíràn mo .̣́ Gbogbo eniyan lo
sì ń pòòyì ilé wọn láti fi ọ mọ wọn saya. Bí ọmọbìnrin yìí ṣe dára tó, ó ní àléébù kan, èyí
náà sì ni pé ó máa ń yí padà sí adìẹ nígbà mìíràn . Bí ó bá ti yí padà báyìí, àgbàdo ni àwọn
òbí re ̣́ máa ń fún un títí tí yóò tún fi padà sí ènìyàn.
Nígbà tí ọmọbìnrin tí orúkọ re ̣́ ń je ̣́ Pẹrẹsẹkẹ rí ẹni tí ó wù ú láti fi ṣe ọkọ , àwọn òbí
re ̣́ sọ òóto ̣́ fún ọkùnrin náà .Ọmọbìnrin yìí ti wọ ọkùnrin náà lójú tí ó fi gbà láti fe ̣́ ẹ ní
o ̣́nàkọnà.Ó sì ṣe ìlérí pé gbogbo èèwo ̣́ re ̣́ lòun yóò máa pamo ̣́ . Bí ìyàwó yìí ṣe délé ni ọkọ
kìlo ̣́ fún ìyáálé re ̣́ pé kò gbọdo ̣́ fi bú u àti pé kò gbọdo ̣́ fún un ní oúnjẹ mìíràn le ̣́yìn àgbàdo
lásìkò tí Pẹrẹsẹkẹ bá di adìẹ.
Nígbà tí Pẹrẹsẹkẹ yóò fi lo ogójì ọjo ̣́ nílé ọ kọ, ìfe ̣́ re ̣́ ti kó sí ọkọ lórí , kò tile ̣́ rójú ti
ìyáálé re ̣́ mo ̣́.Wo ̣́n sì ti be ̣́re ̣́ sí fi Pẹrẹsẹkẹ síle ̣́ lọ sí oko. Ṣùgbo ̣́n bi wo ̣́n ba ti n lo ̣́ si oko ni
wọn yóò fi ọmọbìnrin kékeré kan (ọmọ ìyáálé) tì í, àwọn yòókù yóò sì lọ sí oko.

69
Bí Pẹrẹṣẹkẹ bá ti rí i pé wo ̣́n lọ sí oko tán ni ó máa ń di adìẹ tí yóò sì máa kọrin
báyìí pé:
Apàlo:̣̀ Ìyáálé roko tán
Agbáloọ̀ :̣̀ Pẹrẹsẹkẹ
Apàlo:̣̀ Bàbá roko tán
Agbáloọ̀ :̣̀ Pẹrẹsẹkẹ
Apàlo:̣̀ Mo waa raye di gbagbaka
Agbáloọ̀ :̣̀ Pẹrẹsẹkẹ
Apàlo:̣̀ Mo fo sihin-ín fò soḥ̀ ùn-ún
Agbáloọ̀ :̣̀ Pẹrẹsẹkẹ
Apàlo:̣̀ Ma fo pii dadie ̣̀
Agbáloọ̀ :̣̀ Pẹrẹsẹkẹ
Báyìí ni Pẹrẹsẹkẹ yóò ṣe máa fò láti igi ọdán sí orí igi òro tí yóò máa ti orí àjà fò sí òrùlé
títí yóò fi re ̣́ e ̣́ tí yóò sì tún di ènìyàn padà.
Bí gbogbo wọn bá ti ti oko dé ni ọmọbìnrin tó dúró ti ìyàwó náà ń sọ gbogbo ohun
tí ojú re ̣́ tó fún ìyá re ̣́ tí í ṣe ìyáálé Pẹrẹsẹkẹ . Ìyáálé yóò sì sọ fún ọkọ. Ṣùgbo ̣́n dípò kí èyí
dín ìfe ̣́ tí ọkọ ní sí Pẹrẹsẹkẹ kù , ńṣe ló túbo ̣́ ń po ̣́ sí i. Èyí ló mú kí ìyáálé pinnu láti fi òpin
sí ìfe ̣́ ààrin Pẹrẹsẹkẹ àti ọkọ re ̣́ . Báyìí ló ṣe padà lo ̣́nà oko ní ọjo ̣́ kan tí ó paro ̣́ fún ọ kọ pé
orí ń fo ̣́ òun. Ó lúgọ sí ibi kan nínú ilé, ó sì ní sùúrù títí Pẹrẹsẹkẹ fi di adìẹ t ó sì ń kọrin re ̣́
kiri. Nígbà tí adìẹ náà bà sí ìtòsí ni ó bá fún un ní àmàlà jẹ . Jíjẹ tí adìẹ jẹ àmàlà tán ni kò
bá le yí padà sí ènìyàn mo ̣́ . Àwọn adìẹ gidi sì be ̣́re ̣́ sí ṣá a ní ara . Pẹrẹsẹkẹ ọjo ̣́ náà ló di
Adìẹ aṣa. Ṣíṣá tí àwọn adìẹ fi ẹnu ṣá a lára ní ọjo ̣́ náà ló je ̣́ kí ara re ̣́ rí ṣákaṣàka títí di òní.
E ̣́ko ̣́ tí ìtàn yìí ko ̣́ wa ni pé kí á má ṣe máa gba nǹkan be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ , ọmọ be ̣́e ̣́ be ̣́e ̣́ ni
Pẹrẹsẹkẹ. Ó sì tún ko ̣́ wa kí á máa hùwà aríyàwó -kọ-ìyáálé ènìyàn, ìwà ọkọ Pẹrẹṣẹkẹ ló je ̣́
kí ìyáálé ta ìjàǹbá fún Pẹrẹṣẹkẹ . Ó tún ko ̣́ wa pé kò yẹ kí á máa fi gbogbo inú wa han
obìnrin. Bí ọkọ kò bá sọ èèwo ̣́ Pẹrẹsẹkẹ fún ìyáálé re ̣́ ni, kì bá ti lè ta ìjàǹbá fún un.
Apàlo:̣̀ Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbáńgbáláká;
Ìdí àlo ̣̀ mi rèé gbàǹgbàlàkà;
Kí of̣̀ oṇ̀ -oṇ̀ ó gàjà kó gbé ẹgbàá kò mí

70
Kí n fi agogo ẹnu pópó
Ogbó orógbó ni kí n gbó
Kí n má ṣe gbó ogbó obì
Orógbó ní í gbó ni sáyé
Obì níí bi ni soṛ̀ un
Bí mo bá puro ̣̀
Kágogo e ̣̀nu mi ma ṣe ró
Bí n ko ba paro ̣̀
Kí agogo ẹnu mi ró
Ó di pó! pó! pó!
Ó ró tàbí kò ró?
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ó ró!
Orísun ìtàn: Oṕ̣ ádo ̣́tun (1994)
5.0 Ìsọníṣókí
Ìtàn yìí dá lérí ọkọ àti ìyàwó tí wọn kò ní sùúrù láti wá ọmọ le ̣́yìn ọdún
me ̣́wàá.Wo ̣́n tọ Olódùmarè lọ .Ṣe o ̣́run kò jìnnà sí ayé nígbà náà . Olódùmarè ní kí woṇ́ ní
sùúrù pé ọmọ tó wà níle ̣́ ìṣènìyà nṣẹranko ni . Ṣùgbo ̣́n àìnísùúrù mú wọn gba irúfe ̣́ ọmọ
yìí.Bí ọmọ yìí kò ṣe pé tó, ìyáálé kò nífe ̣́e ̣́ re ̣́.Èyí ló mú u kó ó pinnu láti fi òpin sí ìfe ̣́ ọmọ
yìí àti ọkọ re ̣́.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


1. Júwe o ̣́nà tí tọkọ taya inu itan yii fi ri o ̣́mo ̣́.
2a. Kí ni orúkọ ọmọ náà?
b. Júwe ìrísí àti ìhùwàsí ọmọ náà.
3. Irú orin wo ni ọmọ yìí máa ń kọ tí àwọn òbí re ̣́ bá ti lọ oko tán?
4. Kí ni àwọn e ̣́ko ̣́ tí ìtàn yìí ko ̣́ wa?

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

71
Ìpín kẹrin: Ìtàn Tanímo ̣́la àti Orogún Ìyá Re ̣́
Àkóónú
1.0 Ìfáárà
2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn
3.0 Ìbéèrè ìṣaájú
4.0 Ìdánile ̣́ko ̣́o ̣́
4.1 Kíka ìtàn Ìtàn Tanímo ̣́la àti Orogún Ìyá Re ̣́
5.0 Ìsọníṣókí
6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe
7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí

1.0 Ìfáárà
Ìfáárà yìí kò yàto ̣́ sí ìfáárà tí ó wà ní àwọn ìpín ìṣaájú

2.0 Èròǹgbà àti Àfojúsùn


Wo erongba awo ̣́n ipin isaa
̣́ ju.

3.0 Ìbéèrè ìṣaájú


1. Kí ni ìtumo ̣́ orogún?

4.0 Ìdánileko
̣́ ̣́o ̣́
4.1 Ka itan tí ó wà ní ìsàle ̣́ yìí
Ìtàn Tanimo ̣́la àti Orogún ìyá re ̣́
Apàlo:̣̀ Ààlo ̣̀ o!
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ààlo!̣̀
Apàlo:̣̀ Ní ìgbàkan
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ìgbà kan ń lọ,
Ìgbà kan ń bo,̣̀
Ìgbà kan kì í tán láyé

72
Apàlo:̣̀ Ní ọjo ̣̀ kan
Agbáloọ̀ :̣̀ Ọjo ̣̀ kanlòní je ̣̀
Kórí je ̣̀ ó je ̣̀ ọjo ̣̀ rere fun wa
Apàlo:̣̀ Ní ìgbà kan
Apàlo:̣̀ Obìnrin kan wa
Agbáloọ̀ :̣̀ Ó wà bí e ̣̀wà
Apàlo:̣̀ Ó bí ọmọbìnrin méjì,
Orogún re ̣̀ sì fi ọmọbìnrin kan sí ayé lọ.
Orúkọ ọmọbìnrin tí ìyá re ̣́ ti kú yìí ń je ̣́ Tanímo ̣́la.Ṣé kò sí irú aṣọ tí arẹwà le wo ̣́ kí ẹwà re ̣́
móókùn. Obìnrin ọlo ̣́mọ méjì yìí ti gba àyà lo ̣́wo ̣́ ọkọ re .̣́ Ohun ti o ba so ̣́ ni abe ̣́ ge , òun ló
tile ̣́ ń ṣe bí ọkọ ní o ̣́de ̣́de ̣́ . Ọmọbìnrin naa ko niwa olookan , ó burú ju ikú tíí pa ni lọ .
Ṣùgbo ̣́n onífo ̣́n tí ó sọ pé inú òun kò dára ni , báwo ni ojú re ̣́ ṣe rí ni o ̣́ro ̣́ obìnrin yìí. Kì í ṣe
ìwà nìkan ni kò ní , kò tún le ̣́wà náà. Ó bure ̣́wà bí ìgbá, orí re ̣́ rí féégbé bí ìkéémù ẹle ̣́wo ̣́n .
Ojú re ̣́ rí kànngbo ̣́n-kànngbo ̣́n bí ìgbà tí erèé so ẹyọkan .Ẹse ̣́ re ̣́ rí fọn-ọnran bí ko ̣́bo ̣́ sáré sí
go ̣́tà.Ó ṣe ìdí pẹlẹbẹ, ó sì ṣe apá kánndá bíi ti orogún ẹle ̣́ran.
Obìnrin yìí tún wá dára ju àwọn ọmọ re ̣́ lọ, ṣé ẹni tí a bá sọ pé a ó jọ jíjù ni a máa ń
jù ú. Èyí ló je ̣́ kí àwọn ọmọ tó jọ ìyá wọn bí ìmumu ya ojúlówó òbure ̣́wà . Kò sí e ̣́yà ara
wọn tó ṣe é wò. Ṣùgbo ̣́n ọmọ dára ó dẹjo ̣́ ni ọmọ orogún ìyá wọn yìí . Ńṣe ló po ̣́n we ̣́e ̣́ láti
òkè dé ìsàle ̣́. Kò sí àléébù kan ṣoṣo ní gbogbo ara re ̣́.
Ẹwà ọmọbìnrin aláìsí yìí tí ó bùyààrì ni ó fi kún ìkórira tí orogún ìyá re ̣́ àti àwọn
ọmọ re ̣́ ní sí i . Kò sí ohun tí Tanímo ̣́la lè ṣe tí í dára lójú wọn . Bó bá wúko ̣́ wọn á ló dá
ogun, bó sì re ̣́rìn-ín wọn á ló kan ìjàngbo ̣́n. Àní bí ó bá ń jẹun lásán wọn á ní ó ń bu òkèlè
bí orí àbíkú.Wọn ṣá fi ayé ṣú Tanímo ̣́la yìí. Kàkà kí bàbá re ̣́ sì máa gbà á síle ̣́ lo ̣́wo ̣́ ìyá tí ń
jẹ bí ẹni jẹ iṣu báyìí , ńṣe ni bàbá yóò máa wò bí i ti o ̣́o ̣́kán -ilé. Kì í ṣe ẹjo ̣́ b àbá, ṣebí a ti
ṣàlàyé pé ìyàwó re ̣́ ti fi orí re ̣́ gba pààro ̣́.
Bí ibi ayẹyẹ kan bá wà, obìnrin burúkú yìí máa ń rú sínú aṣọ tó tinú aṣọ wá. Be ̣́e ̣́ ló
sì máa wọ àwọn ọmọbìnrin re ̣́ méjéèjì ní ajínínrin aṣọ. Àkúgbó aṣọ láabi ni í kì bọ
Tanímo ̣́la lo ̣́rùn. Ṣùgbo ̣́n ohun tí ó tún ń ba obìnrin náà nínú je ̣́ ni pé ńṣe ni àwọn ọkùnrin

73
máa ń ṣu Tanímo ̣́la rànyìnrànyìn tòun tàkísà . Àwọn ọmọ tire ̣́ kì í sì í rí ẹnìkan ṣoṣo pè
wo ̣́n wò.
Ìdí o ̣́ro ̣́ mà nìyí, tí orogún láburú yìí fi pinnu láti rán Tanímo ̣́la ní o ̣́run o ̣́sán
gangan. Èrò re ̣́ ni pé nígbà tí àwọn tí ń wá a wá kò bá rí i mo ̣́ , bóyá wọn yóò le máa wo
ojú àwọn ọmọ òun . Bó bá ṣe pé obìnrin náà kúkú dúnbú Tanímo ̣́la ni , o ̣́ro ̣́ kì bá sàn . Ńṣe
ló gbé agbè omi lé e lórí tí ó ní kí ó kọrí sódò lo ̣́jo ̣́ tí àwọn iwin ń ṣọdún wọn.
Báyìí ni Tanímo ̣́la ṣe lọ sí odò t í kò bo ̣́ . Inú obìnrin náà sì dùn dé mùdùnmúdùn
egungun. Èrò re ̣́ ni pé odò ti gbé oníye ̣́ye ̣́ lọ , ìjà òun sì ti tán. Àṣe ewé ló ń bẹ lórí iṣu là ń
be ̣́rù kànyìnkànyìn, obìnrin yìí kò tètè mo ̣́ pé ọlá ìkar ahun ni igbin n je ̣́. Àní kò tètè mo ̣́ pé
ọlá Tanímo ̣́la ni òun ń jẹ tí àwọn o ̣́do ̣́mọkùnrin fi ń dà gìrìgìrì nínú ilé òun. Bí Tanímo ̣́la ṣe
di awati bayii ni onikaluku wo ̣́n ti gbe jokoo sile wo ̣́n . Ìbànúje ̣́ wá dorí àgbà kodò . Inú
obìnrin yìí kò wá dùn mo ̣́, be ̣́e ̣́ sì ni ńṣe ni àwọn ọmọ re ̣́ ń kanra gógó bí ajá elékùúkú.
Ẹ je ̣́ kí á wá wohun tó ti ṣẹle ̣́ sí Tanímo ̣́la le ̣́yìn tí ó ti bo ̣́ so ̣́wo ̣́ àwọn iwin.Nígbà tí ó
ròyìn ohun tí ojú re ̣́ rí fún àwọn iwin , àwọn yẹn náà sì gbà láti ràn án lo ̣́wo ̣́ . Báyìí ni wo ̣́n
fún un lówó àti o ̣́po ̣́lọpo ̣́ nǹkan ọro .̣́ Ìlú re ̣́ tí yóò wo ̣́ báyìí ńṣe ló bá a tí ọba ìlú re ̣́ ṣe ̣́ṣe ̣́ ń
gbadé.Bí ọba ṣe rí i nínú ọláńlá re ̣́ be ̣́e ̣́ ló ní kí wo ̣́n sọ o ̣́ di olórí àwọn olorì.Bí orí ṣe gbé e
dé ibi ọlá nìyí.
Kò pe ̣́ púpo ̣́ tí Tanímo ̣́la di olorì ni wàhálà ṣẹle ̣́ sí orogún ìyá re ̣́ àti àwọn ọmọ
orogún náà. Ẹni kan kú sí wọn lo ̣́rùn , ńṣe ni wo ̣́n dì wo ̣́n ní àpànyàkà dé ààfin ọba . Wọn
kò dá Tanímo ̣́la mo ̣́ mo ̣́ . Ó yẹ kí wo ̣́n pa wo ̣́n ni . Ṣùgbo ̣́n Tanímo ̣́la ló gbà wo ̣́n síle ̣́ .Ó sì
tún ní kí wo ̣́n máa kóbo ̣́ ní ààfin ọba.
E ̣́ko ̣́ tí ìtàn yìí ko ̣́ wa ni pé , kò yẹ kí á máa fi ìyà jẹ aláìlárá nítorí pé a kò mọ e ̣́yìn
o ̣́la.
Apàlo:̣̀ Kí àlo ̣̀ mi gba orógbó jẹ
Kí ó má ṣe gba obì jẹ,
Orógbó ní í gbó ni sáyé
Obì á bì woṇ̀ soṛ̀ un
Bí mo bá puro ̣̀ kí ágogo e ̣̀nu mi má ṣe ró
ní e ̣̀e ̣̀mẹta

74
Bí n kò bá paro ̣̀
Kí agogo ẹnu mi ró
Ó di pó! pó! pó!
Ó ró tàbí kò ró?
Àgbáloọ̀ :̣̀ Ó ró!
Orísun ìtàn: Oṕ̣ ádo ̣́tun (1994)

5.0 Ìsọníṣókí
Ìyá Tanímo ̣́la ti kú.Tanímo ̣́la je ̣́ ọmọ tí ó rẹwà púpo ̣́ jù. Nítorí ẹwà re ̣́, orogún ìyá re ̣́
kò fe ̣́ràn-an re ̣́ rara . Bákan náà ni àwọn ọmọ orogún ìyá re ̣́ kórira re ̣́ . Wo ̣́n pinnu láti pa á .
Orogún ìyá re ̣́ rán an lọ sí odò níjo ̣́ tí àwọn iwi n n s ̣́o ̣́dun pe ̣́lu ero pe awo ̣́n iwin yoo pa a .
Ṣùgbo ̣́n dípò kí àwọn iwin pa á , nígbà tí ó ròyìn ara re ,̣́ wo ̣́n fún un lówó àti o ̣́po ̣́lọpo ̣́
nǹkan oro ̣́. Ọba rí i nígbà tí ó ń wọ ìlú, ó sì fi ṣe ayaba.

6.0 Iṣe ̣́ Ṣíṣe


Dáhùn ìbéèrè wo ̣́nyí:
1a. Wo ipin kinni (paragraph 1) ìtàn yìí, ọnà-èdè wo ni ó jẹyọ níbe?̣́
b. Ìgbà mélòó ni ọnà-èdè yìí jẹyọ?
2. Júwe ìwà àti ìrísí orogún ìyá Tanímo ̣́la
3. Irú ọmọ wo ni Tanímo ̣́la je ̣́.
4. Àwọn kókó wo ni o rí fàyọ nínú ìtàn náà.
5. Ṣe àgbéye ̣́wò bátànì ìparí àlo ̣́ yìí . Àwọn ọnà-èdè wo ni ó jẹyọ níbe ̣́ ? Fi ape ̣́e ̣́re ̣́ gbe
ìdáhùn rẹ le ̣́se ̣́.

7.0 Ìwé Ìto ̣́kasí


Oṕ̣ ádo ̣́tun, O. (1994) Àṣàyàn Àlo ̣̀ Onítàn. Ibadan: Y-Books.

75

You might also like