Jump to content

Fisáyọ̀ Ajíṣọlá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá
Ọjọ́ìbíOlúwáfisáyọ̀ Ajíbọ́lá Ajíṣọlá
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Iṣẹ́Òṣèré, Akọrin, àti Model
Ìgbà iṣẹ́2011 – present
Websitejef.org.ng

Fisáyọ̀ Ajíṣọlá, tí gbogbo ènìyàn tún mọ̀ sí Freezon,[1]jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ṣeré ìtàgé, model àti akọrin. Ó di ìlú mọ̀ọ́ká látàrí ipa tí ó kó nínú eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Jenifa's Diary, pẹ́lú Fúnkẹ́ Akíndélé. Ó tún ma ń kópa nínú eré ọ́lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ This Life, Nectar, Shadows, Burning Spear, Circle of Interest àti The Story of Us ní orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán.[2] Ó kẹ́kọ́ gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Biochemistry láti ilé-ẹ̀kọ́ Federal University of Agriculture, Abẹ́òkúta (FUNAAB), ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Fisáyọ̀ ní Ìlú Èkó, àmọ́ ọmọ bíbí Ìlú AyédùnÌpínlẹ̀ Èkìtì ni àwọn òbí rẹ̀. òun sì ni àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ mẹ́tin tí àwọn òbí rẹ̀ bí.[3]Fisáyọ̀ bẹ̀rẹ̀ eré-ìtàgé láti ìgbà tí ó ti wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama Federal Government College (FGC) Òdoògbólú, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn . Ó dara pọ̀ mọ́ Ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́ni ní eré ìtàgé ti Wale Adénúgà ( PEFTI School) ní inú oṣè kéje ọdún 2010, níbi tí ó ti kọ́ nípa eré orí-ìtàgé.[3]Eré tí ó kọ́kọ́ sọọ́ di ìlú mọ̀ọ́ká ni Nnena and Friends Show, nínú oṣè Kẹjọ ọdún 2010.[3] Ó dá àjọ kan sílẹ̀ nígbà tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì tí ó pè ní Jewel Empowerment Foundation pẹ̀lú èrò láti mú Ìdàgbà-sókè bá àwọn ọ̀dọ́ langba àti àwọn ògo wẹẹrẹ.[4]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré-ìtàgé ní pẹrẹu ní ọdún 2011, tí ó sì kòpa ribiribi nínú àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bí: Tinsel, Burning Spear àti Circle of interest. Ó sinmi díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ fúngbà díẹ̀ láti lè gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ nígbà tí ó wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ní ọdún 2011. Ó bẹ̀rẹ̀.sí ń gbé eré tirẹ̀ ná .jáde ní ọdún 2016, nígba tí ó kọ́kọ́ gbé eré sinimá bí [1] Road to Ruin,[5] pẹ́lú ìrànlọ̀wọ̀ àj9 rẹ̀ tí ó dá sílẹ̀. Ó gbé eré yí jáde láti lè ta ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jí kí eọ́n lè ma pèsè iṣẹ́ gidi fún àwọn ọ̀dọ́ langba tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmò ìjìnlẹ̀ gbogbo. [3][6][5]

Àwọn eré àgbéléwò rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Àkòrí eré Ipa rẹ̀ Olùgbéré-jáde àti Adarí eré Notes
2011 Tinsel Co-star Tope Oshin Ogun Mnet TV series
2011 Burning Spear Lead Akin Akindele TV Drama Series
2011 Circle of Interest Co-star Kalu Anya TV Series
2012 Shadows Lead Tunde Olaoye TV Series
2014 Nectar Co-star Sola Sobowale TV Series
2015 This Life Supporting Role Wale Adenuga TV Series
2016 Jenifa's Diary Co-star Funke Akindele Sitcom

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control